Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

September 16-22

SÁÀMÙ 85-87

September 16-22

Orin 41 àti Àdúrà | Ọ̀rọ̀ Ìbẹ̀rẹ̀ (1 min.)

ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN

1. Àdúrà Máa Ń Jẹ́ Ká Lè Ní Ìfaradà

(10 min.)

Bẹ Jèhófà pé kó jẹ́ kó o máa láyọ̀ (Sm 86:4)

Bẹ Jèhófà pé kó ràn ẹ́ lọ́wọ́ kó o lè máa jẹ́ olóòótọ́ nìṣó (Sm 86:11, 12; w12 5/15 25 ¶10)

Jẹ́ kó dá ẹ lójú pé Jèhófà máa dáhùn àdúrà ẹ (Sm 86:6, 7; w23.05 13 ¶17-18)


BI ARA RẸ PÉ, ‘Ṣé àdúrà mi máa ń gùn, ṣé ó sì máa ń ṣe lemọ́lemọ́ ti mo bá ní ìṣòro?’—Sm 86:3.

2. Àwọn Ẹ̀kọ́ Iyebíye Míì

(10 min.)

  • Sm 86:11—Kí ni àdúrà Dáfídì jẹ́ ká mọ̀ pé ó lè ṣẹlẹ̀ sí ọkàn èèyàn? (it-1 1058 ¶5)

  • Àwọn ẹ̀kọ́ iyebíye wo lo rí nínú Bíbélì kíkà ọ̀sẹ̀ yìí tí wàá fẹ́ sọ?

3. Bíbélì Kíkà

TẸRA MỌ́ IṢẸ́ ÌWÀÁSÙ

4. Bá A Ṣe Lè Bẹ̀rẹ̀ Ọ̀rọ̀ Wa

(3 min.) ÌWÀÁSÙ ÀÌJẸ́-BÍ-ÀṢÀ. Fi ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì lọ ẹni náà. (lmd ẹ̀kọ́ 3 kókó 5)

5. Pa Dà Lọ

(4 min.) ÌWÀÁSÙ ÀÌJẸ́-BÍ-ÀṢÀ. Fi ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì lọ ẹnì kan tó sọ bí àwọn ohun tó ń ṣẹlẹ̀ ṣe ń kó o lọ́kàn sókè nígbà tẹ́ ẹ jọ sọ̀rọ̀ kẹ́yìn. (lmd ẹ̀kọ́ 7 kókó 4)

6. Sọ Àwọn Èèyàn Di Ọmọ Ẹ̀yìn

(5 min.) lff ẹ̀kọ́ 15 kókó 5. Sọ ètò tó o ṣe fún akẹ́kọ̀ọ́ rẹ kó lè ṣe ìkẹ́kọ̀ọ́ rẹ̀ lọ́sẹ̀ tó ò ní sí nílé. (lmd ẹ̀kọ́ 10 kókó 4)

MÁA HÙWÀ TÓ YẸ KRISTẸNI

Orin 83

7. Má Jẹ́ Kó Sú Ẹ

(5 min.) Ìjíròrò.

Jẹ́ kí àwọn ará wo FÍDÍÒ náà. Lẹ́yìn náà béèrè pé:

  • Kí ló lè mú kí iṣẹ́ ìwàásù sú wa nígbà míì?

  • Kí nìdí tá ò fi gbọ́dọ̀ jẹ́ kó sú wa?

8. Máa Fi Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Lọ Àwọn Èèyàn

(10 min.) Ìjíròrò.

Ṣé o ti lẹ́ni tó ò ń fi ìwé Gbádùn Ayé Rẹ Títí Láé! kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì lásìkò àkànṣe ìwàásù yìí? Tó bá rí bẹ́ẹ̀, inú ẹ máa dùn gan-an, ó sì tún máa fún àwọn míì níṣìírí. Àmọ́, ká sọ pé o ò tíì ní ẹni tó ò ń kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, ó lè máa ṣe ẹ́ bíi pé ṣe lo kàn ń fàkókò ẹ ṣòfò. Kí lo lè ṣe tó bá ń ṣe ẹ́ bẹ́ẹ̀?

Jẹ́ káwọn ará wo FÍDÍÒ ‘À Ń Dámọ̀ràn Ara Wa Bí Òjíṣẹ́ Ọlọ́run . . . Bá A Ṣe Ń Mú Sùúrù’—Tá A Bá Ń Wàásù. Lẹ́yìn náà, béèrè pé:

  • Báwo ni 2 Kọ́ríńtì 6:4, 6 ṣe lè ràn wá lọ́wọ́ tó bá ń ṣe wá bíi pé iṣẹ́ ìwàásù wa ò méso jáde?

  • Àwọn àyípadà wo la lè ṣe tá ò bá lẹ́ni tá à ń kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì láìka bá a ṣe ń jáde tó?

Ká rántí pé, iye àwọn tá à ń kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì kọ́ ló máa pinnu bóyá a máa láyọ̀ lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù. Àmọ́, ohun tó yẹ kó máa fún wa láyọ̀ ni pé Jèhófà mọrírì ìsapá wa. (Lk 10:17-20) Torí náà, ẹ jẹ́ ká fi gbogbo ọkàn wa kópa nínú àkànṣe ìwàásù yìí, kẹ́ ẹ sì jẹ́ kó dá yín lójú pé “làálàá yín kò ní já sí asán nínú Olúwa”!—1Kọ 15:58.

9. Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Ìjọ

Ọ̀rọ̀ Ìparí (3 min.) | Orin 39 àti Àdúrà