ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN
Máa Yin Jèhófà Nítorí Ọgbọ́n Rẹ̀
Jèhófà fún Sólómọ́nì ní ọgbọ́n tó ṣàrà ọ̀tọ̀ (1Ọb 10:1-3; w99 7/1 30 ¶6)
Ẹnu ya ọbabìnrin Ṣébà nígbà tó rí ọgbọ́n tí Jèhófà fún Sólómọ́nì (1Ọb 10:4, 5; w99 11/1 20 ¶6)
Ọbabìnrin Ṣébà yin Jèhófà torí pé Sólómọ́nì ló yàn láti jẹ́ ọba (1Ọb 10:6-9; w99 7/1 30-31)
Bíi ti ọbabìnrin Ṣébà, a lè fi hàn pé a mọyì ọgbọ́n Jèhófà. Ọ̀nà wo la lè gbà ṣe bẹ́ẹ̀? Ọ̀nà kan tá a lè gbà ṣe bẹ́ẹ̀ ni pé ká máa fi ohun tí Jésù kọ́ni sílò, ká sì ṣe gbogbo ohun tá a bá lè ṣe láti máa fara wé e. (Mt 12:42; 1Pe 2:21) Ọ̀nà míì ni pé ká máa sọ nípa ọgbọ́n Ọlọ́run fáwọn míì lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù.