Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

MÁA HÙWÀ TÓ YẸ KRISTẸNI

Ran Àwọn Tí Kò Ṣe Ẹ̀sìn Kankan Lọ́wọ́ Kí Wọ́n Lè Gbà Pé Ọlọ́run Wà

Ran Àwọn Tí Kò Ṣe Ẹ̀sìn Kankan Lọ́wọ́ Kí Wọ́n Lè Gbà Pé Ọlọ́run Wà

Tó o bá pàdé ẹni tí kò ṣe ẹ̀sìn kankan lóde ìwàásù, ṣé ó máa ń ṣe ẹ́ bíi pé kó o má ṣe wàásù fún un torí o ronú pé kò ní fẹ́ gbọ́? Tó bá rí bẹ́ẹ̀, rántí pé ọ̀pọ̀ àwọn tí kò ṣe ẹ̀sìn kankan tẹ́lẹ̀ títí kan àwọn tí kò gbà pé Ọlọ́run wà ló ti di Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Lọ́pọ̀ ìgbà, ohun tí wọ́n nílò ni ẹni tó máa ràn wọ́n lọ́wọ́ kí wọ́n lè rí àwọn ẹ̀rí tó fi hàn pé Ọlọ́run wà lóòótọ́.—Ro 1:20; 10:14.

Ẹ WO FÍDÍÒ MÁA RÁNTÍ PÉ ÀWỌN ALÁÌGBÀGBỌ́ LÈ DI ONÍGBÀGBỌ́!—ÀWỌN TÍ KÒ ṢE Ẹ̀SÌN KANKAN, KẸ́ Ẹ SÌ DÁHÙN ÌBÉÈRÈ YÌÍ:

Báwo ni ohun tó ṣẹlẹ̀ sí Tommaso ṣe jẹ́ ká rí i pé kò yẹ ká jẹ́ kó sú wa láti máa wàásù fáwọn tí kò ṣe ẹ̀sìn kankan?