Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

MÁA HÙWÀ TÓ YẸ KRISTẸNI

Tí Ọmọdé Kan Bá Sọ Pé Ká Wọlé

Tí Ọmọdé Kan Bá Sọ Pé Ká Wọlé

Tí ọmọdé kan bá sọ pé ká wọlé, ó yẹ ká bi í bóyá àwọn òbí ẹ̀ wà nílé. Èyí fi hàn pé a bọ̀wọ̀ fún wọn, a sì gbà pé wọ́n láṣẹ lórí àwọn ọmọ wọn. (Owe 6:20) A ò gbọ́dọ̀ wọlé táwọn òbí ọmọ náà kò bá sí nílé, kódà bí ọmọ náà bá sọ pé ká wọlé. Tí àwọn òbí ò bá sí nílé, ńṣe ni ká pa dà bẹ̀ wọ́n wò nígbà míì.

Tó bá jẹ́ pé ọmọ tó ti dàgbà díẹ̀ ni, bóyá tó wà láàárín ọdún mẹ́ẹ̀ẹ́dógún sí mọ́kàndínlógún, ó ṣì máa dáa ká béèrè àwọn òbí rẹ̀. Tí wọn ò bá sí nílé, a lè béèrè pé ṣé àwọn òbí rẹ̀ máa gbà kó ka ìwé tá a fẹ́ fún un? Tó bá dáhùn pé bẹ́ẹ̀ ni, a lè fún un ní ìwé, a sì tún lè ní kó lọ sórí ìkànnì jw.org.

Tí a bá fẹ́ ṣe ìpadàbẹ̀wò sọ́dọ̀ ọ̀dọ́ tó nífẹ̀ẹ́ sí ọ̀rọ̀ wa yìí, ó yẹ ká rí àwọn òbí rẹ̀. Èyí á jẹ́ ká lè ṣàlàyé ìdí tá a fi ń wá sọ́dọ̀ ọmọ wọn, a sì tún máa fi ìmọ̀ràn tí gbogbo ìdílé lè gbára lé hàn wọ́n látinú Bíbélì. (Sm 119:86, 138) Tá a bá ń bọ̀wọ̀ fún àwọn òbí, tá a sì ń kà wọ́n sí, èyí lè jẹ́ kí wọ́n rí i pé ọmọlúwàbí ni wá, ó sì tún lè jẹ́ ká láǹfààní láti wàásù ìhìn rere fún ìdílé náà.—1Pe 2:12.