Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN

Dáàbò Bo Ogún Iyebíye Tí Jèhófà Fún Ẹ

Dáàbò Bo Ogún Iyebíye Tí Jèhófà Fún Ẹ

Kélẹ́bù lé àwọn ọ̀tá kúrò lórí ilẹ̀ tí Jèhófà fún un, ó sì tipa bẹ́ẹ̀ dáàbò bo ilẹ̀ náà (Joṣ 15:14; it-1 1083 ¶3)

Kì í ṣe gbogbo àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ló lé àwọn tí kì í ṣe olùjọsìn Jèhófà kúrò lórí ilẹ̀ wọn (Joṣ 16:10; it-1 848)

Jèhófà máa ń ṣèrànwọ́ fáwọn tó bá pinnu láti dáàbò bo ogún wọn (Di 20:1-4; Joṣ 17:17, 18; it-1 402 ¶3)

Jèhófà ṣèlérí láti fún gbogbo àwọn tó jẹ́ olóòótọ́ ní ẹ̀bùn iyebíye kan, ìyẹn ìyè àìnípẹ̀kun. Ká lè dáàbò bo ogún yìí, à ń sapá láti borí àwọn ìdẹwò Sátánì. Ìdí nìyẹn tá a fi ń kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì lójoojúmọ́, tá à ń lọ sípàdé déédéé, tá à ń ṣiṣẹ́ ìwàásù, tá a sì ń gbàdúrà.

BI ARA RẸ PÉ, ‘Ṣé mò ń dáàbò bo ogún iyebíye tí Jèhófà fún mi?’