MÁA HÙWÀ TÓ YẸ KRISTẸNI
Mọyì Àjọṣe Rẹ Pẹ̀lú Jèhófà
Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ní àǹfààní àrà ọ̀tọ̀ kan. Lẹ́yìn tá a yara wa sí mímọ́ fún Jèhófà tá a sì ṣèrìbọmi, a túbọ̀ ń sapá kí àjọṣe wa pẹ̀lú Jèhófà Ẹlẹ́dàá wa lè máa lágbára sí i. Ó lo Jésù Ọmọ rẹ̀ láti fà wá sọ́dọ̀ ara rẹ̀. (Jo 6:44) Ó sì máa ń gbọ́ àdúrà wa.—Sm 34:15.
Báwo la ṣe lè fi hàn pé a mọyì àjọṣe tó ṣàrà ọ̀tọ̀ tá a ní pẹ̀lú Ọlọ́run? Ohun kan ni pé, a gbọ́dọ̀ sá fún ohun tó máa mú ká dẹ́ṣẹ̀ bíi tàwọn ọmọ Ísírẹ́lì. Kò pẹ́ lẹ́yìn tí wọ́n bá Jèhófà dá májẹ̀mú, wọ́n ṣe ère ọmọ màlúù, wọ́n sì ń jọ́sìn rẹ̀. (Ẹk 32:7, 8; 1Kọ 10:7, 11, 14) Àwa náà lè bi ara wa pé: ‘Kí ni màá ṣe tí mo bá kojú ìdẹwò? Ṣé mò ń fi hàn pé mo mọyì àjọṣe mi pẹ̀lú Jèhófà?’ Tí ìfẹ́ tá a ní fún Jèhófà bá jinlẹ̀, àá máa sá fún ohunkóhun tí Jèhófà bá kórìíra.—Sm 97:10.
Ẹ WO FÍDÍÒ NÁÀ MÁ ṢE JẸ́ KÍ ÀJỌṢE RẸ PẸ̀LÚ JÈHÓFÀ BÀ JẸ́ (KOL 3:5), KẸ́ Ẹ SÌ DÁHÙN ÀWỌN ÌBÉÈRÈ YÌÍ:
-
Kí ni ojúkòkòrò?
-
Kí nìdí tó fi yẹ ká sá fún ojúkòkòrò àti ìbọ̀rìṣà?
-
Báwo ni ìṣekúṣe àti ìbọ̀rìṣà ṣe jọra?
-
Kí nìdí tó fi yẹ káwọn tó ń múpò iwájú máa fiyè sí ohun tí ẹnì kejì wọn nílò?