MÁA HÙWÀ TÓ YẸ KRISTẸNI
Jẹ́ Kí Jèhófà Máa Wà Níwájú Rẹ Nígbà Gbogbo
Ó lè má rọrùn láti fi Ìjọba Ọlọ́run àti òdodo rẹ̀ sípò àkọ́kọ́ láyé wa tí àtijẹ-àtimu bá ṣòro. Ó lè máa ṣe wá bíi pé ká gba iṣẹ́ tó ta ko àwọn ìlànà Bíbélì tàbí èyí tí ò ní jẹ́ ká ráyè sin Jèhófà. Àmọ́, ẹ jẹ́ kó dá wa lójú pé Jèhófà máa ń fi agbára rẹ̀ hàn “nítorí àwọn tí wọ́n ń fi gbogbo ọkàn wọn sìn ín.” (2Kr 16:9) Kò sóhun tó lè dí Baba wa onífẹ̀ẹ́ lọ́wọ́ láti pèsè àwọn nǹkan tá a nílò àti láti ràn wá lọ́wọ́. (Ro 8:32) Torí náà, tá a bá fẹ́ pinnu irú iṣẹ́ tá a máa ṣe, ó ṣe pàtàkì ká gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà, ká sì pọkàn pọ̀ sórí iṣẹ́ ìsìn wa sí i.—Sm 16:8.
Ẹ WO FÍDÍÒ NÁÀ MÁA ṢIṢẸ́ JÈHÓFÀ TỌKÀNTỌKÀN, KẸ́ Ẹ SÌ DÁHÙN ÀWỌN ÌBÉÈRÈ YÌÍ:
-
Kí nìdí tí Jason ò fi gba ẹ̀gúnjẹ?
-
Báwo la ṣe lè fi Kólósè 3:23 sílò?
-
Báwo ni ìwà rere Jason ṣe ran Thomas lọ́wọ́?
-
Báwo la ṣe lè fi Mátíù 6:22 sílò?