October 8-14
JÒHÁNÙ 11-12
Orin 16 àti Àdúrà
Ọ̀rọ̀ Ìbẹ̀rẹ̀ (3 min. tàbí kó máà tó bẹ́ẹ̀)
ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN
“Máa Tu Àwọn Míì Nínú Bí I Ti Jésù”: (10 min.)
Jo 11:23-26—Jésù sọ ọ̀rọ̀ ìtùnú fún Màtá (“Mo mọ̀ pé yóò dìde” àlàyé ọ̀rọ̀ lórí Jo 11:24, nwtsty; “Èmi ni àjíǹde àti ìyè” àlàyé ọ̀rọ̀ lórí Jo 11:25, nwtsty)
Jo 11:33-35—Inú Jésù bà jẹ́ gan-an nígbà tó rí Màríà àtàwọn míì tí wọ́n ń sunkún (“sunkún,” “kérora . . . ó sì dààmú,” “nínú ẹ̀mí” àlàyé ọ̀rọ̀ lórí Jo 11:33, nwtsty; “bẹ̀rẹ̀ sí da omijé” àlàyé ọ̀rọ̀ lórí Jo 11:35, nwtsty)
Jo 11:43, 44—Jésù ṣèrànwọ́ fáwọn tó nílò ìrànlọ́wọ́
Máa Walẹ̀ Jìn Nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run: (8 min.)
Jo 11:49—Ta ló yan Káyáfà sípò àlùfáà àgbà, báwo ló sì ṣe pẹ́ tó nípò yẹn? (“àlùfáà àgbà” àlàyé ọ̀rọ̀ lórí Jo 11:49, nwtsty)
Jo 12:42—Kí nìdí tẹ́rù fi ń ba àwọn Júù kan láti sọ pé Jésù ni Kristi? (“àwọn olùṣàkóso,” “lé wọn jáde kúrò nínú sínágọ́gù” àlàyé ọ̀rọ̀ lórí Jo 12:42, nwtsty)
Kí ni Bíbélì kíkà ọ̀sẹ̀ yìí kọ́ ẹ nípa Jèhófà?
Àwọn ìṣúra tẹ̀mí wo lo tún rí látinú Bíbélì kíkà ọ̀sẹ̀ yìí?
Bíbélì Kíkà: (4 min. tàbí kó máà tó bẹ́ẹ̀) Jo 12:35-50
MÁA LO ARA RẸ LẸ́NU IṢẸ́ ÌWÀÁSÙ
Nígbà Àkọ́kọ́: (2 min. tàbí kó máà tó bẹ́ẹ̀) Lo ohun tá a lè bá àwọn èèyàn sọ.
Ìpadàbẹ̀wò Àkọ́kọ́—Fídíò: (5 min.) Ẹ wo fídíò náà, kẹ́ ẹ sì jíròrò rẹ̀.
Àsọyé: (6 min. tàbí kó máà tó bẹ́ẹ̀) w13 9/15 32—Àkòrí: Kí Ló Fà Á Tí Jésù Fi Da Omijé Lójú Kó Tó Jí Lásárù Dìde?
MÁA HÙWÀ TÓ YẸ KRISTẸNI
Jésù Ni “Àjíǹde àti Ìyè” (Jo 11:25): (15 min.) Ìjíròrò. Jẹ́ kí àwọn ará wo fídíò náà ‘Dájúdájú Ọlọ́run Fi Í Ṣe Olúwa àti Kristi’—Apá II, Àyọlò. Lẹ́yìn náà, béèrè àwọn ìbéèrè yìí: Kí ni ìtàn yìí kọ́ wa nípa bí Jésù ṣe jẹ́ aláàánú? Ọ̀nà wo ni Jésù gbà jẹ́ “àjíǹde àti ìyè”? Àwọn iṣẹ́ ìyanu wo ni Jésù máa ṣe lọ́jọ́ iwájú?
Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Ìjọ: (30 min.) lv orí 14 ¶1-9
Àtúnyẹ̀wò àti Ohun Tá A Máa Kọ́ Lọ́sẹ̀ Tó Ń Bọ̀ (3 min.)
Orin 147 àti Àdúrà