“Fi Gbogbo Ọkàn Àyà Rẹ Gbẹ́kẹ̀ Lé Jèhófà”
Jèhófà ló yẹ ká gbẹ́kẹ̀ lé pátápátá. Ìtúmọ̀ orúkọ rẹ̀ jẹ́ ohun tó fi wá lọ́kàn balẹ̀ pé ó máa mú gbogbo ìlérí rẹ̀ ṣẹ láìkù síbi kan. Àdúrà jẹ́ ọ̀nà kan tá a lè gbà fi hàn pé a gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà. Òwe orí 3 fi wá lọ́kàn balẹ̀ pé Jèhófà máa san wá lẹ́san tá a bá gbẹ́kẹ̀ lé e, ọ̀nà tó sì máa gbà ṣe bẹ́ẹ̀ ni pé ó máa ‘mú àwọn ipa ọ̀nà wa tọ́.’
Ẹni tó bá jẹ́ ọlọ́gbọ́n lójú ara rẹ̀ . . .
-
Ẹni tó gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà . . .
-
máa ń ṣe ìpinnu láìkọ́kọ́ béèrè pé kí Jèhófà tọ́ òun sọ́nà
• máa ń gbára lé èrò tirẹ̀ tàbí ti ayé
-
máa ń ní àjọṣe tímọ́tímọ́ pẹ̀lú rẹ̀ nípasẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, àṣàrò àti àdúrà
-
máa ń wá ìtọ́sọ́nà Ọlọ́run ní ti pé ó máa ń jẹ́ kí ìlànà Bíbélì tọ́ òun sọ́nà tó bá fẹ́ ṣèpinnu
ÀKỌ́KỌ́: Mo máa ń yan ohun tí mo rò pé ó mọ́gbọ́n dání jù lọ |
ÀKỌ́KỌ́: Mo máa ń bẹ Jèhófà pé kó bù kún ìpinnu tí mo bá ṣáà ti ṣe |
ÌKEJÌ: Mo máa ń wá ìtọ́sọ́nà Jèhófà nípasẹ̀ àdúrà àti ìdákẹ́kọ̀ọ́ |
ÌKEJÌ: Mo máa ń yan ohun tó bá àwọn ìlànà Bíbélì mu |