Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

MÁA HÙWÀ TÓ YẸ KRISTẸNI

Ẹ̀yin Ọ̀dọ́—Ṣé Jèhófà Ni Ọ̀rẹ́ Tẹ́ Ẹ Fẹ́ràn Jù Lọ?

Ẹ̀yin Ọ̀dọ́—Ṣé Jèhófà Ni Ọ̀rẹ́ Tẹ́ Ẹ Fẹ́ràn Jù Lọ?

Gbogbo wa la máa ń fẹ́ ní ọ̀rẹ́ táá dúró tì wá nígbà ìṣòro, táá máa fàánú hàn sí wa, táá sì jẹ́ ọ̀làwọ́. Gbogbo ànímọ́ yìí ni Jèhófà ní. (Ẹk 34:6; Iṣe 14:17) Jèhófà máa ń gbọ́ àdúrà wa. Ó máa ń ràn wá lọ́wọ́ nígbà gbogbo. (Sm 18:​19, 35) Ó máa ń dárí jì wá. (1Jo 1:9) Ọ̀rẹ́ gidi ni Jèhófà lóòótọ́!

Báwo lo ṣe lè di ọ̀rẹ́ Jèhófà? Máa ka Bíbélì kó o lè túbọ̀ mọ Jèhófà. Máa sọ gbogbo ohun tó wà lọ́kàn rẹ̀ fún un. (Sm 62:8; 142:2) Fi hàn pé o mọyì àwọn ohun tó ṣe pàtàkì sí Jèhófà, ìyẹn àwọn nǹkan bíi Ìjọba rẹ̀, Ọmọ rẹ̀, àtàwọn ìlérí rẹ̀. Máa sọ̀rọ̀ rẹ̀ fáwọn míì. (Di 32:3) Tó o bá ní àjọṣe tó dáa pẹ̀lú Jèhófà, ẹ̀yin méjèèjì á máa ṣọ̀rẹ́ títí láé.​—Sm 73:25, 26, 28.

Ẹ WO FÍDÍÒ NÁÀ Ẹ̀YIN Ọ̀DỌ́​—Ẹ TỌ́ JÈHÓFÀ WÒ, KÍ Ẹ SÌ RÍ I PÉ Ó JẸ́ ẸNI RERE, KẸ́ Ẹ SÌ DÁHÙN ÀWỌN ÌBÉÈRÈ YÌÍ:

  • Kí ló yẹ kó o ṣe kó o lè yara ẹ sí mímọ́, kó o sì ṣèrìbọmi?

  • Báwo làwọn ará nínú ìjọ ṣe lè ràn ẹ́ lọ́wọ́ kó o lè máa sin Jèhófà?

  • Báwo ni iṣẹ́ ìwàásù ṣe lè mú kí àjọṣe tó o ní pẹ̀lú Jèhófà lágbára sí i?

  • Títí láé ni wàá máa gbádùn àjọṣe tó o ní pẹ̀lú Jèhófà!

    Àwọn iṣẹ́ wo lo lè ṣe nínú ètò Ọlọ́run, tó o bá ní àjọṣe tó dáa pẹ̀lú Jèhófà?

  • Kí lohun tó o fẹ́ràn jù nípa Jèhófà?