September 24-30
JÒHÁNÙ 7-8
Orin 12 àti Àdúrà
Ọ̀rọ̀ Ìbẹ̀rẹ̀ (3 min. tàbí kó máà tó bẹ́ẹ̀)
ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN
“Jésù Yin Baba Rẹ̀ Lógo”: (10 min.)
Jo 7:15-18—Táwọn èèyàn bá yin Jésù nítorí ohun tó kọ́ wọn, Jèhófà ló máa ń fọpẹ́ fún (cf 100-101 ¶5-6)
Jo 7:28, 29—Jésù sọ pé Ọlọ́run ló rán òun wá sáyé, tó fi hàn pé Jésù kéré sí Jèhófà
Jo 8:29—Jésù sọ fáwọn tó ń gbọ́ ọ̀rọ̀ rẹ̀ pé gbogbo ìgbà ni òun máa ń ṣe ohun tí Jèhófà fẹ́ (w11 3/15 11 ¶19)
Máa Walẹ̀ Jìn Nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run: (8 min.)
Jo 7:8-10—Ṣé irọ́ ni Jésù pa fáwọn àbúrò rẹ̀ tí kò nígbàgbọ́ nínú rẹ̀? (w07 2/1 6 ¶4)
Jo 8:58—Kí nìdí tí wọ́n fi lo ọ̀rọ̀ náà “Èmi ti wà” ní ìparí ẹsẹ yìí dípò kí wọ́n sọ pé “Mo wà,” kí sì nìdí tó fi ṣe pàtàkì? (“èmi ti wà” àlàyé ọ̀rọ̀ lórí Jo 8:58, nwtsty)
Kí ni Bíbélì kíkà ọ̀sẹ̀ yìí kọ́ ẹ nípa Jèhófà?
Àwọn ìṣúra tẹ̀mí wo lo tún rí látinú Bíbélì kíkà ọ̀sẹ̀ yìí?
Bíbélì Kíkà: (4 min. tàbí kó máà tó bẹ́ẹ̀) Jo 8:31-47
MÁA LO ARA RẸ LẸ́NU IṢẸ́ ÌWÀÁSÙ
Ìpadàbẹ̀wò Kejì: (3 min. tàbí kó máà tó bẹ́ẹ̀) Bẹ̀rẹ̀ pẹ̀lú ohun tá a lè bá àwọn èèyàn sọ. Kó o sì pe ẹni náà wá sí ìpàdé.
Ìpadàbẹ̀wò Kẹta: (3 min. tàbí kó máà tó bẹ́ẹ̀) Ìwọ ni kó o yan ẹsẹ ìwé mímọ́ tó o máa lò, fi ọ̀kan nínú àwọn ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ lọ̀ ọ́.
Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì: (6 min. tàbí kó máà tó bẹ́ẹ̀) lv 9-10 ¶10-11
MÁA HÙWÀ TÓ YẸ KRISTẸNI
“Ní Ẹ̀mí Ìrẹ̀lẹ̀, Kó O Sì Mọ̀wọ̀n Ara Rẹ Bí I Ti Jésù”: (15 min.) Ìjíròrò. Jẹ́ kí àwọn ará wo àwọn fídíò yìí.
Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Ìjọ: (30 min.) lv orí 13 ¶5-15 àti àpótí Àwọn Àjọ̀dún Ìsìn Àti Ìjọsìn Sátánì [Kò pọn dandan kẹ́ ẹ ka àpótí tàbí àfikún àlàyé]
Àtúnyẹ̀wò àti Ohun Tá A Máa Kọ́ Lọ́sẹ̀ Tó Ń Bọ̀ (3 min.)
Orin 119 àti Àdúrà