Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN

Máa Fi Gbogbo Ọkàn Rẹ Tẹ̀ Lé Jèhófà

Máa Fi Gbogbo Ọkàn Rẹ Tẹ̀ Lé Jèhófà

Àtikékeré ni Kélẹ́bù ti ń fi gbogbo ọkàn rẹ̀ tẹ̀ lé Jèhófà (Joṣ 14:7, 8)

Lẹ́yìn ọ̀pọ̀ ọdún, Kélẹ́bù ṣì gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà nígbà tó fẹ́ ṣe iṣẹ́ kan tó nira láti bójú tó (Joṣ 14:10-12; w04 12/1 12 ¶2)

Jèhófà bù kún Kélẹ́bù torí pé ó fi tọkàntọkàn sìn ín (Joṣ 14:13, 14; w06 10/1 18 ¶11)

Bí Kélẹ́bù ṣe ń tẹ̀ lé ìtọ́ni Jèhófà, tí Jèhófà sì ń bù kún un, ìyẹn ń mú kí ìgbàgbọ́ rẹ̀ túbọ̀ lágbára. Báwa náà ṣe ń rí i tí Jèhófà ń dáhùn àdúrà wa, tó sì ń tọ́ wa sọ́nà, ìgbàgbọ́ wa á máa lágbára sí i, àá sì máa bá a lọ lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn Jèhófà.​—1Jo 5:14, 15.