October 5-11
Ẹ́KÍSÓDÙ 31-32
Orin 45 àti Àdúrà
Ọ̀rọ̀ Ìbẹ̀rẹ̀ (1 min.)
ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN
“Ẹ Sá fún Ìbọ̀rìṣà”: (10 min.)
Ẹk 32:1—Ti pé nǹkan ò rọrùn ò túmọ̀ sí pé ó yẹ ká máa sin ọlọ́run míì (w09 5/15 11 ¶11)
Ẹk 32:4-6—Àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ń sin ọlọ́run míì, àmọ́ wọ́n gbà pé ìjọsìn tòótọ́ làwọn ń ṣe (w12 10/15 25 ¶12)
Ẹk 32:9, 10—Jèhófà bínú sáwọn ọmọ Ísírẹ́lì (w18.07 20 ¶14)
Máa Walẹ̀ Jìn Nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run: (10 min.)
Ẹk 31:17—Kí ló túmọ̀ sí pé Jèhófà sinmi ní ọjọ́ keje? (w19.12 3 ¶4)
Ẹk 32:32, 33—Báwo la ṣe mọ̀ pé ẹ̀kọ́ èké ni èrò táwọn kan ní pé “ìgbàlà lẹ́ẹ̀kan, ìgbàlà gbogbo ìgbà”? (w87 9/1 29)
Àwọn ìṣúra tẹ̀mí wo lo tún rí nínú Bíbélì kíkà ọ̀sẹ̀ yìí nípa Jèhófà, iṣẹ́ ìwàásù tàbí àwọn nǹkan míì?
Bíbélì Kíkà: (4 min. tàbí kó máà tó bẹ́ẹ̀) Ẹk 32:15-35 (th ẹ̀kọ́ 10)
MÁA LO ARA RẸ LẸ́NU IṢẸ́ ÌWÀÁSÙ
Fídíò Nígbà Àkọ́kọ́: (4 min.) Ìjíròrò. Ẹ wo fídíò náà, lẹ́yìn náà béèrè pé: Báwo ni Jọkẹ́ ṣe lo ìbéèrè lọ́nà tó yẹ? Báwo ló ṣe múra ọkàn onílé sílẹ̀ fún ìpadàbẹ̀wò?
Nígbà Àkọ́kọ́: (4 min. tàbí kó máà tó bẹ́ẹ̀) Bẹ̀rẹ̀ pẹ̀lú ohun tá a lè bá àwọn èèyàn sọ. Ṣe bíi pé ẹ wo fídíò Kí Nìdí Tó Fi Yẹ Kó O Kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì? (àmọ́ ẹ má ṣe wò ó) (th ẹ̀kọ́ 9)
Àsọyé: (5 min. tàbí kó máà tó bẹ́ẹ̀) w10 5/15 21—Àkòrí: Kí Nìdí Tí Jèhófà Ò Ṣe Fìyà Jẹ Áárónì Torí Pé Ó Ṣe Ère Ọmọ Màlúù? (th ẹ̀kọ́ 7)
MÁA HÙWÀ TÓ YẸ KRISTẸNI
“Mọyì Àjọṣe Rẹ Pẹ̀lú Jèhófà”: (15 min.) Ìjíròrò. Jẹ́ kí àwọn ará wo fídíò náà Má Ṣe Jẹ́ Kí Àjọṣe Rẹ Pẹ̀lú Jèhófà Bà Jẹ́ (Kol. 3:5).
Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Ìjọ: (30 min. tàbí kó máà tó bẹ́ẹ̀) jy orí 135
Ọ̀rọ̀ Ìparí (3 min. tàbí kó máà tó bẹ́ẹ̀)
Orin 90 àti Àdúrà