October 31 sí November 6
Òwe 22-26
Orin 88 àti Àdúrà
Ọ̀rọ̀ Ìbẹ̀rẹ̀ (3 min. tàbí kó máà tó bẹ́ẹ̀)
ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN
“Tọ́ Ọmọdékùnrin Ní Ọ̀nà Tí Yóò Tọ̀”: (10 min.)
Owe 22:6; 23:24, 25
—Tó o bá fi ìlànà Ọlọ́run kọ́ àwọn ọmọ rẹ, tí wọ́n bá dàgbà wọ́n á láyọ̀, ìgbésí ayé wọn á nítumọ̀, wọ́n á sì mọ̀wà hù (w08 4/1 ojú ìwé 16; w07 6/1 ojú ìwé 31) Owe 22:15; 23:13, 14
—“Ọ̀pá” túmọ̀ sí onírúurú ìbáwí tí àwọn òbí máa ń fún àwọn ọmọ nínú ìdílé (w97 10/15 ojú ìwé 32; it-2-E ojú ìwé 818 ìpínrọ̀ 4) Owe 23:22
—Àwọn ọmọ tó ti dàgbà máa ń jàǹfààní lára ọgbọ́n táwọn òbí wọn ní (w04 6/15 ojú ìwé 14 ìpínrọ̀ 1-3; w00 6/15 ojú ìwé 21 ìpínrọ̀ 13)
Máa Walẹ̀ Jìn Nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run: (8 min.)
Owe 24:16
—Báwo ni òwe yìí ṣe fún wa ní ìṣírí láti máa lo ìfaradà lẹ́nu eré ìje ìyè tí à ń sá? (w13 3/15 ojú ìwé 4 àti 5 ìpínrọ̀ 5 sí 8) Owe 24:27
—Ẹ̀kọ́ wo ni Òwe yìí kọ́ wa? (w09 10/15 ojú ìwé 12 ìpínrọ̀ 1) Ẹ̀kọ́ wo ni Bíbélì kíkà ọ̀sẹ̀ yìí kọ́ mi nípa Jèhófà?
Àwọn kókó wo látinú Bíbélì kíkà ọ̀sẹ̀ yìí ni mo lè lò lóde ẹ̀rí?
Bíbélì Kíkà: (4 min. tàbí kó máà tó bẹ́ẹ̀) Owe 22:
1-21
MÁA LO ARA RẸ LẸ́NU IṢẸ́ ÌWÀÁSÙ
Nígbà Àkọ́kọ́: (2 min. tàbí kó máà tó bẹ́ẹ̀) Lo káàdì ìkànnì JW.ORG.
—Ìjẹ́rìí àìjẹ́-bí-àṣà. Ìpadàbẹ̀wò: (4 min. tàbí kó máà tó bẹ́ẹ̀) Lo káàdì ìkànnì JW.ORG.
—Sọ ohun tí wàá bá ẹni náà jíròrò nígbà tó o bá tún pa dà wá, kó o sì jẹ́ kó wo fídíò Kí Nìdí Tó Fi Yẹ Kó O Kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì? láti fi kádìí ọ̀rọ̀ rẹ. Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì: (6 min. tàbí kó máà tó bẹ́ẹ̀) lv ojú ìwé 179 sí 181 ìpínrọ̀ 18 àti 19
MÁA HÙWÀ TÓ YẸ KRISTẸNI
Orin 101
“Ṣé O Máa Ń Lo Káàdì Ìkànnì JW.ORG?”: (15 min.) Ìjíròrò. Jẹ́ kí àwọn ará wo fídíò ọ̀nà ìgbọ́rọ̀kalẹ̀ tá a lè lò, kẹ́ ẹ sì jíròrò àwọn kókó pàtàkì tó wà níbẹ̀. Gba àwọn ará níyanjú pé kí wọ́n máa mú káàdì mélòó kan dání ní gbogbo ìgbà tí wọ́n bá fẹ́ jáde nílé.
Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Ìjọ: (30 min.) kr orí 3 ìpínrọ̀ 1 sí 12 àti Apá 1
—Òtítọ́ Nípa Ìjọba Ọlọ́run—Pípèsè Oúnjẹ Nípa Tẹ̀mí Àtúnyẹ̀wò àti Ohun Tá A Máa Kọ́ Lọ́sẹ̀ Tó Ń Bọ̀ (3 min.)
Orin 146 àti Àdúrà
Ìránnilétí: Jẹ́ kí àwọn ará kọ́kọ́ gbọ́ orin tuntun yìí lẹ́ẹ̀kan, lẹ́yìn náà, kí ẹ kọ ọ́.