October 7-13
SÁÀMÙ 92-95
Orin 84 àti Àdúrà | Ọ̀rọ̀ Ìbẹ̀rẹ̀ (1 min.)
1. Ohun Tó Dáa Jù Téèyàn Lè Fayé Ẹ̀ Ṣe Ni Pé Kó Sin Jèhófà
(10 min.)
Jèhófà ló yẹ ká máa sìn (Sm 92:1, 4; w18.04 26 ¶5)
Ó fún wa lọ́gbọ́n táá jẹ́ ká lè ṣèpinnu tó dáa, táá sì jẹ́ ká gbádùn ayé wa (Sm 92:5; w18.11 20 ¶8)
Ó mọyì àwọn àgbàlagbà tó ń sìn ín (Sm 92:12-15; w20.01 19 ¶18)
BI ARA RẸ PÉ, ‘Kí ló ń dí mi lọ́wọ́ láti ya ara mi sí mímọ́ fún Jèhófà kí n sì ṣèrìbọmi?’
2. Àwọn Ẹ̀kọ́ Iyebíye Míì
(10 min.)
-
Sm 92:5—Báwo ni ẹsẹ Bíbélì yìí ṣe jẹ́ ká mọ bí ọgbọ́n Jèhófà ṣe pọ̀ tó? (cl 176 ¶18)
-
Àwọn ẹ̀kọ́ iyebíye wo lo rí nínú Bíbélì kíkà ọ̀sẹ̀ yìí tí wàá fẹ́ sọ?
3. Bíbélì Kíkà
(4 min.) Sm 94:1-23 (th ẹ̀kọ́ 5)
4. Bá A Ṣe Lè Bẹ̀rẹ̀ Ọ̀rọ̀ Wa
(4 min.) ÌWÀÁSÙ ÀÌJẸ́-BÍ-ÀṢÀ. Wá bó o ṣe lè sọ fún ẹnì kan tẹ́ ẹ jọ ń sọ̀rọ̀ nípa bó o ṣe máa ń ran àwọn èèyàn lọ́wọ́ láti kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. (lmd ẹ̀kọ́ 5 kókó 3)
5. Pa Dà Lọ
(3 min.) ÌWÀÁSÙ ÀÌJẸ́-BÍ-ÀṢÀ. O ti fi ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì lọ ẹni náà nígbà kan rí, àmọ́ kò gbà. Gbìyànjú láti tún fi ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì lọ̀ ọ́. (lmd ẹ̀kọ́ 8 kókó 4)
6. Sọ Àwọn Èèyàn Di Ọmọ Ẹ̀yìn
(5 min.) Ìjíròrò pẹ̀lú akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì kan tí ò tẹ̀ síwájú. (lmd ẹ̀kọ́ 12 kókó 5)
Orin 5
7. Ohun Táwọn Ọ̀dọ́ Lè Ṣe Tí Ọkàn Wọn Ò Bá Balẹ̀
(15 min.) Ìjíròrò.
Gbogbo èèyàn ló máa ń ṣàníyàn, èyí ò sì yọ àwọn tó ń sin Jèhófà sílẹ̀. Bí àpẹẹrẹ, àwọn ìgbà kan wà tí ọkàn Dáfídì ò balẹ̀, bó sì ṣe rí fáwọn ará wa lónìí náà nìyẹn. (Sm 13:2; 139:23) Kódà, àwọn ọ̀dọ́ náà máa ń bára wọn nírú ipò yìí. Nígbà míì, àníyàn lè jẹ́ kí àwọn nǹkan tá à ń ṣe lójoojúmọ́ di ohun tó ń kà wá láyà, irú bíi lílọ sílé ìwé tàbí àwọn ìpàdé ìjọ. Téèyàn bá ń ṣàníyàn jù, ó lè jẹ́ káyà èèyàn máa já láìnídìí tàbí kéèyàn tiẹ̀ máa ronú láti pa ara ẹ̀.
Ẹ̀yin ọ̀dọ́, tí nǹkan kan bá ń kó yín lọ́kàn sókè, tó sì mú kí gbogbo nǹkan tojú sú yín, ẹ fọ̀rọ̀ náà lọ àwọn òbí yín tàbí àgbàlagbà kan tí òtítọ́ jinlẹ̀ nínú ẹ̀. Ẹ má sì gbàgbé láti gbàdúrà sí Jèhófà. (Flp 4:6) Torí pé ó ṣe tán láti ràn yín lọ́wọ́. (Sm 94:17-19; Ais 41:10) Ẹ jẹ́ ká wo àpẹẹrẹ Steing.
Jẹ́ kí àwọn ará wo FÍDÍÒ Jèhófà Bìkítà Nípa Mi. Lẹ́yìn náà, béèrè pé:
• Ẹsẹ Bíbélì wo ló ran Steing lọ́wọ́, báwo ló sì ṣe ràn án lọ́wọ́?
• Báwo ni Jèhófà ṣe ràn án lọ́wọ́?
Ẹ̀yin òbí, ẹ máa fara balẹ̀ tẹ́tí sáwọn ọmọ yín, kẹ́ ẹ sì máa ṣe ohun tó fi hàn pé ẹ nífẹ̀ẹ́ wọn. Bákan náà, ẹ máa ràn wọ́n lọ́wọ́ kí wọ́n lè fọkàn tán Jèhófà, kí wọ́n sì gbà pé ó nífẹ̀ẹ́ wọn. Tẹ́ ẹ bá ń ṣe bẹ́ẹ̀, wọ́n á lè borí ìṣòro èyíkéyìí tó ń kó wọn lọ́kàn sókè. (Tit 2:4; Jem 1:19) Bẹ Jèhófà pé kó fún ẹ lókùn, kó sì fi ẹ́ lọ́kàn balẹ̀ kó o lè ran àwọn ọmọ rẹ lọ́wọ́.
A lè má mọ̀ tí ẹnì kan nínú ìjọ bá ní ìṣòro kan tó ń kó o lọ́kàn sókè, a sì lè má mọ bí nǹkan ṣe rí lára ẹ̀. Àmọ́, a lè ran irú àwọn ẹni bẹ́ẹ lọ́wọ́ tá a bá ń fìfẹ́ hàn sí gbogbo àwọn ará, tá a sì ń ṣe ohun táá mára tù wọ́n.—Owe 12:25; Heb 10:24.
8. Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Ìjọ
(30 min.) bt orí 16 ¶6-9, àpótí ojú ìwé 132