Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN | Ẹ́KÍSÓDÙ 37-38

Ohun Tí Pẹpẹ Àgọ́ Ìjọsìn Wà Fún

Ohun Tí Pẹpẹ Àgọ́ Ìjọsìn Wà Fún

37:​25, 29; 38:1

Jèhófà ló fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ní ìtọ́ni nípa bí wọ́n ṣe máa kọ́ àgọ́ ìjọsìn, ó sì nídìí pàtàkì tó fi ní kí wọ́n ṣe é bẹ́ẹ̀.

  • Bíi ti tùràrí olóòórùn dídùn táwọn ọmọ Ísírẹ́lì máa ń sun, inú Jèhófà máa ń dùn táwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ bá ń gbàdúrà sí i

  • Táwọn ọmọ Ísírẹ́lì bá rúbọ lórí pẹpẹ ẹbọ sísun, Jèhófà máa ń tẹ́wọ́ gbà á. Ìwájú ibi mímọ́ ni pẹpẹ yìí wà, èyí jẹ́ ká rí i pé a gbọ́dọ̀ nígbàgbọ́ nínú ẹbọ ìràpadà Jésù kínú Ọlọ́run tó lè dùn sí wa.​—Jo 3:​16-18; Heb 10:​5-10

Báwo la ṣe lè mú kí àdúrà wa dà bíi tùràrí olóòórùn dídùn sí Ọlọ́run?​—Sm 141:2