‘Àwọn Ọmọkùnrin Yín àti Àwọn Ọmọbìnrin Yín Yóò Máa Sọ Tẹ́lẹ̀’
Àwọn Kristẹni ẹni àmì òróró ń kópa nínú iṣẹ́ ìsọtẹ́lẹ̀. Wọ́n ń sọ̀rọ̀ nípa “àwọn ohun ọlá ńlá Ọlọ́run” wọ́n sì ń kéde “ìhìn rere ìjọba” náà. (Iṣe 2:11, 17-21; Mt 24:14) Àwọn àgùntàn mìíràn ń tì wọ́n lẹ́yìn lẹ́nu iṣẹ́ yìí
Kí ló túmọ̀ sí láti “ké pe orúkọ Jèhófà”?
-
Ká mọ orúkọ rẹ̀
-
Ká bọ̀wọ̀ fún orúkọ rẹ̀
-
Ká gbára lé Ẹni tó ń jẹ́ orúkọ náà ká sì gbẹ́kẹ̀ lé e
Bi ara rẹ pé, ‘Báwo ni mo ṣe lè ti àwọn ẹni àmì òróró lẹ́yìn lẹ́nu iṣẹ́ ìsọtẹ́lẹ̀?’