Jésù Wàásù fún Obìnrin Ará Samáríà Kan
Kí ló jẹ́ kí Jésù lè wàásù lọ́nà àìjẹ́-bí-àṣà?
-
4:7—Dípò táá fi sọ̀rọ̀ nípa Ìjọba Ọlọ́run tàbí kó sọ fún un pé òun ni Mèsáyà, ńṣe ló kọ́kọ́ béèrè omi mímu lọ́wọ́ obìnrin náà
-
4:9—Kò rò ó lọ́kàn rẹ̀ pé obìnrin náà ò ní gbọ́ torí pé ará Samáríà ni
-
4:9, 12—Nígbà tí obìnrin yẹn sọ ohun tó lè dá àríyànjiyàn sílẹ̀, ṣe ni Jésù pọkàn pọ̀ sórí ohun tó fẹ́ kọ́ obìnrin yẹn.—cf 77 ¶3
-
4:10—Àpèjúwe kan tó dá lórí ohun tí obìnrin yẹn ń ṣe lójoojúmọ́ ni Jésù fi bẹ̀rẹ̀ ọ̀rọ̀ rẹ̀
-
4:16-19—Bó tílẹ̀ jẹ́ pé obìnrin yẹn máa ń ṣèṣekúṣe, síbẹ̀ Jésù fi ọ̀wọ̀ tiẹ̀ wọ̀ ọ́
Báwo ni ìtàn yìí ṣe jẹ́ ká rí ìdí tó fi ṣe pàtàkì pé ká máa wàásù lọ́nà àìjẹ́-bí-àṣà?