Àwọn Ànímọ́ Jèhófà Tó Fani Mọ́ra
Mósè mọyì àwọn ànímọ́ Jèhófà, ìdí nìyẹn tó fi ń fi sùúrù bá àwọn ọmọ Ísírẹ́lì lò. Táwa náà bá mọyì àwọn ànímọ́ Jèhófà, àá máa ṣàánú àwọn ará wa.
-
“Ọlọ́run aláàánú, tó ń gba tẹni rò”: Báwọn òbí ṣe máa ń tọ́jú àwọn ọmọ wọn, bẹ́ẹ̀ ni Jèhófà ṣe máa ń fìfẹ́ bójú tó àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀, tó sì ń gba tiwọn rò
-
“Kì í tètè bínú”: Jèhófà máa ń mú sùúrù fáwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ kí wọ́n lè ṣàtúnṣe sí ìwà wọn
-
“Ìfẹ́ rẹ̀ tí kì í yẹ̀ . . . pọ̀ gidigidi”: Bí Jèhófà ṣe ń fi ìfẹ́ tí kì í yẹ̀ hàn sáwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ mú kí wọ́n ní àjọṣe tó dáa pẹ̀lú rẹ̀
BI ARA RẸ PÉ, ‘Àwọn ọ̀nà wo ni mo lè gbà máa fi àánú hàn bíi ti Jèhófà?’