MÁA HÙWÀ TÓ YẸ KRISTẸNI
Jèhófà Fẹ́ Kí Ìgbéyàwó Wà Pẹ́ Títí
Ìdílé tó bá ní ayọ̀ máa ń mú ìyìn bá Jèhófà, ó sì máa ń jẹ́ kí ọkàn tọkọtaya balẹ̀. (Mk 10:9) Kí Kristẹni kan tó lè ní ìdílé aláyọ̀, kí ìgbéyàwó ẹ̀ sì dùn bí oyin, ó gbọ́dọ̀ fi àwọn ìlànà Bíbélì sílò tó bá fẹ́ yan ẹni tó máa fẹ́.
Kó o tó ní àfẹ́sọ́nà, á dáa kó o “kọjá ìgbà ìtànná èwe,” ìyẹn ìgbà tí ìfẹ́ láti ní ìbálòpọ̀ máa ń lágbára, tó sì lè mú kéèyàn ṣi ìpinnu ṣe. (1Kọ 7:36) O lè fi àkókò tó o fi wà láìní ọkọ tàbí aya mú kí àjọṣe tó o ní pẹ̀lú Jèhófà túbọ̀ lágbára, kó o sì mú kí ìwà rẹ dáa sí i. Tó o bá wá ṣègbéyàwó, àwọn ohun tó o ti kọ́ yìí á jẹ́ kó o lè di ọkọ tàbí aya rere.
Kó o tó pinnu láti fẹ́ ẹnì kan, ó yẹ kó o ṣe sùúrù, kó o sì fara balẹ̀ dáadáa kó o lè mọ “ẹni ìkọ̀kọ̀ ti ọkàn.” (1Pe 3:4) Tó o bá kíyè sí àwọn ohun kan tó kù-díẹ̀-káàtó, á dáa kíwọ àti àfẹ́sọ́nà ẹ jọ jókòó sọ ọ́. Bó o ṣe ń ronú nípa ìgbéyàwó, ohun tó yẹ kó jẹ ẹ́ lógún ni ohun tó o lè fún ẹnì kejì ẹ, kì í ṣe ohun tó o lè rí gbà lọ́wọ́ rẹ̀. (Flp 2:3, 4) Tó bá ti mọ́ ẹ lára láti máa fi àwọn ìlànà Bíbélì sílò kó o tó ṣègbéyàwó, á rọrùn fún ẹ láti máa ṣe bẹ́ẹ̀ lẹ́yìn tó o bá ṣègbéyàwó, ìyẹn á sì jẹ́ kí ayọ̀ wà nínú ìdílè ẹ, kí ìgbéyàwó ẹ sì dùn bí oyin.
Ẹ WO FÍDÍÒ NÁÀ BÓ O ṢE LÈ MÚRA SÍLẸ̀ FÚN ÌGBÉYÀWÓ—APÁ 3: ṢÍRÒ OHUN TÓ MÁA NÁ Ẹ,” KẸ́ Ẹ SÌ DÁHÙN ÀWỌN ÌBÉÈRÈ YÌÍ:
-
Báwo ni nǹkan ṣe rí láàárín arábìnrin náà àti Shane nígbà tí wọ́n kọ́kọ́ bẹ̀rẹ̀ sí í fẹ́ra sọ́nà?
-
Kí ni arábìnrin náà kíyè sí bọ́jọ́ ṣe ń gorí ọjọ́?
-
Báwo làwọn òbí ẹ̀ ṣe ràn án lọ́wọ́, ìpinnu tó bọ́gbọ́n mu wo ló sì ṣe?