Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

MÁA HÙWÀ TÓ YẸ KRISTẸNI

Gbẹ́kẹ̀ Lé Jèhófà Tí Ẹnì Kan Bá Ń Halẹ̀ Mọ́ Ẹ

Gbẹ́kẹ̀ Lé Jèhófà Tí Ẹnì Kan Bá Ń Halẹ̀ Mọ́ Ẹ

Àwọn tó ń halẹ̀ mọ́ni lè pa wá lára, kí wọ́n sì ṣe ohun tó máa mú kí inú wa bà jẹ́. Wọ́n tiẹ̀ lè máa ta kò wá torí pé à ń jọ́sìn Ọlọ́run, tá a bá sì jẹ́ kí ẹ̀rù bà wá, ìyẹn lè ba àjọṣe wa pẹ̀lú Jèhófà jẹ́. Kí lo lè ṣe tí ẹnì kan bá ń halẹ̀ mọ́ ẹ?

Ọ̀pọ̀ àwọn ìránṣẹ́ Jèhófà ni wọ́n halẹ̀ mọ́, àmọ́ wọ́n borí àwọn tó ń halẹ̀ mọ́ wọn torí pé wọ́n gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà. (Sm 18:17) Bí àpẹẹrẹ, Ẹ́sítà fìgboyà sọ fún ọba nípa ohun búburú tí Hámánì tó ń halẹ̀ mọ́ àwọn Júù fẹ́ ṣe. (Ẹst 7:​1-6) Kí Ẹ́sítà tó sọ fún ọba, ó gbààwẹ̀, ìyẹn sì fi hàn pé ó gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà. (Ẹst 4:​14-16) Jèhófà ràn án lọ́wọ́, ó sì dáàbò bo Ẹ́sítà àtàwọn èèyàn rẹ̀.

Ẹ̀yin ọ̀dọ́, tí ẹnì kan bá ń halẹ̀ mọ́ yín, ẹ bẹ Jèhófà pé kó ràn yín lọ́wọ́, kẹ́ ẹ sì sọ ìṣòro náà fún àgbàlagbà kan tí òtítọ́ jinlẹ̀ nínú ẹ̀, irú bí àwọn òbí yín. Ó dájú pé Jèhófà máa ràn yín lọ́wọ́ bíi ti Ẹ́sítà. Kí lo tún lè ṣe tí ẹnì kan bá ń halẹ̀ mọ́ ẹ?

Ẹ WO FÍDÍÒ NÁÀ ÌGBÀ Ọ̀DỌ́ MI—OHUN TÓ O LÈ ṢE TÍ WỌ́N BÁ Ń HALẸ̀ MỌ́ Ẹ, KẸ́ Ẹ SÌ DÁHÙN ÀWỌN ÌBÉÈRÈ YÌÍ:

  • Ẹ̀kọ́ wo làwọn ọ̀dọ́ lè rí kọ́ lára Charlie àti Ferin?

  • Kí làwọn òbí lè rí kọ́ látinú ohun tí Charlie àti Ferin sọ nípa báwọn òbí ṣe lè ran àwọn ọmọ wọn lọ́wọ́ tí ẹnì kan bá ń halẹ̀ mọ́ wọn?