MÁA HÙWÀ TÓ YẸ KRISTẸNI
Ìfẹ́ Ni A Fi Ń Dá Àwọn Kristẹni Tòótọ́ Mọ̀—Yẹra fún Ohun Tó Lè Ba Ìṣọ̀kan Jẹ́
ÌDÍ TÓ FI ṢE PÀTÀKÌ: Lálẹ́ ọjọ́ tó ṣáájú ikú Jésù, Jésù gbàdúrà pé kí àwọn ọmọlẹ́yìn òun di “ọ̀kan.” (Jo 17:23) Kí ìṣọ̀kan tó wà láàárín wọn má bàa dà rú, wọ́n gbọ́dọ̀ máa nífẹ̀ẹ́ ara wọn, ìyẹn ìfẹ́ tí “kì í kọ àkọsílẹ̀ ìṣeniléṣe.”—1Kọ 13:5.
BÓ O ṢE LÈ ṢE É:
-
Tẹ̀ lé àpẹẹrẹ Jèhófà, ibi táwọn èèyàn dáa sí ni kó o máa wò
-
Máa dárí jini látọkàn wá
-
Tí ọ̀rọ̀ kan bá ti yanjú, kò yẹ kó o tún máa sọ̀rọ̀ nípa ẹ̀ mọ́.—Owe 17:9
Ẹ WO FÍDÍÒ NÁÀ “Ẹ NÍ ÌFẸ́ LÁÀÁRÍN ARA YÍN”—MÁ ṢE MÁA KỌ ÀKỌSÍLẸ̀ ÌṢENILÉṢE, KẸ́ Ẹ SÌ DÁHÙN ÀWỌN ÌBÉÈRÈ YÌÍ:
-
Ní apá àkọ́kọ́ fídíò yẹn, báwo ni Fọlákẹ́ ṣe fi hàn pé òun ń ‘kọ àkọsílẹ̀ ìṣeniléṣe’?
-
Ní apá kejì fídíò náà, báwo ni Fọlákẹ́ ṣe borí èròkérò, tó sì bẹ̀rẹ̀ sí í ní èrò tó tọ́?
-
Lẹ́yìn-ọ̀-rẹyìn, kí ni Fọlákẹ́ ṣe tó fi hàn pé ó fẹ́ kí ìṣọ̀kan wà nínú ìjọ?