Ìwé Ìròyìn Ilé Ìṣọ́ àti Jí
Àwọn ìwé ìròyìn wa tá a gbé ka Bíbélì wà lórí Íńtánẹ́ẹ̀tì, o lè wà wọ́n jáde ní ọgọ́rọ̀ọ̀rún èdè, èdè àwọn adití náà wà níbẹ̀. Ìwé ìròyìn Ilé Ìṣọ́ ń jẹ́ ká rí bí àwọn àsọtẹ́lẹ̀ Bíbélì ṣe ń nímùúṣẹ lóde òní. Ó ń fi ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run tu àwọn èèyàn nínú, ó sì ń jẹ́ kéèyàn túbọ̀ nígbàgbọ́ nínú Jésù Kristi. Ìwé ìròyìn Jí! ń jẹ́ ká mọ bá a ṣe lè kápá àwọn ìṣòro òde òní, ó sì ń mú kéèyàn túbọ̀ gbà pé Ẹlẹ́dàá wa máa mú ayé tuntun wá, níbi tí alálàáfíà àti ààbò máa wà, gẹ́gẹ́ bó ṣe ṣèlérí.
Yan èdè tó o bá fẹ́ nínú àpótí kékeré tá a ti ń yan èdè, lẹ́yìn náà kó o tẹ Wá a, tó o bá ti tẹ̀ ẹ́, wà á rí àwọn ìwé ìròyìn ní oríṣiríṣi ọ̀nà.