September 10-16
JÒHÁNÙ 3-4
Orin 57 àti Àdúrà
Ọ̀rọ̀ Ìbẹ̀rẹ̀ (3 min. tàbí kó máà tó bẹ́ẹ̀)
ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN
“Jésù Wàásù fún Obìnrin Ará Samáríà Kan”: (10 min.)
Jo 4:6, 7—Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ó ti rẹ Jésù, síbẹ̀ ó wàásù fún obìnrin ará Samáríà kan (“tí ó ti rẹ̀” àlàyé ọ̀rọ̀ lórí Jo 4:6, nwtsty)
Jo 4:21-24—Bí Jésù ṣe wàásù fún obìnrin náà mú kí ọ̀pọ̀ èèyàn gbọ́ nípa Mèsáyà
Jo 4:39-41—Ọ̀pọ̀ àwọn ará Samáríà ló gba Jésù gbọ́, torí pé ó sapá láti bá obìnrin yẹn sọ̀rọ̀
Máa Walẹ̀ Jìn Nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run: (8 min.)
Jo 3:29—Kí ni ẹsẹ Bíbélì yìí túmọ̀ sí? (“ọ̀rẹ́ ọkọ ìyàwó” àlàyé ọ̀rọ̀ lórí Jo 3:29, nwtsty)
Jo 4:10—Kí ló ṣeé ṣe kí obìnrin ará Samáríà yẹn máa rò nígbà tí Jésù sọ̀rọ̀ nípa “omi ààyè,” àmọ́ kí ni Jésù ń tọ́ka sí? (“omi ààyè” àlàyé ọ̀rọ̀ lórí Jo 4:10, nwtsty)
Kí ni Bíbélì kíkà ọ̀sẹ̀ yìí kọ́ ẹ nípa Jèhófà?
Àwọn ìṣúra tẹ̀mí wo lo tún rí látinú Bíbélì kíkà ọ̀sẹ̀ yìí?
Bíbélì Kíkà: (4 min. tàbí kó máà tó bẹ́ẹ̀) Jo 4:1-15
MÁA LO ARA RẸ LẸ́NU IṢẸ́ ÌWÀÁSÙ
Nígbà Àkọ́kọ́: (2 min. tàbí kó máà tó bẹ́ẹ̀) Wo Ohun Tá A Lè Bá Àwọn Èèyàn Sọ.
Ìpadàbẹ̀wò Àkọ́kọ́—Fídíò: (5 min.) Ẹ wo fídíò náà, kẹ́ ẹ sì jíròrò rẹ̀.
Àsọyé: (6 min. tàbí kó máà tó bẹ́ẹ̀) wp16.2 9 ¶1-4—Àkòrí: Ìtumọ̀ Ọ̀rọ̀ Inú Jòhánù 4:23.
MÁA HÙWÀ TÓ YẸ KRISTẸNI
“Mú Kí Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Rẹ Sunwọ̀n Sí I—Bá A Ṣe Lè Sọ Ìjíròrò Lásán Di Ìwàásù”: (15 min.) Ìjíròrò. Ní ìparí iṣẹ́ rẹ, gba àwọn ará níyànjú pé kí wọ́n bẹ̀rẹ̀ ìjíròrò kan tó máa yọrí sí ìwàásù láàárín lọ́sẹ̀ yìí. Ní ìpàdé àárín ọ̀sẹ̀ tó ń bọ̀, àwọn akéde máa láǹfààní láti sọ ìrírí tí wọ́n ní.
Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Ìjọ: (30 min.) lv orí 12 ¶15-22 àti àpótí Ṣé Ọ̀rọ̀ Ẹnu Mi Ń Gbéni Ró?
Àtúnyẹ̀wò àti Ohun Tá A Máa Kọ́ Lọ́sẹ̀ Tó Ń Bọ̀ (3 min.)
Orin 35 àti Àdúrà