Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

MÁA HÙWÀ TÓ YẸ KRISTẸNI

Máa Kọ́ Agbára Ìfòyemọ̀ Rẹ

Máa Kọ́ Agbára Ìfòyemọ̀ Rẹ

Àwọn tó ń sáré gbọ́dọ̀ máa ṣe ìdánrawò lóòrèkóòrè, kí iṣan ara wọn lè lágbára, kí wọ́n sì lè máa mókè nínú ìdíje. Bákan náà, a gbọ́dọ̀ máa kọ́ agbára ìfòyemọ̀ wa ká lè máa ṣèpinnu tó tọ́. (Heb 5:14) Nígbà míì, ó lè máa ṣe wá bíi pé ká ṣerú ìpinnu táwọn míì ṣe, àmọ́ àwa fúnra wa ló yẹ ká kọ́ bá a ṣe lè ronú jinlẹ̀ ká lè máa ṣèpinnu tó dáa. Kí nìdí tíyẹn fi ṣe pàtàkì? Ìdí ni pé ẹnì kọ̀ọ̀kan lá jíhìn ìpinnu tó bá ṣe.​—Ro 14:12.

Kò yẹ ká máa ronú pé ọjọ́ pẹ́ tá a ti ṣèrìbọmi, torí náà gbogbo ìgbà làá máa ṣèpinnu tó tọ́. Ká tó lè ṣèpinnu tó dáa, a gbọ́dọ̀ gbára lé Jèhófà pátápátá, ká máa kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì jinlẹ̀, ká sì fọkàn tán ètò Ọlọ́run.​—Joṣ 1:7, 8; Owe 3:5, 6; Mt 24:45.

Ẹ WO FÍDÍÒ NÁÀ “Ẹ DI Ẹ̀RÍ-ỌKÀN RERE MÚ,” KẸ́ Ẹ SÌ DÁHÙN ÀWỌN ÌBÉÈRÈ YÌÍ:

  • Ìpinnu wo ló ṣòro fún Emma láti ṣe?

  • Kí nìdí tí kò fi yẹ ká máa gbé ìlànà tiwa kalẹ̀ lórí àwọn ìpinnu tó jẹ mọ́ ẹ̀rí ọkàn?

  • Ìmọ̀ràn ọlọ́gbọ́n wo ni tọkọtaya kan fún Emma?

  • Ibo ni Emma ti rí ìsọfúnni tó ràn án lọ́wọ́ láti ṣèpinnu tó tọ́?