Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

MÁA HÙWÀ TÓ YẸ KRISTẸNI

Ìfẹ́ Ni A Fi Ń Dá Àwọn Kristẹni Tòótọ́ Mọ̀​—Máa Yọ̀ Pẹ̀lú Òtítọ́

Ìfẹ́ Ni A Fi Ń Dá Àwọn Kristẹni Tòótọ́ Mọ̀​—Máa Yọ̀ Pẹ̀lú Òtítọ́

ÌDÍ TÓ FI ṢE PÀTÀKÌ: Bíi ti Jésù, àwa náà gbọ́dọ̀ jẹ́rìí sí òtítọ́ nípa àwọn nǹkan tí Ọlọ́run fẹ́ ṣe fún aráyé. (Jo 18:37) Láìka ti pé inú ayé tó kún fún irọ́ àti ìwà àìṣòdodo là ń gbé, a gbọ́dọ̀ máa yọ̀ pẹ̀lú òtítọ́, ká máa sọ òtítọ́, ká sì máa ronú lórí ohun yòówù tí ó jẹ́ òtítọ́.​—1Kọ 13:6; Flp 4:8.

BÓ O ṢE LÈ ṢE É:

  • Pinnu pé oò ní máa tẹ́tí sí òfófó àti pé oò ní máa ṣe òfófó.​—1Tẹ 4:11

  • Má ṣe máa yọ̀ tí nǹkan burúkú bá ṣẹlẹ̀ sẹ́nì kan

  • Àwọn ohun tó dáa tó sì ń fúnni níṣìírí ni kó o jẹ́ kó máa múnú rẹ dùn

Ẹ WO FÍDÍÒ NÁÀ “Ẹ NÍ ÌFẸ́ LÁÀÁRÍN ARA YÍN”​—MÁA YỌ̀ PẸ̀LÚ ÒTÍTỌ́, KÌ Í ṢE LÓRÍ ÀÌṢÒDODO, KẸ́ Ẹ SÌ DÁHÙN ÀWỌN ÌBÉÈRÈ YÌÍ:

  • Ọ̀nà wo ni Dámilọ́lá gbà “yọ̀ lórí àìṣòdodo”?

  • Báwo ni Àìná ṣe yí ìjíròrò òun àti Dámilọ́lá sí èyí tó ń gbéni ró?

  • Àwọn nǹkan tó dáa wo la lè sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀?

Máa yọ̀ pẹ̀lú òtítọ́, kì í ṣe lórí àìṣòdodo