Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

MÁA HÙWÀ TÓ YẸ KRISTẸNI

Mú Kí Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Rẹ Sunwọ̀n Sí I—Bá A Ṣe Lè Sọ Ìjíròrò Lásán Di Ìwàásù

Mú Kí Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Rẹ Sunwọ̀n Sí I—Bá A Ṣe Lè Sọ Ìjíròrò Lásán Di Ìwàásù

Ó ṣeé ṣe fún Jésù láti jẹ́rìí fún obìnrin ará Samáríà yẹn lọ́nà àìjẹ́-bí-àṣà torí pé ó bẹ̀rẹ̀ ìjíròrò pẹ̀lú obìnrin náà. Báwo làwa náà ṣe lè sunwọ̀n sí i tó bá dọ̀rọ̀ ká bẹ̀rẹ̀ ìjíròrò pẹ̀lú ẹni tá ò mọ̀ rí?

  • Jẹ́ kára ẹ yọ̀ mọ́ọ̀yàn, kó o sì máa bá àwọn èèyàn sọ̀rọ̀. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ó ti rẹ Jésù, síbẹ̀ ó dọ́gbọ́n tọrọ omi lọ́wọ́ obìnrin náà, kó lè bẹ̀rẹ̀ ìjíròrò pẹ̀lú rẹ̀. Tíwọ náà bá fẹ́ bẹ̀rẹ̀ ìjíròrò, kọ́kọ́ kí ẹni náà pẹ̀lú ọ̀yàyà, lẹ́yìn náà o lè wá sọ̀rọ̀ nípa bójú ọjọ́ ṣe rí tàbí ohun kan tó ṣẹ̀ṣẹ̀ ṣẹlẹ̀. Rántí pé ńṣe lo kàn fẹ́ bá ẹni náà sọ̀rọ̀, torí náà o lè sọ̀rọ̀ nípa kókó èyíkéyìí tẹ́ni náà máa nífẹ̀ẹ́ sí. Tí kò bá dá ẹ lóhùn, má fi ṣèbínú. Tún wá ẹlòmíì tí wàá bá sọ̀rọ̀. Bẹ Jèhófà pé kó fún ẹ nígboyà.​—Ne 2:4; Iṣe 4:29.

  • Máa wá ọ̀nà tó o lè gbà sọ ìhìn rere fáwọn èèyàn, àmọ́ má ṣe kánjú. Má ṣe fipá mú ẹni náà láti bá ẹ sọ̀rọ̀. Tó o bá ṣe bẹ́ẹ̀, ó lè má bá ẹni náà lára mu, kó má sì fẹ́ bá ẹ sọ̀rọ̀ mọ́. Má ṣe jẹ́ kó ká ẹ lára tó ò bá láǹfààní láti wàásù fún ẹni náà kí ìjíròrò yín tó parí. Tó bá ṣòro fún ẹ láti wàásù lọ́nà àìjẹ́-bí-àṣà, máa fi kọ́ra láti bá àwọn tí o kò mọ̀ rí sọ̀rọ̀, má wulẹ̀ wàásù fún wọn, ṣáà bá wọn sọ̀rọ̀. [Jẹ́ káwọn ará wo fídíò 1 kẹ́ ẹ sì jíròrò rẹ̀.]

  • Tó o bá fẹ́ wàásù fún ẹnìkan, o lè sọ ohun kan tó o gbà gbọ́ fún ẹni náà, táá sì mú kẹ́ni náà bi ẹ́ ní ìbéèrè láti mọ púpọ̀ sí i. Jésù sọ ọ̀rọ̀ kan tó gbàfiyèsí obìnrin náà, ìdí nìyẹn tó fi bi Jésù ní ìbéèrè. Nígbà tí Jésù fi máa dáhùn ìbéèrè obìnrin yẹn, ó ti bẹ̀rẹ̀ sí í wàásù ìhìn rere fún un. [Jẹ́ káwọn ará wo fídíò 2 kẹ́ ẹ sì jíròrò rẹ̀, lẹ́yìn náà kẹ́ ẹ wo fídíò 3 kẹ́ ẹ sì jíròrò rẹ̀.]