September 30–October 6
SÁÀMÙ 90-91
Orin 140 àti Àdúrà | Ọ̀rọ̀ Ìbẹ̀rẹ̀ (1 min.)
1. Gbẹ́kẹ̀ Lé Jèhófà, Tó O Bá Fẹ́ Kí Ẹ̀mí Ẹ Gùn
(10 min.)
Kò sóhun táwa èèyàn lè ṣe láti mú kí ẹ̀mí wa gùn sí i (Sm 90:10; wp19.3 5 ¶2-4)
Jèhófà ti wà “láti ayérayé dé ayérayé” (Sm 90:2; wp19.1 5, àpótí)
Ó lágbára láti fún àwọn tó bá gbẹ́kẹ̀ lé e ní ìyè àìnípẹ̀kun, ó sì máa ṣe bẹ́ẹ̀ (Sm 21:4; 91:16)
Má ṣe gba ìtọ́jú tó ta ko ìlànà Bíbélì, torí ìyẹn lè ba àjọṣe ìwọ àti Jèhófà jẹ́.—w22.06 18 ¶16-17.
2. Àwọn Ẹ̀kọ́ Iyebíye Míì
(10 min.)
3. Bíbélì Kíkà
(4 min.) Sm 91:1-16 (th ẹ̀kọ́ 10)
4. Bá A Ṣe Lè Bẹ̀rẹ̀ Ọ̀rọ̀ Wa
(3 min.) ÌWÀÁSÙ ÀÌJẸ́-BÍ-ÀṢÀ. Láì kọ́kọ́ sọ̀rọ̀ nípa Bíbélì, máa bá ẹnì kan sọ̀rọ̀ títí wàá fi mọ ohun tó wà lọ́kàn ẹ̀, kó o lè mọ ìmọ̀ràn Bíbélì tó o lè fi ràn án lọ́wọ́. (lmd ẹ̀kọ́ 1 kókó 3)
5. Bá A Ṣe Lè Bẹ̀rẹ̀ Ọ̀rọ̀ Wa
(4 min.) ÌWÀÁSÙ ÀÌJẸ́-BÍ-ÀṢÀ. (lmd ẹ̀kọ́ 1 kókó 4)
6. Àsọyé
(5 min.) lmd àfikún A kókó 5—Àkòrí: Àwọn Èèyàn Á Máa Gbé Ayé Títí Láé. (th ẹ̀kọ́ 14)
Orin 158
7. Ṣé O Mọyì Bí Sùúrù Ọlọ́run Ṣe Pọ̀ Tó?—Ojú Tí Jèhófà Fi Ń Wo Àkókò
(5 min.) Ìjíròrò.
Jẹ́ kí àwọn ará wo FÍDÍÒ náà. Lẹ́yìn náà, béèrè pé:
-
Tá a bá ronú lórí bí Jèhófà ṣe ń fi sùúrù ṣe nǹkan lákòókò tó yẹ, báwo nìyẹn ṣe máa jẹ́ ká lè máa fi sùúrù dúró títí táá fi mú àwọn ìlérí rẹ̀ ṣẹ?
8. Ohun Tí Ètò Ọlọ́run Ti Ṣe ti oṣù September
(10 min.) Jẹ́ kí àwọn ará wo FÍDÍÒ náà.
9. Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Ìjọ
(30 min.) bt orí 16 ¶1-5, àpótí ojú ìwé 128