Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

MÁA HÙWÀ TÓ YẸ KRISTẸNI

Àwọn Nǹkan Tó Yẹ Kó O Yẹra fún Tó O Bá Ń Darí Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì

Àwọn Nǹkan Tó Yẹ Kó O Yẹra fún Tó O Bá Ń Darí Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì

Má Sọ̀rọ̀ Jù: Má ṣe rò pé ìwọ lo gbọ́dọ̀ ṣàlàyé gbogbo ọ̀rọ̀. Jésù máa ń lo ìbéèrè láti mú káwọn èèyàn ronú kí wọ́n sì lóye ohun tó ń sọ. (Mt 17:24-27) Ìbéèrè máa ń jẹ́ kí ìkẹ́kọ̀ọ́ gbádùn mọ́ni, ó máa ń jẹ́ ká mọ̀ bóyá akẹ́kọ̀ọ́ lóye ohun tó ń kọ́, ó sì máa ń jẹ́ ká mọ ohun tó gbà gbọ́. (be ojú ìwé 253 ìpínrọ̀ 2 àti 3) Tó o bá béèrè ìbéèrè, ní sùúrù kí ẹni náà dáhùn. Tí ìdáhùn akẹ́kọ̀ọ́ náà ò bá tọ̀nà, dípò tí wàá fí sọ ìdáhùn fún un, tún bi í ní ìbéèrè míì tá á jẹ́ kó lè sọ ìdáhùn tó tọ̀nà. (be ojú ìwé 238 ìpínrọ̀ 1 àti 2) Má ṣe da ọ̀rọ̀ sílẹ̀ wuuruwù, kí akẹ́kọ̀ọ́ náà lè lóye ohun tuntun tí ẹ̀ ń jíròrò.—be ojú ìwé 230 ìpínrọ̀ 4.

Má Ṣe Jẹ́ Kí Ọ̀rọ̀ Rẹ Lọ́jú Pọ̀: Má ṣe sọ gbogbo ohun tó o mọ̀ nípa ẹ̀kọ́ náà. (Jo 16:12) Kókó tó wà nínú ìpínrọ̀ náà ni kó o gbájú mọ́. (be ojú ìwé 226 ìpínrọ̀ 4 àti 5) Tí àlàyé bá ti pọ̀ jù, ì báà tiẹ̀ jẹ́ èyí tó gbádùn mọ́ni, ó lè da ojú ọ̀rọ̀ rú. (be ojú ìwé 235 ìpínrọ̀ 3) Tí kókó ọ̀rọ̀ bá ti ṣe kedere sí akẹ́kọ̀ọ́ náà, ẹ lọ sí ìpínrọ̀ tó kàn.

Má Ṣe Rò Pé Ẹ Gbọ́dọ̀ Ka Ibi Tó Pọ̀: Ohun tá a fẹ́ ni pé kí òtítọ́ wọ àwọn èèyàn lọ́kàn, kì í ṣe bí ohun tá a kà ṣe pọ̀ tó ló ṣe pàtàkì. (Lk 24:32) Tó o bá ń ṣàlàyé àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ tó tan mọ́ ohun tẹ́ ẹ̀ ń kọ́ ní tààràtà, èyí á fi hàn pé ò ń lo Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run dáadáa. (2Kọ 10:4; Heb 4:12; be ojú ìwé 144 ìpínrọ̀ 1 sí 3) Lo àpèjúwe tó máa tètè yéni. (be ojú ìwé 245 ìpínrọ̀ 2 sí 4) Máa ronú nípa àwọn ìṣòro akẹ́kọ̀ọ́ náà àti òhun tó gbà gbọ́, kó o sì jẹ́ kó rí bó ṣe lè fi ohun tó ń kọ́ sílò. Bi í láwọn ìbéèrè bíi: “Báwo ni ẹ̀kọ́ tó ò ń kọ́ yìí ṣe rí lára ẹ?” “Kí ni èyí kọ́ wa nípa Jèhófà?” “Àǹfààní wo lo máa rí tó o bá ń fi àwọn ìmọ̀ràn yìí sílò?”—be ojú ìwé 238 ìpínrọ̀ 3 sí 5; ojú ìwé 259 ìpínrọ̀ 1.