MÁA HÙWÀ TÓ YẸ KRISTẸNI
Àwọn Nǹkan Táá Jẹ́ Kó O Gbádùn Ìwé Gbádùn Ayé Rẹ Títí Láé!
Ṣé ò ń gbádùn àwọn fídíò àtàwọn ìbéèrè tó ń múni ronú jinlẹ̀ nínú ìwé Gbádùn Ayé Rẹ Títí Láé! Ṣé o sì ń gbádùn apá tá a pè ní “Àwọn Kan Sọ Pé,” “Ohun Tó Yẹ Kó O Ṣe” àti “Ṣèwádìí”? Àwọn nǹkan wo ló tún wà nínú ìwé yìí tó lè ràn ẹ́ lọ́wọ́ bó o ṣe ń sọni dọmọ ẹ̀yìn?—Mt 28:19, 20.
Àwọn fídíò: Tó bá jẹ́ pé ìwé ló wù ẹ́ láti máa fi kọ́ ẹnì kan lẹ́kọ̀ọ́, báwo lo ṣe lè rí gbogbo àwọn fídíò tó wà nínú ìwé náà lójú kan? Nínú ẹ̀dà torí ẹ̀rọ, yan ọ̀kan lára àwọn apá mẹ́rin tí ìwé náà pín sí. Nísàlẹ̀ àwọn àkòrí tó wà ní apá náà, wàá rí apá kan tá a pè ní “Ohun Tá A Tọ́ka Sí,” ibẹ̀ ni wàá ti rí gbogbo fídíò tá a tọ́ka sí ní apá náà. (Wo àwòrán 1.)
Bó o ṣe lè lo “Printed Edition” lórí ẹ̀rọ: Tó bá jẹ́ pé ẹ̀dà ti orí ẹ̀rọ lò ń lò, tó o sì fẹ́ jẹ́ kó dà bíi torí ìwé, o lè fi sí “Printed Edition.” Tó o bá ti ṣí ẹ̀kọ́ tẹ́ ẹ fẹ́ kà, tẹ àmì tóótòòtó mẹ́ta tó wà ní ọwọ́ ọ̀tún lápá òkè, kó o sì mú “Printed Edition.” Èyí máa jẹ́ kó o lè máa rí bí apá ibi tẹ́ ẹ̀ ń jíròrò lọ́wọ́ ṣe tan mọ́ gbogbo ẹ̀kọ́ náà lápapọ̀. Tó o bá fẹ́ pa dà sí bó ṣe máa ń rí lórí ẹ̀rọ, tẹ àmì tóótòòtó mẹ́ta yẹn pa dà, kó o sì mú “Digital Edition.”
“Ṣé Mo Ti Múra Tán?”: Àwọn àpótí tó wà lọ́wọ́ ìparí ìwé yìí sọ àwọn nǹkan téèyàn gbọ́dọ̀ ṣe kó tó lè kúnjú ìwọ̀n láti máa wàásù pẹ̀lú ìjọ, kó sì ṣèrìbomi. (Wo àwòrán 2.)
Àlàyé Ìparí Ìwé: Ní apá yìí, wàá rí àlàyé sí i lórí àwọn kókó pàtàkì kan. Nínú ẹ̀dà ti orí ẹ̀rọ, wàá rí ìlujá kan níparí àlàyé ìparí ìwé kọ̀ọ̀kan tó máa gbé ẹ pa dà síbi tẹ́ ẹ̀ ń jíròrò nínú ẹ̀kọ́ náà. (Wo àwòrán 2.)
Rí i dájú pé o parí ìwé Gbádùn Ayé Rẹ Títí Láé! pẹ̀lú ẹni tó ò ń kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ kódà tí ẹni yẹn bá ṣèrìbọmi kẹ́ ẹ tó parí ìwé náà. Tó bá jẹ́ pé ẹ ṣì ń ṣe ìkẹ́kọ̀ọ́ lẹ́yìn tẹ́ni náà ṣèrìbọmi, o lè máa kọ àkókò tẹ́ ẹ lò, ìpadàbẹ̀wò àti ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì sínú ìròyìn ẹ. Tó bá jẹ́ pé ìwọ àti akéde míì lẹ jọ lọ, tí akéde náà sì lóhùn sí ìkẹ́kọ̀ọ́ náà, òun náà lè kọ àkókò tẹ́ ẹ lò sínú ìròyìn ẹ̀