Ẹ̀kọ́ Tó Wúlò Títí Ayé
Ẹ̀kọ́ Tó Wúlò Títí Ayé
“Bíbélì [ni] atọ́nà tó ga jù lọ fún gbígbé ìgbésí ayé.”—Thomas Tiplady, 1924.
KÌ Í ṢE àsọdùn rárá táa bá sọ pé ẹ̀kọ́ táa gbé karí Bíbélì máa ń yí ìgbésí ayé padà. Ó ti mú kí àwọn tí ìgbésí ayé wọn kò já mọ́ nǹkan nígbà kan rí, tó sì kún fún wàhálà di ẹni tí ìgbésí ayé wọn wá nítumọ̀ tó sì kún fún ìrètí. Òbí kan tó jẹ́ anìkantọ́mọ láti orílẹ̀-èdè Namibia kọ̀wé sí ẹ̀ka ọ́fíìsì àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó wà ní Gúúsù Áfíríkà pé:
“Ẹni ọdún mọ́kàndínlọ́gbọ̀n ni mí, kò sì ju ọjọ́ méjì péré ti mo fi ka ìwé náà, Awọn Ìbéèrè Tí Awọn Ọ̀dọ́ Ń Béèrè—Awọn Ìdáhùn Tí Ó Gbéṣẹ́, tán. Ó wọ̀ mí lọ́kàn gan-an ni nítorí mi ò ní alábàárò kankan. Ẹni tí mo bímọ fún kú nínú jàǹbá ọkọ̀ ayọ́kẹ́lẹ́, ó sì fi àwọn ọmọ kéékèèké méjì sílẹ̀ fún mi. Ìyà tó ń jẹ wá kúrò ní kèrémí. Nígbà míì, mo máa ń rò ó pé ó kúkú sàn kí n pa wọ́n, kí èmi náà sì pa ara mi. Ṣùgbọ́n nígbà ti mo rí ìwé yìí, mo pèrò mi dà. Ẹ jọ̀wọ́, ẹ ràn mí lọ́wọ́, ẹ wá bá mi ṣèkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì lọ́fẹ̀ẹ́.”
Bíbélì jẹ́ ìwé atọ́nà tó lè ran àwọn èèyàn lọ́wọ́ láti ṣàṣeyọrí ní gbogbo apá ìgbésí ayé wọn—nínú àjọṣe wọn pẹ̀lú ìdílé wọn, pẹ̀lú àwọn òṣìṣẹ́ ẹlẹgbẹ́ wọn, àtàwọn tí wọ́n jọ ń gbé ládùúgbò. (Sáàmù 19:7; 2 Tímótì 3:16) Ó ń fúnni ní ìtọ́sọ́nà tó jíire nípa béèyàn ṣe lè lépa ohun tó dára kí ó sì yàgò fún ohun tó burú. Ìwé kan tó dìídì ń sọ bí a ṣe lè kojú ọ̀ràn ìgbésí ayé ni. Bóo ti ń kà á, bẹ́ẹ̀ ni wàá máa rí i pé àkọsílẹ̀ àwọn ènìyàn tó ti gbé ayé rí ló kún inú rẹ̀. Wàá rí nǹkan tó mú kí ìgbésí ayé àwọn kan láyọ̀ kó sì lérè, tí tàwọn kan sì jẹ́ kìkì wàhálà àti ìbànújẹ́. Àwọn nǹkan tó ní láárí àtèyí tí kò wúlò á wá di èyí tó hàn sí ẹ kedere.
Ẹ̀kọ́ Tó Wúlò fún Ìgbésí Ayé Ìsinsìnyí
Bíbélì tẹnu mọ́ ìdí tí ọgbọ́n tó wúlò fi ṣe pàtàkì. Ó sọ pé: “Ọgbọ́n ni ohun ṣíṣe pàtàkì jù lọ. Òwe 4:7) Ó tún jẹ́ ká mọ̀ pé ọ̀pọ̀ ìgbà ni ẹ̀dá ènìyàn kì í ní ọgbọ́n, nítorí náà ó ṣí wa létí pé: “Bí ẹnikẹ́ni nínú yín bá ṣaláìní ọgbọ́n, kí ó máa bá a nìṣó ní bíbéèrè lọ́wọ́ Ọlọ́run, nítorí òun a máa fi fún gbogbo ènìyàn pẹ̀lú ìwà ọ̀làwọ́.”—Jákọ́bù 1:5.
Ní ọgbọ́n.” (Báwo ni Ẹlẹ́dàá wa, Jèhófà Ọlọ́run, ṣe ń fi ọgbọ́n fúnni pẹ̀lú ìwà ọ̀làwọ́? Nípasẹ̀ Ọ̀rọ̀ rẹ̀, Bíbélì ni, èyí tí ó ń rọ̀ wá pé kí á máa kà á. Ọlọ́run jírẹ̀ẹ́bẹ̀ pé: “Ọmọ mi, bí ìwọ yóò bá gba àwọn àsọjáde mi, tí ìwọ yóò sì fi àwọn àṣẹ tèmi ṣúra sọ́dọ̀ rẹ, láti lè dẹ etí rẹ sí ọgbọ́n . . . , ìwọ yóò lóye ìbẹ̀rù Jèhófà, ìwọ yóò sì rí ìmọ̀ Ọlọ́run gan-an. Nítorí Jèhófà fúnra rẹ̀ ní ń fúnni ní ọgbọ́n.” (Òwe 2:1, 2, 5, 6) Nígbà táa bá mú àmọ̀ràn táa rí nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run lò, táa sì wá rí bó ṣe wúlò tó, a ó mọ̀ pé lóòótọ́ ló fi ọgbọ́n Ọlọ́run hàn.
Fún àpẹẹrẹ, gbé ọ̀ràn kíkojú ìṣòro àìnílọ́wọ́ yẹ̀ wò. Bíbélì dámọ̀ràn iṣẹ́ àṣekára, ó sì kìlọ̀ pé ká yẹra fún àwọn àṣà fífi nǹkan tí kò tó tẹ́lẹ̀ ṣòfò. Nípa bẹ́ẹ̀, ó hàn kedere pé àwọn àṣàkaṣà bíi lílo tábà àti mímu ọtí nímukúmu kò sí ní ìbámu pẹ̀lú àwọn ìlànà Bíbélì.—Òwe 6:6-11; 10:26; 23:19-21; 2 Kọ́ríńtì 7:1.
Ní ti ipa táwọn táa ń bá kẹ́gbẹ́ lè ní lórí wa ńkọ́? Bíbélì sọ pé: “Ẹni tí ó bá ń bá àwọn ọlọ́gbọ́n rìn yóò gbọ́n, ṣùgbọ́n ẹni tí ó bá ń ní ìbálò pẹ̀lú àwọn arìndìn yóò rí láburú.” (Òwe 13:20) Ṣe ìwọ náà ti ṣàkíyèsí pé lọ́pọ̀ ìgbà lẹ̀mí ṣohun tẹ́gbẹ́ ń ṣe ti ti àwọn èèyàn—lọ́mọdé àti lágbà—sínú mímutí àmujù, jíjoògùnyó, àti ṣíṣe ìṣekúṣe? Òótọ́ ni o, táa bá ń bá àwọn tí wọ́n ń hu irú ìwà bẹ́ẹ̀ rìn, àwa náà á dà bíi wọn, àní gan-an bí Bíbélì ṣe wí pé: “Ẹgbẹ́ búburú a máa ba ìwà rere jẹ́.”—1 Kọ́ríńtì 15:33.
Dájúdájú, gbogbo wa la fẹ́ jẹ́ aláyọ̀. Ṣùgbọ́n báwo nìyẹn ṣe lè ṣeé ṣe? Ǹjẹ́ o mọ̀ pé Bíbélì sọ pé kì í ṣe níní àwọn nǹkan ló lè fúnni láyọ̀, kàkà bẹ́ẹ̀, ó jẹ́ nípa níní ìṣarasíhùwà àti àjọṣe bíbójúmu, pàápàá jù lọ níní àjọṣe rere pẹ̀lú Ọlọ́run? (1 Tímótì 6:6-10) Nínú Ìwàásù lílókìkí tí Jésù Kristi ṣe lórí Òkè, ó sọ pé àwọn tó láyọ̀ ní tòótọ́ ni àwọn tí “àìní wọn nípa ti ẹ̀mí ń jẹ lọ́kàn,” tí wọ́n jẹ́ “onínú tútù,” ‘tí òùngbẹ ń gbẹ wọ́n fún òdodo,’ tí wọ́n jẹ́ “aláàánú,” “àwọn ẹni mímọ́ gaara ní ọkàn-àyà,” àti àwọn “ẹlẹ́mìí àlàáfíà.”—Mátíù 5:1-9.
Nígbà tóo bá ronú jinlẹ̀ nípa àwọn ẹ̀kọ́ inú Bíbélì, wàá mọyì bí wọ́n ṣe lè ṣèrànwọ́ láti tọ́ wa sọ́nà nínú ìgbésí ayé wa. Gẹ́gẹ́ bí orísun ìmọ̀ràn, Bíbélì kò lẹ́gbẹ́. Kò sígbà tí ìmọ̀ràn rẹ̀ kì í ṣàǹfààní—kì í sọ̀rọ̀ tí kò gbéṣẹ́ bẹ́ẹ̀ ni kì í ṣèpalára fún wa. Àwọn tó máa ń fi ìmọ̀ràn Bíbélì sílò máa ń jàǹfààní nígbà gbogbo.
Ẹ̀kọ́ Tó Wúlò Títí Ayé
Síbẹ̀, ní àfikún sí pé ó ń ṣàǹfààní fún wa nísinsìnyí, Bíbélì tún fúnni ní ìrètí fún ìgbésí ayé ọjọ́ iwájú. Ó sọ nípa fífọ ilẹ̀ ayé mọ́ tónítóní àti sísọ ọ́ di ilé àgbàyanu fún àwọn tó bá sin Ọlọ́run. Kíyè sí àkọsílẹ̀ tí ń múni lọ́kàn yọ̀ yìí nípa ọjọ́ ọ̀la: “Wò ó! Àgọ́ Ọlọ́run wà pẹ̀lú aráyé, yóò sì máa bá wọn gbé, wọn yóò sì máa jẹ́ ènìyàn rẹ̀. Ọlọ́run fúnra rẹ̀ yóò sì wà pẹ̀lú wọn. Yóò sì nu omijé gbogbo nù kúrò ní ojú wọn, ikú kì yóò sì sí mọ́, bẹ́ẹ̀ ni kì yóò sí ọ̀fọ̀ tàbí igbe ẹkún tàbí ìrora mọ́. Àwọn ohun àtijọ́ ti kọjá lọ.”—Ìṣípayá 21:3, 4; Òwe 2:21, 22.
Tiẹ̀ rò ó wò ná: Kò sí àwọn ọmọ olókùnrùn mọ́, kò sí ebi mọ́, àwọn àrùn tí ń dáyà foni, tó ń gba okun ara lọ́wọ́ èèyàn ti dàwátì, kò ní sí ìrora gógó mọ́! Ẹkún táwọn èèyàn ń sun nígbà táyé bá sú wọn, tí wọ́n bá ní ìjákulẹ̀, àti ẹ̀dùn ọkàn yóò pòórá, nítorí àwọn ipò tó ń fa irú àwọn nǹkan bẹ́ẹ̀ yóò ti di èyí táa yí padà tàbí táa mú kúrò. Níwọ̀n bí agbo àwọn áńgẹ́lì tí í ṣe ọmọ ogun Ọlọ́run yóò ti pa àwọn ẹni burúkú tó kọ̀ láti yí padà run nígbà yẹn, àwọn olè, apànìyàn, òpùrọ́, àtàwọn tó ń fayé nini lára kò tún ní sí mọ́. Á ṣeé ṣe fáwọn èèyàn láti ní ilé tiwọn, tí wọ́n á sì gbádùn wọn láìséwu.—Aísáyà 25:8, 9; 33:24; 65:17-25.
Ǹjẹ́ ìyẹn dùn mọ́ ọ nínú? Ṣé wàá fẹ́ láti túbọ̀ mọ̀ nípa bí o ṣe lè fi àwọn ìlànà Bíbélì sílò kí o bàa lè ṣe ara rẹ láǹfààní nísinsìnyí àti lọ́jọ́ iwájú? Bó bá jẹ́ bẹ́ẹ̀, jọ̀wọ́ kàn sí àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà, inú wọn yóò sì dún láti fi ìwọ àti ìdílé rẹ sínú ètò “ẹ̀kọ́ tó wúlò títí ayé” tí wọ́n ń ṣe kárí ayé.