Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

MÁA HÙWÀ TÓ YẸ KRISTẸNI

Wọn Ò Fi Ohunkóhun Ṣòfò

Wọn Ò Fi Ohunkóhun Ṣòfò

Lẹ́yìn tí Jésù bọ́ àwọn obìnrin, àwọn ọmọ kéékèèké pẹ̀lú ẹgbẹ̀rún márùn-ún (5,000) ọkùnrin, ó sọ fún àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ pé: “Ẹ kó èébù tí ó ṣẹ́ kù jọpọ̀, kí ó má bàa sí ohun tí a fi ṣòfò.” (Jo 6:12) Bí Jésù kò ṣe fi ohunkóhun ṣòfò fi hàn pé ó mọrírì ohun tí Jèhófà pèsè.

Lóde òní, Ìgbìmọ̀ Olùdarí náà ń gbìyànjú láti tẹ̀ lé àpẹẹrẹ Jésù lórí bí wọ́n ṣe ń fọgbọ́n lo ohun tá a fi ń ṣètìlẹyìn. Bí àpẹẹrẹ, nígbà tá a ń kọ́ orílé-iṣẹ́ wa ní Warwick, New York, àwọn arákùnrin yan àwòrán ilé tó máa jẹ́ ká lè lo owó tá a fi ń ṣètìlẹyìn lọ́nà tó dáa.

KÍ LA LÈ ṢE TÁ Ò FI NÍ MÁA FI NǸKAN ṢÒFÒ . . .