Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

September 23-29

SÁÀMÙ 88-89

September 23-29

Orin 22 àti Àdúrà | Ọ̀rọ̀ Ìbẹ̀rẹ̀ (1 min.)

ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN

1. Ìṣàkóso Jèhófà Ló Dáa Jù

(10 min.)

Ìṣàkóso Jèhófà máa mú ìdájọ́ òdodo wá (Sm 89:14; w17.06 28 ¶5)

Ìṣàkóso Jèhófà máa mú káwọn èèyàn láyọ̀ (Sm 89:15, 16; w17.06 29 ¶10-11)

Ìṣàkóso Jèhófà máa wà títí láé (Sm 89: 34-37; w14 10/15 10 ¶14)

Tá a bá ń ronú lórí bí ìṣàkóso Jèhófà ṣe dáa tó, ìyẹn ò ní jẹ́ ká dá sí ọ̀rọ̀ òṣèlú

2. Àwọn Ẹ̀kọ́ Iyebíye Míì

(10 min.)

  • Sm 89:37 —Kí ni ìyàtọ̀ tó wà láàárín bí òṣùpá ṣe jẹ́ adúróṣinṣin àti bí àwa èèyàn ṣe lè jẹ́ adúróṣinṣin? (cl 281 ¶4-5)

  • Àwọn ẹ̀kọ́ iyebíye wo lo rí nínú Bíbélì kíkà ọ̀sẹ̀ yìí tí wàá fẹ́ sọ?

3. Bíbélì Kíkà

TẸRA MỌ́ IṢẸ́ ÌWÀÁSÙ

4. Bá A Ṣe Lè Bẹ̀rẹ̀ Ọ̀rọ̀ Wa

(3 min.) ÌWÀÁSÙ NÍBI TÍ ÈRÒ PỌ̀ SÍ. Fi ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì lọ ẹni tí kì í ṣe Kristẹni. (lmd ẹ̀kọ́ 5 kókó 5)

5. Pa Dà Lọ

(4 min.) ÌWÀÁSÙ ILÉ-DÉ-ILÉ. Fi bá a ṣe ń ṣe ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì hàn án. (th ẹ̀kọ́ 9)

6. Ṣàlàyé Ohun Tó O Gbà Gbọ́

(5 min.) Àsọyé. ijwbq 181—Àkòrí: Kí Ni Bíbélì Dá Lé? (th ẹ̀kọ́ 2)

MÁA HÙWÀ TÓ YẸ KRISTẸNI

Orin 94

7. Àwọn Ìlànà Jèhófà Ló Dáa Jù

(10 min.) Ìjíròrò.

Ọ̀pọ̀ èèyàn máa ń wo ìlànà Bíbélì nípa ìbálòpọ̀ àti ìgbéyàwó bí ohun tó ti le koko jù tí kò sì bágbà mu mọ́. Ṣé ó dá ẹ lójú pé tó o bá ń tẹ̀ lé àwọn ìlànà Jèhófà, ó máa ṣe ẹ́ láǹfààní?—Ais 48:17, 18; Ro 12:2.

Bíbélì jẹ́ ká mọ̀ pé àwọn tí kò tẹ̀ lé ìlànà Ọlọ́run “kò ní jogún Ìjọba Ọlọ́run.” (1Kọ 6:9, 10) Àmọ́, ṣé torí àtijogún Ìjọba Ọlọ́run nìkan ló fi yẹ ká máa tẹ̀ lé ìlànà Ọlọ́run?

Jẹ́ kí àwọn ará wo FÍDÍÒ Jẹ́ Kí Ohun Tó O Gbà Gbọ́ Dá Ẹ Lójú—Ṣé Ìlànà Ọlọ́run Ni Màá Tẹ̀ Lé àbí Èrò Ara Mi. Lẹ́yìn náà béèrè pé:

  • Báwo làwọn ìlànà Jèhófà ṣe ń dáàbò bò wá?

8. Ohun Tó Ń Fẹ́ Àbójútó Nínú Ìjọ

(5 min.)

9. Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Ìjọ

(30 min.) bt orí 15 ¶15-20

Ọ̀rọ̀ Ìparí (3 min.) | Orin 133 àti Àdúrà