September 27–October 3
JÓṢÚÀ 6-7
Orin 144 àti Àdúrà
Ọ̀rọ̀ Ìbẹ̀rẹ̀ (1 min.)
ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN
“Yẹra Fáwọn Nǹkan Tí Kò Ní Láárí”: (10 min.)
Àwọn Ìṣúra Tẹ̀mí: (10 min.)
Joṣ 6:20—Kí ló fi hàn pé kò pẹ́ táwọn ọmọ Ísírẹ́lì dó ti ìlú Jẹ́ríkò àtijọ́ tí wọ́n fi ṣẹ́gun wọn? (w15 11/15 13 ¶2-3)
Àwọn ìṣúra tẹ̀mí wo lo tún rí nínú Bíbélì kíkà ọ̀sẹ̀ yìí nípa Jèhófà, iṣẹ́ ìwàásù tàbí àwọn nǹkan míì?
Bíbélì Kíkà: (4 min.) Joṣ 6:1-14 (th ẹ̀kọ́ 10)
MÁA LO ARA RẸ LẸ́NU IṢẸ́ ÌWÀÁSÙ
Nígbà Àkọ́kọ́: (3 min.) Bẹ̀rẹ̀ pẹ̀lú ohun tá a lè bá àwọn èèyàn sọ. Onílé sọ ohun táwọn èèyàn sábà máa ń sọ tí wọn ò bá fẹ́ gbọ́ ìwàásù. Fèsì ní ṣókí, kó o sì máa bá ọ̀rọ̀ rẹ lọ. (th ẹ̀kọ́ 12)
Ìpadàbẹ̀wò: (4 min.) Bẹ̀rẹ̀ pẹ̀lú ohun tá a lè bá àwọn èèyàn sọ. Ṣe bíi pé ẹ wo fídíò Kí Nìdí Tó Fi Yẹ Kó O Kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì? (àmọ́ ẹ má ṣe wò ó) (th ẹ̀kọ́ 9)
Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì: (5 min.) lffi ẹ̀kọ́ 01 kókó 3 (th ẹ̀kọ́ 8)
MÁA HÙWÀ TÓ YẸ KRISTẸNI
Ohun Tí Ètò Ọlọ́run Ti Ṣe: (5 min.) Jẹ́ káwọn ará wo fídíò Ohun Tí Ètò Ọlọ́run Ti Ṣe ti oṣù September.
Ẹni Tó Bá Mọ̀ọ́mọ̀ Ṣàìgbọràn Máa Ń Jìyà Àbájáde Rẹ̀: (10 min.) Ìjíròrò. Jẹ́ káwọn ará wo fídíò ‘Kò Sí Ọ̀rọ̀ Kan Tí Ó Kùnà’—Àyọlò. Lẹ́yìn náà, bi àwọn ará ní ìbéèrè yìí: Ìkìlọ̀ tó ṣe kedere wo ni Jèhófà fáwọn ọmọ Ísírẹ́lì nípa ìlú Jẹ́ríkò? Kí ni Ákánì àti ìdílé rẹ̀ ṣe, kí sì nìdí tí wọ́n fi ṣe bẹ́ẹ̀? Kí la rí kọ́ nínú ìtàn yìí? Gba àwọn ará níyànjú pé kí wọ́n wo fídíò náà látìbẹ̀rẹ̀ dópin.
Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Ìjọ: (30 min.) rr orí 14 ¶8-14 àti àpótí 13A
Ọ̀rọ̀ Ìparí (3 min.)
Orin 88 àti Àdúrà