Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Èé Ṣe Tí Ìfẹ́ Fi Ń Pòórá?

Èé Ṣe Tí Ìfẹ́ Fi Ń Pòórá?

Èé Ṣe Tí Ìfẹ́ Fi Ń Pòórá?

“Ó jọ pé ó rọrùn gan-an láti bẹ̀rẹ̀ nínífẹ̀ẹ́ ẹnì kan ju mímú kí ìfẹ́ yẹn máa bá a nìṣó.”—Ọ̀MỌ̀WÉ KAREN KAYSER.

PÍPỌ̀ tí àwọn ìgbéyàwó tí kò ti sí ìfẹ́ ń pọ̀ sí i kò fi bẹ́ẹ̀ yani lẹ́nu. Oríṣi àjọṣe kan tó díjú gbáà ni ìgbéyàwó jẹ́ láàárín àwọn èèyàn, ọ̀pọ̀ èèyàn ló sì ń kó wọnú rẹ̀ láìsí ìmúrasílẹ̀ tí ó tó. Dókítà Dean S. Edell sọ pé: “Wọ́n máa ń fẹ́ ká fi hàn kedere pé a tóótun dáadáa táa bá fẹ́ gba ìwé àṣẹ ìwakọ̀, ṣùgbọ́n táa bá fẹ́ gba ìwé ẹ̀rí ìgbéyàwó, tìrọ̀rùntìrọ̀rùn la fi máa ń buwọ́ lùwé.”

Nítorí náà, bó tilẹ̀ jẹ́ pé ọ̀pọ̀ ìgbéyàwó ń ṣe dáadáa, tí wọ́n sì jẹ́ aláyọ̀ lóòótọ́, nǹkan kò rọgbọ fún àwọn kan. Ó lè jẹ́ pé àwọn tọkọtaya kan tàbí ẹnì kan nínú àwọn méjèèjì wọnú ìgbéyàwó pẹ̀lú ìrètí pé nǹkan á dára ṣùgbọ́n tí wọn kò mọ àwọn ohun tí wọ́n lè ṣe tí ìbágbépọ̀ wọn yóò fi tọ́jọ́. Ọ̀mọ̀wé Harry Reis sọ pé: “Nígbà tí àwọn èèyàn bá kọ́kọ́ bẹ̀rẹ̀ sí rìn mọ́ ara wọn, ọkàn wọ́n máa ń balẹ̀ nípa ara wọn gan-an.” Wọ́n máa ń rò pé ẹnì kejì àwọn “nìkan ni èrò rẹ̀ bá tàwọn mu ní gbogbo ayé. Èrò yẹn máa ń ṣá nígbà míì, tó bá sì rí bẹ́ẹ̀, ó lè ṣàkóbá fún ìgbéyàwó náà.”

A dúpẹ́ pé ọ̀rọ̀ kò burú tó bẹ́ẹ̀ yẹn nínú ọ̀pọ̀ ìgbéyàwó. Ṣùgbọ́n ẹ jẹ́ ká wo díẹ̀ lára àwọn ohun tó ti mú kí ìfẹ́ pòórá nínú àwọn ọ̀ràn kan.

Ìjákulẹ̀—“Ohun Tí Mo Retí Kọ́ Yìí”

Rose sọ pé: “Nígbà tí mo fẹ́ Jim, mo rò pé èkùrọ́ lalábàákú ẹ̀wà—pé a óò máa fara rora, a óò máa ṣera wa ní jẹ̀lẹ́ńkẹ́, a óò sì máa gba ti ara wa rò ni.” Ṣùgbọ́n kò pẹ́ tó fi di pé ẹni tí Rose gba tiẹ̀ gan-an tẹ́lẹ̀ kò dára lójú rẹ̀ mọ́. Ó sọ pé: “Ó wá já mi kulẹ̀ pátápátá.”

Ọ̀pọ̀ sinimá, ìwé, àti àwọn orin tó wọ́pọ̀ kì í sọ òótọ́ nípa ìfẹ́. Nígbà tí ọkùnrin àti obìnrin kan bá ń fẹ́ ara wọn sọ́nà, wọ́n lè máa rò pé àlá àwọn ti ṣẹ; ṣùgbọ́n lẹ́yìn ọdún mélòó kan tí wọ́n bá ti ṣègbéyàwó, wọ́n máa ń sọ pé àlá lásán làwọ́n ń lá nígbà yẹn! Bí ohun téèyàn kà nínú ìwé ìtàn nípa ìfẹ́ kò bá ṣẹlẹ̀ nínú ìgbéyàwó ẹni, ìgbéyàwó tó tòrò lè dà bí èyí tó forí ṣánpọ́n.

Lóòótọ́, kò burú láti fojú sọ́nà fún àwọn ohun kan nínú ìgbéyàwó. Fún àpẹẹrẹ, ohun tó bójú mu ni láti retí pé kí ẹni tí a fẹ́ nífẹ̀ẹ́ ẹni, kó fúnni láfiyèsí, kó sì tini lẹ́yìn. Ṣùgbọ́n àwọn ohun tí a retí wọ̀nyí tiẹ̀ lè má ṣẹlẹ̀. Ọ̀ṣọ́ọ́rọ́ ìyàwó kan ní Íńdíà, tórúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Meena, sọ pé: “Díẹ̀ ló kù kó rí lára mi bíi pé mi ò tíì relé ọkọ. Mo nìkan wà, mo di ẹni ìpatì.”

Àìbáramu—“Kò Sóhun Táa Fi Bára Mu”

Obìnrin kan sọ pé: “Ó fẹ́rẹ̀ẹ́ máà sí ohun tí èmi àti ọkọ mi fohùn ṣọ̀kan lé lórí. Kó sọ́jọ́ kan tó kọjá rí tí mi ò kábàámọ̀ gidigidi pé mo fẹ́ ẹ. A ò tiẹ̀ bára wa mu rárá ni.”

Ó sábà máa ń ṣẹlẹ̀ pé kì í pẹ́ kí tọkọtaya kan tó mọ̀ pé àwọn ò fi bẹ́ẹ̀ bára mu tó bí àwọn ṣe rò nígbà tí àwọn ń fẹ́ ara àwọn sọ́nà. Ọ̀mọ̀wé Nina S. Fields kọ̀wé pé: “Ìgbéyàwó sábà máa ń fi àwọn ànímọ́ tí tọkọtaya fúnra wọn kò mọ̀ pé àwọn ní nígbà tí wọn kò tíì ṣègbéyàwó hàn.”

Èyí ló ń fà á tí àwọn tọkọtaya kan fi lè máa rò pé àwọn ò bára mu rárá lẹ́yìn tí wọ́n bá ti ṣègbéyàwó. Dókítà Aaron T. Beck sọ pé: “Láìka ti pé ọ̀pọ̀ èèyàn ló ní àwọn ànímọ́ tó jọra sí, tí wọ́n bá ṣègbéyàwó, wọ́n á wá rí i pé ọ̀nà tí wọ́n ń gbà ṣe nǹkan, ìwà wọn, àti ìṣesí wọn máa ń yàtọ̀.” Ọ̀pọ̀ tọkọtaya ni kò mọ bí wọ́n ṣe lè jíròrò nípa àwọn ìyàtọ̀ yẹn.

Ìjà—“Ìgbà Gbogbo La Máa Ń Ja Ara Wa Níyàn”

“Ẹnu yà wá pé a ń jà gan-an—a máa ń kígbe rara, èyí tó sì burú jù ni pé a kì í sọ̀rọ̀ síra wa fún ọ̀pọ̀ ọjọ́ nítorí pé inú ń bí wa.” Ohun tí Cindy sọ pé ó ṣẹlẹ̀ nígbà tí wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ ṣègbéyàwó nìyẹn.

Kò sí kí àìfohùnṣọ̀kan máà ṣẹlẹ̀ nínú ìgbéyàwó. Ṣùgbọ́n báwo ni a ṣe ń yanjú wọn? Ọ̀mọ̀wé Daniel Goleman kọ̀wé pé: “Nínú ìgbéyàwó rere, ọkọ àti ìyàwó kì í lọ́ra láti sọ ẹ̀dùn ọkàn wọn. Ṣùgbọ́n ó sábà máa ń ṣẹlẹ̀ pé tí inú bá ń bí èèyàn, ọ̀nà tí a máa ń gbà sọ ẹ̀dùn ọkàn wa jáde máa ń dun ẹnì kejì, bí ìgbà tí a ń sọ̀kò ọ̀rọ̀ lù ú fún ohun tó ṣe.”

Nígbà tí èyí bá ṣẹlẹ̀, ẹnì kìíní kejì á múra tán láti lo àkókò ìjùmọ̀sọ̀rọ̀ láti fi gbe èrò tirẹ̀ lẹ́yìn, wọ́n á wá máa sọ̀kò ọ̀rọ̀ lu ara wọn dípò kí wọ́n máa jíròrò ọ̀rọ̀. Àwùjọ àwọn ògbógi kan sọ pé: “Ọ̀kan lára àwọn ohun tó ń ba nǹkan jẹ́ jù lọ nínú iyàn jíjà tó le débi tí agbára ò ká a mọ́ ni pé, ó jọ pé àwọn tọkọtaya máa ń sọ àwọn nǹkan tó ń ṣèpalára fún ohun tó ṣe pàtàkì jù lọ nínú ìgbéyàwó wọn.”

Ẹ̀mí Ìdágunlá—“Ó Ti Sú Wa”

Obìnrin kan sọ lẹ́yìn ọdún márùn-ún tó ti ṣègbéyàwó pé: “Ọ̀ràn gbígbìyànjú láti mú kí ìgbéyàwó wa gún régé ti sú mi. Mo mọ̀ pé kò lè ṣeé ṣe mọ́ nísinsìnyí. Nítorí náà, ohun tó jẹ mí lógún ni ti àwọn ọmọ mi.”

Wọ́n ti máa ń sọ ọ́ pé kì í ṣe ìkórìíra ni òdì kejì ìfẹ́ ní ti gidi bí kò ṣe ìdágunlá. Ní tòótọ́, ìwà ìdágunlá lè ṣe irú ìbàjẹ́ kan náà tí ìwà jàgídíjàgan ń ṣe nínú ìgbéyàwó.

Bó ti wù kó rí, ó bani nínú jẹ́ pé wíwà nínú ìdè ìgbéyàwó tí kò ti sí ìfẹ́ ti mọ́ àwọn tọkọtaya kan lára gan-an débi pé wọn kò ní ìrètí pé nǹkan lè dára rárá. Fún àpẹẹrẹ, ọkọ kan sọ pé ńṣe ni ìgbéyàwó tí òun ti ṣe láti ọdún mẹ́tàlélógún sẹ́yìn dà bí pé “èèyàn ń ṣe iṣẹ́ tí kò tẹ́ ẹ lọ́rùn.” Ó fi kún un pé: “Bọ́ràn bá ti rí báyìí, ìwọ̀nba ohun tágbára ẹ bá ká ni wàá ṣe.” Bákan náà, ìyàwó kan tó ń jẹ́ Wendy kò fọkàn sí pé àárín òun àti ọkọ tó ti fẹ́ fún ọdún méje tún lè dán mọ́rán mọ́. Ó sọ pé: “Mo gbìyànjú lọ́pọ̀ ìgbà, ṣùgbọ́n ńṣe ló máa ń já mi kulẹ̀. Ìbànújẹ́ ló gbẹ̀yìn rẹ̀ fún mi. N kò fẹ́ kí irú rẹ̀ tún ṣẹlẹ̀ sí mi mọ́. Bí mo bá lọ ń retí pé nǹkan á dára, màá kàn máa bara mi nínú jẹ́ ni. Ó sàn kí n kúkú má retí ohunkóhun—mo mọ̀ pé inú mi ò ní dùn dáadáa o, ṣùgbọ́n inú mi ò ṣáà ní bà jẹ́.”

Ìjákulẹ̀, àìbáramu, ìjà, àti ẹ̀mí ìdágunlá wulẹ̀ jẹ́ díẹ̀ lára àwọn ohun tó lè mú kó máà sí ìfẹ́ nínú ìgbéyàwó ni. Ó hàn gbangba pé ó ṣì ku ọ̀pọ̀ nǹkan tó ń fà á, a sì kọ díẹ̀ lára wọn sínú àpótí tó wà ní ojú ìwé 5. Láìka ohun tó fà á sí, ǹjẹ́ ìrètí kankan wà fún àwọn tọkọtaya tó jọ pé wọ́n ti há sínú ìgbéyàwó kan tí kò ti sí ìfẹ́?

[Àpótí/Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 5]

ÀÌSÍFẸ̀Ẹ́ NÍNÚ ÌGBÉYÀWÓ—ÀWỌN OHUN MÌÍRÀN TÓ Ń FÀ Á

Owó: “Èèyàn lè fojú inú wò ó pé ṣíṣe ìwéwèé ìnáwó yóò mú tọkọtaya ṣọ̀kan nínú àwọn ọ̀ràn pípọndandan bíi fífọwọ́sowọ́pọ̀, pípawọ́pọ̀ ra àwọn ohun kòṣeémánìí, àti gbígbádùn èrè làálàá wọn. Ṣùgbọ́n ó tún máa ń ṣẹlẹ̀ pé ohun tó lè mú kí tọkọtaya ṣọ̀kan nínú pípawọ́pọ̀ ṣe nǹkan ló sábà máa ń da àárín wọn rú.”—Ọ̀mọ̀wé Aaron T. Beck.

Jíjẹ́ Òbí: “A ti ṣàwárí pé ìpín mẹ́tàdínláàádọ́rin lára àwọn tọkọtaya ni kì í ní ìtẹ́lọ́rùn nínú ìgbéyàwó wọn mọ́ lẹ́yìn tí wọ́n bá ti bí ọmọ wọn àkọ́kọ́, ìjà sì máa ń ṣẹlẹ̀ ní ìlọ́po mẹ́jọ ju ti tẹ́lẹ̀ lọ. Lápá kan, èyí jẹ́ nítorí pé jíjẹ́ òbí ti sú wọn, àti pé wọn kò ráyè fún ara wọn mọ́.”—Ọ̀mọ̀wé John Gottman.

Ẹ̀tàn: “Ẹ̀tàn sábà máa ń bá àìṣòótọ́ nínú ìgbéyàwó rìn, tí a kò bá sì fẹ́ fọ̀rọ̀ sábẹ́ ahọ́n sọ, ohun tí ẹ̀tàn túmọ̀ sí ni dída ẹni tó gbẹ́kẹ̀ léni. Níwọ̀n bí a ti mọ̀ dájú pé ìgbẹ́kẹ̀lé jẹ́ ọ̀kan pàtàkì nínú gbogbo ìgbéyàwó tó kẹ́sẹ járí, tó sì tọ́jọ́, ṣé ó wá yẹ kó yani lẹ́nu pé ẹ̀tàn lè dá yánpọnyánrin sílẹ̀ nínú ìdè ìgbéyàwó?”—Ọ̀mọ̀wé Nina S. Fields.

Ìbálòpọ̀: “Nígbà tí tọkọtaya bá kọ̀wé wá pé àwọn fẹ́ kọ ara àwọn, ohun tó wọ́pọ̀, tó sì máa ń bani lẹ́rù níbẹ̀ ni pé kì í ṣe ọdún kan kì í ṣe ọdún méjì tí wọn ò ti bára wọn lòpọ̀ mọ́. Ìbálòpọ̀ kò tiẹ̀ rídìí fi múlẹ̀ láàárín àwọn kan, ní ti àwọn mìíràn, kì í wá látinú ọkàn wọn, kí wọ́n ṣáà ti jẹ́ kí ẹnì kejì wọn ṣe ohun tó fẹ́ ṣe ni.”—Judith S. Wallerstein, ọ̀mọ̀ràn nínú iṣẹ́ ìfìṣemọ̀rònú.

[Àpótí/Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 6]

IPA WO LÓ Ń NÍ LÓRÍ ÀWỌN ỌMỌ?

Ǹjẹ́ ohun tó ń ṣẹlẹ̀ nínú ìgbéyàwó yín lè nípa lórí àwọn ọmọ yín? Ọ̀rọ̀ tí Ọ̀mọ̀wé John Gottman, tó ṣèwádìí ọ̀ràn nípa àwọn tọkọtaya fún nǹkan bí ogún ọdún sọ fi hàn pé bẹ́ẹ̀ ni. Ó sọ pé: “Nínú ìwádìí tí a fi ogún ọdún ṣe, a ṣàwárí pé ìwọ̀n ìlùkìkì ọkàn-àyà àwọn ọmọ ọwọ́ tí àwọn òbí wọn kò láyọ̀ máa ń ga jù nígbà tí àwọn èèyàn bá ń bá wọn ṣeré, wọn kì í sì í lè tẹ́ ara wọn lọ́rùn. Bí ọjọ́ ti ń gorí ọjọ́, àwọn ìjà tó ń ṣẹlẹ̀ nínú ìgbéyàwó kì í jẹ́ kí àwọn ọmọ ṣe dáadáa nílé ìwé bó ti wù kí wọ́n jáfáfá tó.” Ní òdì kejì èyí, Ọ̀mọ̀wé Gottman sọ pé, àwọn ọmọ táwọn tọkọtaya tí àárín wọ́n gún régé bí “máa ń ṣe dáadáa nílé ìwé àti láàárín àwọn ẹgbẹ́ wọn, nítorí pé àwọn òbí wọn ti fi hàn wọ́n bó ṣe yẹ kí wọ́n máa bọ̀wọ̀ fún àwọn ẹlòmíràn àti bó ṣe yẹ kí wọ́n máa yanjú ọ̀ràn tí inú bá bí wọn.”