October 28–November 3
SÁÀMÙ 103-104
Orin 30 àti Àdúrà | Ọ̀rọ̀ Ìbẹ̀rẹ̀ (1 min.)
1. “Ó Rántí Pé Erùpẹ̀ Ni Wá”
(10 min.)
Torí pé aláàánú ni Jèhófà, ó máa ń gba tiwa rò (Sm 103:8; w23.07 21 ¶5)
Kò ní pa wá tì tá a bá tiẹ̀ ṣàṣìṣe (Sm 103:9, 10; w23.09 6-7 ¶16-18)
Kì í retí ohun tó ju agbára wa lọ (Sm 103:14; w23.05 26 ¶2)
BI ARA RẸ PÉ, ‘Ṣé ojú tí Jèhófà fi ń wo ọkọ tàbí aya mi lèmi náà fi ń wò ó, ṣé mo sì máa ń gba tiẹ̀ rò?’
2. Àwọn Ẹ̀kọ́ Iyebíye Míì
(10 min.)
3. Bíbélì Kíkà
(4 min.) Sm 104:1-24 (th ẹ̀kọ́ 11)
4. Bá A Ṣe Lè Bẹ̀rẹ̀ Ọ̀rọ̀ Wa
(3 min.) ÌWÀÁSÙ NÍBI TÍ ÈRÒ PỌ̀ SÍ. (lmd ẹ̀kọ́ 3 kókó 4)
5. Pa Dà Lọ
(4 min.) ÌWÀÁSÙ ILÉ-DÉ-ILÉ. Jíròrò fídíò Ohun Tó O Máa Gbádùn Nínú Ẹ̀kọ́ Bíbélì Rẹ pẹ̀lú ẹnì kan tó gbà láti kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. (th ẹ̀kọ́ 9)
6. Àsọyé
(5 min.) lmd àfikún A kókó 6—Àkòrí: Ó Yẹ Kí Ọkọ “Nífẹ̀ẹ́ Aya Rẹ̀ Bó Ṣe Nífẹ̀ẹ́ Ara Rẹ̀.” (th ẹ̀kọ́ 1)
Orin 44
7. Ó Yẹ Ká Mọ Ohun Tágbára Wa Gbé
(15 min.) Ìjíròrò.
Inú Jèhófà máa dùn tá a bá ń ṣe gbogbo ohun tá a lè ṣe lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn rẹ̀, àwa náà sì máa láyọ̀. (Sm 73:28) Àmọ́, ó yẹ ká mọ ibi tágbára wa mọ. Àìjẹ́ bẹ́ẹ̀, a lè bẹ̀rẹ̀ sí í kọ́kàn sókè, kí ìrẹ̀wẹ̀sì sì bá wa.
Jẹ́ kí àwọn ará wo FÍDÍÒ A Máa Tẹ̀ Síwájú Tá A Bá Ń Ronú Nípa Nǹkan Tọ́wọ́ Wa Lè Tẹ̀. Lẹ́yìn náà, béèrè pé:
-
Kí ni Jèhófà fẹ́ ká ṣe? (Mik 6:8)
-
Kí ni kò jẹ́ kí arábìnrin náà da ara ẹ̀ láàmú mọ́ bó tiẹ̀ jẹ́ pé ọwọ́ ẹ̀ ò tíì tẹ àfojúsùn ẹ̀?
8. Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Ìjọ
(30 min.) bt orí 17 ¶8-12, àpótí ojú ìwé 137