October 4-10
JÓṢÚÀ 8-9
Orin 127 àti Àdúrà
Ọ̀rọ̀ Ìbẹ̀rẹ̀ (1 min.)
ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN
“Ohun Tá A Rí Kọ́ Látinú Ìtàn Àwọn Ará Gíbíónì”: (10 min.)
Àwọn Ìṣúra Tẹ̀mí: (10 min.)
Joṣ 8:29—Kí nìdí tí wọ́n fi gbé ọba Áì kọ́ sórí òpó igi? (it-1 1030)
Àwọn ìṣúra tẹ̀mí wo lo tún rí nínú Bíbélì kíkà ọ̀sẹ̀ yìí nípa Jèhófà, iṣẹ́ ìwàásù tàbí àwọn nǹkan míì?
Bíbélì Kíkà: (4 min.) Joṣ 8:28–9:2 (th ẹ̀kọ́ 5)
MÁA LO ARA RẸ LẸ́NU IṢẸ́ ÌWÀÁSÙ
Nígbà Àkọ́kọ́: (3 min.) Bẹ̀rẹ̀ pẹ̀lú ohun tá a lè bá àwọn èèyàn sọ. Onílé sọ ohun táwọn èèyàn sábà máa ń sọ tí wọn ò bá fẹ́ gbọ́ ìwàásù. Fèsì ní ṣókí, kó o sì máa bá ọ̀rọ̀ rẹ lọ. (th ẹ̀kọ́ 2)
Ìpadàbẹ̀wò: (4 min.) Bẹ̀rẹ̀ pẹ̀lú ohun tá a lè bá àwọn èèyàn sọ. Pe ẹni náà wá sípàdé, kó o sì ṣe bíi pé ẹ wo fídíò Kí Ló Máa Ń Ṣẹlẹ̀ Nínú Gbọ̀ngàn Ìjọba? (àmọ́ ẹ má ṣe wò ó) (th ẹ̀kọ́ 11)
Àsọyé: (5 min.) it-1 520; 525 ¶1—Àkòrí: Kí La Rí Kọ́ Látinú Májẹ̀mú Tí Jóṣúà Dá Pẹ̀lú Àwọn Ará Gíbíónì? (th ẹ̀kọ́ 13)
MÁA HÙWÀ TÓ YẸ KRISTẸNI
Jẹ́ Ẹlẹ́mìí Ìrẹ̀lẹ̀ (1Pe 5:5): (15 min.) Ìjíròrò. Jẹ́ káwọn ará wo fídíò náà. Lẹ́yìn náà, bi àwọn ará ní ìbéèrè yìí: Báwo ni Pétérù àti Jòhánù ṣe tẹ̀ lé ìsọfúnni tí Jésù fún wọn nípa Ìrékọjá? Báwo ni Jésù ṣe kọ́ àwọn ọmọ ẹ̀yìn ẹ̀ nípa ẹ̀mí ìrẹ̀lẹ̀ ní alẹ́ tó ku ọ̀la kó kú? Báwo la ṣe mọ̀ pé Pétérù àti Jòhánù fi ẹ̀kọ́ yẹn sọ́kàn? Báwo la ṣe lè fi hàn pé a lẹ́mìí ìrẹ̀lẹ̀?
Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Ìjọ: (30 min.) rr orí 14 ¶15-20
Ọ̀rọ̀ Ìparí (3 min.)
Orin 59 àti Àdúrà