ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN
“Ìgbà Wo Lẹ Máa Ṣiyèméjì Dà?”
Èlíjà ní káwọn ọmọ Ísírẹ́lì pinnu bóyá Jèhófà ni wọ́n máa jọ́sìn tàbí Báálì (1Ọb 18:21; w17.03 14 ¶6)
Òrìṣà tí kò lẹ́mìí ni Báálì (1Ọb 18:25-29; ia 88 ¶15)
Jèhófà fi hàn lọ́nà tó ṣàrà ọ̀tọ̀ pé òun nìkan ni Ọlọ́run tòótọ́ (1Ọb 18:36-38; ia 90 ¶18)
Èlíjà sọ fáwọn èèyàn náà pé tí wọ́n bá ń pa Òfin Jèhófà mọ́, ìyẹn á fi hàn pé wọ́n nígbàgbọ́. (Di 13:5-10; 1Ọb 18:40) Lónìí, a lè fi hàn pé a nígbàgbọ́, a sì bẹ̀rù Ọlọ́run tá a bá ń pa àwọn àṣẹ rẹ̀ mọ́.