Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

September 2-8

SÁÀMÙ 79-81

September 2-8

Orin 29 àti Àdúrà | Ọ̀rọ̀ Ìbẹ̀rẹ̀ (1 min.)

ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN

1. Máa Fi Hàn Pé O Nífẹ̀ẹ́ Orúkọ Jèhófà Tó Jẹ́ Ológo

(10 min.)

Jáwọ́ nínú ìwà èyíkéyìí tó lè tàbùkù sórúkọ Jèhófà (Sm 79:9; w17.02 9 ¶5)

Máa ké pe orúkọ Jèhófà (Sm 80:18; ijwbv 3 ¶4-5)

Jèhófà máa bù kún wa lọ́pọ̀lọpọ̀ tá a bá jẹ́ onígbọràn, tá a sì nífẹ̀ẹ́ orúkọ rẹ̀ (Sm 81:13, 16)

Kí ìwà wa tó lè fìyìn fún Jèhófà, a gbọ́dọ̀ jẹ́ káwọn èèyàn mọ̀ pé Ẹlẹ́rìí Jèhófà ni wá

2. Àwọn Ẹ̀kọ́ Iyebíye Míì

(10 min.)

  • Sm 80:1—Kí nìdí tí Bíbélì fi máa ń lo orúkọ Jósẹ́fù nígbà míì láti tọ́ka sí àwọn ẹ̀yà Ísírẹ́lì lápapọ̀? (it-2 111)

  • Àwọn ẹ̀kọ́ iyebíye wo lo rí nínú Bíbélì kíkà ọ̀sẹ̀ yìí tí wàá fẹ́ sọ?

3. Bíbélì Kíkà

TẸRA MỌ́ IṢẸ́ ÌWÀÁSÙ

4. Bá A Ṣe Lè Bẹ̀rẹ̀ Ọ̀rọ̀ Wa

(1 min.) ÌWÀÁSÙ ILÉ-DÉ-ILÉ. Fi ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì lọ ẹni náà. (lmd ẹ̀kọ́ 4 kókó 4)

5. Bá A Ṣe Lè Bẹ̀rẹ̀ Ọ̀rọ̀ Wa

(3 min.) ÌWÀÁSÙ ÀÌJẸ́-BÍ-ÀṢÀ. Fi ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì lọ ẹni náà. (lmd ẹ̀kọ́ 4 kókó 3)

6. Bá A Ṣe Lè Bẹ̀rẹ̀ Ọ̀rọ̀ Wa

(2 min.) ÌWÀÁSÙ NÍBI TÍ ÈRÒ PỌ̀ SÍ. Fi ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì lọ ẹni náà. (lmd ẹ̀kọ́ 3 kókó 3)

7. Pa Dà Lọ

(5 min.) ÌWÀÁSÙ ILÉ-DÉ-ILÉ. Fi ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì lọ ẹnì kan tí ò gbà láti kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì tẹ́lẹ̀ bó tiẹ̀ jẹ́ pé ó nífẹ̀ẹ́ sí ọ̀rọ̀ wa. (lmd ẹ̀kọ́ 8 kókó 3)

MÁA HÙWÀ TÓ YẸ KRISTẸNI

Orin 10

8. “Wọ́n Máa Sọ Orúkọ Mi Di Mímọ́”

(15 min.) Ìjíròrò.

Inú ọgbà Édẹ́nì ni Sátánì ti kọ́kọ́ ba Jèhófà lórúkọ jẹ́. Látìgbà yẹn ló ti jẹ́ pé bí Ọlọ́run ṣe máa dá orúkọ ẹ̀ láre lohun tó ṣe pàtàkì jù sáwọn áńgẹ́lì àtàwa èèyàn.

Ọ̀pọ̀lọpọ̀ irọ́ burúkú ni Sátánì ti pa mọ́ Jèhófà. Bí àpẹẹrẹ, ó fẹ̀sùn kan Ọlọ́run pé ìkà ni àti pé kì í ṣe alákòóso rere. (Jẹ 3:1-6; Job 4:18, 19) Ó tiẹ̀ tún sọ pé torí ohun táwọn ìránṣẹ́ Jèhófà máa rí gbà lọ́wọ́ ẹ̀ ni wọ́n ṣe ń sìn ín. (Job 2:4, 5) Ó tún mú kí ọ̀pọ̀ mílíọ́nù èèyàn gbà pé Jèhófà kọ́ ló dá gbogbo nǹkan.—Ro 1:20, 21.

Báwo làwọn irọ́ tí Sátánì pa yìí ṣe rí lára ẹ? Ó lè máa ṣe ẹ́ bíi pé kó o já àwọn irọ́ yìí kó o sì jẹ́ káwọn èèyàn mọ ohun tó jẹ́ òótọ́ nípa Jèhófà. Jèhófà mọ̀ pé àwọn ìránṣẹ́ òun máa ṣe gbogbo ohun tí wọ́n lè ṣe láti sọ orúkọ òun di mímọ́. (Fi wé Àìsáyà 29:23.) Báwo nìwọ náà ṣe lè ṣe bẹ́ẹ̀?

  • Ran àwọn èèyàn lọ́wọ́ kí wọ́n lè mọ Jèhófà, kí wọ́n sì nífẹ̀ẹ́ rẹ̀. (Jo 17:25, 26) Ṣàlàyé àwọn ẹ̀rí táá jẹ́ kó dá wọn lójú pé Ọlọ́run wà lóòótọ́, kó o sì jẹ́ kí wọ́n mọ irú ẹni tó jẹ́ àtàwọn ohun rere tó ti ṣe.—Ais 63:7

  • Fi gbogbo ọkàn rẹ nífẹ̀ẹ́ Jèhófà. (Mt 22:37, 38) Máa pa àwọn òfin Jèhófà mọ́, kì í ṣe torí pé wọ́n máa ṣe ẹ́ láǹfààní nìkan àmọ́ torí pé o fẹ́ múnú Jèhófà dùn.—Owe 27:11

Jẹ́ kí àwọn ará wo FÍDÍÒ Má Ṣe Jẹ́ Kí Ìfẹ́ Rẹ Yẹ̀ Láé . . . Bó O Tiẹ̀ Ń Kojú Ìṣòro Nílé Ìwé. Lẹ́yìn náà, béèrè pé:

  • Báwo ni Ariel àti Diego ṣe gbèjà orúkọ Jèhófà?

  • Kí ló ràn wọ́n lọ́wọ́ láti gbèjà orúkọ Jèhófà?

  • Báwo lo ṣe lè tẹ̀ lé àpẹẹrẹ wọn?

9. Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Ìjọ

Ọ̀rọ̀ Ìparí (3 min.) | Orin 90 àti Àdúrà