Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

September 9-15

SÁÀMÙ 82-84

September 9-15

Orin 80 àti Àdúrà | Ọ̀rọ̀ Ìbẹ̀rẹ̀ (1 min.)

ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN

Ọ̀kan lára àwọn ọmọ Kórà ń wo ìtẹ́ ẹyẹ alápàáǹdẹ̀dẹ̀ tó wà ní àgbàlá tẹ́ńpìlì

1. Mọyì Ohunkóhun Tó O Bá Ń Ṣe Lẹ́nu Iṣẹ́ Ìsìn Jèhófà

(10 min.)

A mọyì iṣẹ́ ìsìn èyíkéyìí tá a bá láǹfààní láti ṣe (Sm 84:1-3; wp16.6 8 ¶2-3)

Máa fayọ̀ ṣe iṣẹ́ èyíkéyìí tó o bá ní nínú ètò Ọlọ́run dípò tí wàá fi máa ronú ṣáá lórí èyí tó wù ẹ́ kó o ní (Sm 84:10; w08 7/15 30 ¶3-4)

Jèhófà máa ń ṣojú rere sí gbogbo àwọn tó ń sìn ín tọkàntọkàn (Sm 84:11; w20.01 17 ¶12)

Kò sí iṣẹ́ ìsìn tí kò ní ìbùkún àti ìṣòro tiẹ̀. Tó o bá ń ronú nípa àwọn àǹfààní tó wà níbẹ̀, kò sí iṣẹ́ ìsìn tó ò ní gbádùn.

2. Àwọn Ẹ̀kọ́ Iyebíye Míì

(10 min.)

  • Sm 82:3—Kí nìdí tó fi ṣe pàtàkì pé ká máa fìfẹ́ hàn sáwọn “ọmọ aláìníbaba” tó wà nínú ìjọ? (it-1 816)

  • Àwọn ẹ̀kọ́ iyebíye wo lo rí nínú Bíbélì kíkà ọ̀sẹ̀ yìí tí wàá fẹ́ sọ?

3. Bíbélì Kíkà

TẸRA MỌ́ IṢẸ́ ÌWÀÁSÙ

4. Máa Fọ̀rọ̀ Ro Ara Ẹ Wò—Ohun Tí Jésù Ṣe

(7 min.) Ìjíròrò. Jẹ́ kí àwọn ará wo FÍDÍÒ náà, kẹ́ ẹ sì jíròrò lmd ẹ̀kọ́ 9 kókó 1-2.

5. Máa Fọ̀rọ̀ Ro Ara Ẹ Wò—Tẹ̀ Lé Àpẹẹrẹ Jésù

(8 min.) Ìjíròrò tó dá lórí lmd ẹ̀kọ́ 9 kókó 3-5 àti “Tún Wo.”

MÁA HÙWÀ TÓ YẸ KRISTẸNI

Orin 57

6. Ohun Tó Ń Fẹ́ Àbójútó Nínú Ìjọ

(15 min.)

7. Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Ìjọ

Ọ̀rọ̀ Ìparí (3 min.) | Orin 130 àti Àdúrà