Ó Ṣeé Ṣe Kí Ìgbéyàwó Yín Má Forí Ṣánpọ́n O!
Ó Ṣeé Ṣe Kí Ìgbéyàwó Yín Má Forí Ṣánpọ́n O!
Àwọn ìmọ̀ràn tó gbéṣẹ́, tó lè ṣàǹfààní fún tọkọtaya kún inú Bíbélì rẹpẹtẹ. Èyí kì í ṣe ọ̀rọ̀ àgbọ́-ṣe-hàà, nítorí pé Ẹni tó mí sí Bíbélì náà ló tún dá ètò ìgbéyàwó sílẹ̀.
BÍ Ọ̀RÀN ìgbéyàwó ṣe rí gẹ́lẹ́ ni Bíbélì ṣe sọ ọ́. Ó sọ pé ọkọ àti aya yóò ní “ìpọ́njú” tàbí gẹ́gẹ́ bí ìtumọ̀ New English Bible ṣe sọ ọ́, wọn yóò ní “ìrora àti ẹ̀dùn ọkàn.” (1 Kọ́ríńtì 7:28) Síbẹ̀, Bíbélì tún sọ pé ìgbéyàwó lè mú ayọ̀ wá, àní ayọ̀ púpọ̀ jọjọ, ó sì gbọ́dọ̀ ṣe bẹ́ẹ̀. (Òwe 5:18, 19) Àwọn èrò méjèèjì wọ̀nyí kò tako ara wọn rárá. Ńṣe ni wọ́n wulẹ̀ fi hàn pé láìka àwọn ìṣòro tó le koko sí, àárín tọkọtaya kan ṣì lè dán mọ́rán, kí wọ́n sì nífẹ̀ẹ́ ara wọn dáadáa.
Ṣé bẹ́ẹ̀ ni ìgbéyàwó tìẹ rí? Ṣé kì í ṣe pé ìrora àti ìjákulẹ̀ ti dojú àjọṣe tímọ́tímọ́ àti ayọ̀ tó jẹ́ pé òun ló jọba nínú ìgbéyàwó yín nígbà kan rí délẹ̀ báyìí? Kódà, ká sọ pé ìgbéyàwó rẹ ti di èyí tí kò sí ìfẹ́ níbẹ̀ mọ́ fún ọ̀pọ̀ ọdún, o ṣì lè rí ohun tó sọnù nínú ìgbéyàwó rẹ tó fi dà bẹ́ẹ̀. Àmọ́ ṣá o, o kò gbọ́dọ̀ retí ohun tí kò ṣeé ṣe o. Kò sí bí ọkùnrin tàbí obìnrin tó jẹ́ aláìpé ṣe lè mọ̀ ọ́n ṣe tó kí àwọn kùdìẹ̀ kudiẹ bíi mélòó kan má máa jẹ yọ nínú ìgbéyàwó rẹ̀ lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan. Síbẹ̀síbẹ̀, àwọn ohun kan wà tóo lè ṣe láti yanjú àwọn kùdìẹ̀ kudiẹ wọ̀nyí.
Bóo ṣe ń ka àkójọ ọ̀rọ̀ tó wà nísàlẹ̀ yìí, gbìyànjú láti fojú sun àwọn kókó pàtó tó bá ipò tí ìgbéyàwó rẹ wà mu. Dípò kó jẹ́ pé kìkìdá àbùkù ọkọ tàbí aya rẹ ni wàá máa ṣàròyé nípa rẹ̀ ní gbogbo ìgbà, ṣe àṣàyàn àwọn kókó díẹ̀ tí ìwọ alára lè fi sílò, kí o sì fi àwọn ìmọ̀ràn tó wà nínú Ìwé Mímọ́ sílò. Ìwọ yóò wá rí i pé ìrètí ń bẹ fún ìgbéyàwó rẹ ju bí o ti rò lọ.
Ẹ jẹ́ ká kọ́kọ́ sọ̀rọ̀ nípa ìṣarasíhùwà, nítorí pé ojú tí o fi ń wo ẹ̀jẹ́ rẹ àti èrò tí o ní nípa ìyàwó tàbí ọkọ rẹ ṣe pàtàkì gidigidi.
Ojú Tí O Fi Ń Wo Ẹ̀jẹ́
Bí o bá fẹ́ ṣiṣẹ́ lórí ìgbéyàwó rẹ kó bàa lè dára, o gbọ́dọ̀ máa fojú wò ó bí ohun kan tó gbọ́dọ̀ wà pẹ́ títí. Ó ṣe tán, Ọlọ́run ṣètò ìgbéyàwó láti mú kí èèyàn méjì wà pa pọ̀ tí kò fi ní ṣeé ṣe fún ẹnikẹ́ni láti yà wọ́n. (Jẹ́nẹ́sísì 2:24; Mátíù 19:4, 5) Nítorí náà, àjọṣe ìwọ àti ọkọ tàbí aya rẹ kò dà bí iṣẹ́ kan tí o kàn lè sọ pé o ò ṣe mọ́ nígbà tó bá wù ọ́, bẹ́ẹ̀ ni kò dà bí ilé tí o ń yá gbé tí o kàn lè sọ fún onílé pé o ò gbé ilé rẹ̀ mọ́ tí wàá sì kó ẹrù rẹ jáde. Kàkà bẹ́ẹ̀, nígbà tí o ń ṣe ìgbéyàwó, o jẹ́jẹ̀ẹ́ láti wà pẹ̀lú ọkọ tàbí aya rẹ nígbà òjò àti nígbà ẹ̀ẹ̀rùn. Mímọ̀ pé o jẹ́jẹ̀ẹ́ lọ́nà yìí bá ohun tí Jésù Kristi sọ ní èyí tó fẹ́rẹ̀ẹ́ tó ẹgbàá [2,000] ọdún sẹ́yìn mu, ó ní: “Ohun tí Ọlọ́run ti so pọ̀, kí ènìyàn kankan má ṣe yà á sọ́tọ̀.”—Mátíù 19:6.
Àwọn kan lè sọ pé, ‘Ẹn, ṣe bí a ṣì ń gbé pa pọ̀. Ṣé èyí ò fi hàn pé a dúró ti ẹ̀jẹ́ wa ni?’ Ó ṣeé ṣe kó rí bẹ́ẹ̀. Ṣùgbọ́n, gẹ́gẹ́ báa ṣe sọ nínú àpilẹ̀kọ kìíní nínú ọ̀wọ́ àpilẹ̀kọ yìí, àwọn tọkọtaya kan tí wọ́n ṣì ń gbé pa pọ̀ ló jẹ́ pé wàhálà ò tán rí nínú ìgbéyàwó wọn, wọ́n ti kó sínú ìgbéyàwó tí kò ti sí ìfẹ́. Góńgó rẹ gbọ́dọ̀ jẹ́ láti mú kí ìgbéyàwó rẹ jẹ́ èyí tó ń gbádùn mọ́ni, kó má kàn jẹ́ èyí tí èèyàn wulẹ̀ ń mú mọ́ra. Ẹ̀jẹ́ kì í ṣe àdéhùn láti jẹ́ olóòótọ́ sí ètò ìgbéyàwó nìkan ni, ṣùgbọ́n láti tún jẹ́ olóòótọ́ sí ẹni tí o ti jẹ́jẹ̀ẹ́ láti nífẹ̀ẹ́ àti láti ṣìkẹ́.—Éfésù 5:33.
Àwọn nǹkan tóo bá sọ fún ọkọ tàbí ìyàwó rẹ lè fi bí ẹ̀jẹ́ tí o jẹ́ láti wà pẹ̀lú rẹ̀ ṣe jinlẹ̀ tó hàn. Fún àpẹẹrẹ, nígbà tí èdèkòyédè bá ṣẹlẹ̀, àwọn ọkọ àti aya kan máa ń fi ìwàǹwára sọ̀rọ̀ bíi kí wọ́n sọ pé, “Màá fi ilé sílẹ̀ fún ẹ!” tàbí kí wọ́n ní, “Mo máa lọ fẹ́ ẹlòmíràn tó máa mọyì mi!” Ká tiẹ̀ sọ pé kò dé inú ẹni tó sọ irú ọ̀rọ̀ bẹ́ẹ̀ pàápàá, irú ọ̀rọ̀ bẹ́ẹ̀ fi hàn pé wọ́n lè fi ara wọ́n sílẹ̀ ní ìgbàkigbà, àti pé ẹni tó sọ bẹ́ẹ̀ ti múra tán láti lọ ní ìgbàkigbà.
Bóo bá fẹ́ kí ìfẹ́ tún padà jọba nínú ìgbéyàwó rẹ, má ṣe máa sọ irú àwọn ọ̀rọ̀ bẹ́ẹ̀. Àbí, nígbà tóo mọ̀ pé o lè kó
kúrò nínú ilé kan ní ìgbàkigbà, ṣé wàá wá fi oríṣiríṣi ohun ọ̀ṣọ́ to irú ilé bẹ́ẹ̀? Nígbà náà, kí ló dé tóo fi ń retí pé kí ọkọ tàbí aya rẹ ṣe àwọn àtúnṣe kan nínú ìgbéyàwó tó lè máà tọ́jọ́? Múra tán láti sa gbogbo ipá rẹ láti wá ojútùú sí àwọn ìṣòro ìgbéyàwó yín.Ohun tí ìyàwó kan ṣe nìyẹn nígbà tí àárín òun àti ọkọ rẹ̀ ò gún. Ó ní: “Bó tiẹ̀ jẹ́ pé mo máa ń kórìíra rẹ̀ nígbà mìíràn, mi ò fìgbà kan ronú pé kí n kọ̀ ọ́ sílẹ̀. Gbogbo ohun tó bá jẹ́ àléébù la máa ń ṣàtúnṣe rẹ̀ bákan ṣáá. Àmọ́ ní báyìí, lẹ́yìn ọdún méjì tó le koko bí ojú ẹja, mo lè sọ pé tìdùnnú-tìdùnnú làwa méjèèjì fi ń gbé pa pọ̀.”
Bó ṣe rí gẹ́lẹ́ nìyẹn, iṣẹ́ àjọṣe ni ọ̀rọ̀ ẹ̀jẹ́ jẹ́, kì í ṣe pé ká kàn máa gbé pa pọ̀ lásán bí kò ṣe láti gbárùkù ti góńgó kan náà. Ó dára, o lè ronú pé níbi tọ́ràn dé dúró yìí, mímọ̀ tí o mọ̀ pé ẹ gbọ́dọ̀ wà pa pọ̀ ni kò tíì jẹ́ kí ìgbéyàwó yín tú ká. Bó bá jẹ́ bẹ́ẹ̀ lọ̀ràn rí, má sọ̀rètí nù. Ìfẹ́ tún lè padà wá lẹ́ẹ̀kan sí i. Lọ́nà wo?
Bíbọlá fún Ọkọ Tàbí Aya Rẹ
Bíbélì sọ pé: “Kí ìgbéyàwó ní ọlá láàárín gbogbo ènìyàn.” (Hébérù 13:4; Róòmù 12:10) Ọ̀rọ̀ Gíríìkì tí a túmọ̀ níhìn-ín sí “ọlá” ni a túmọ̀ ní àwọn ibòmíràn nínú Bíbélì sí “ọ̀wọ́n,” “àgbégẹ̀gẹ̀,” “níye lórí.” Bí a bá mọyì ohun kan dáadáa, ohun tó bá gbà lá máa fún un láti máa bójú tó o. Ó ṣeé ṣe kí o ti kíyè sí i pé bí ọkùnrin kan tó ṣẹ̀ṣẹ̀ ra ọkọ̀ ayọ́kẹ́lẹ́ tuntun olówó gọbọi kan ṣe ń bójú tó ọkọ̀ ayọ́kẹ́lẹ́ rẹ̀ nìyẹn. Ńṣe ló máa tọ́jú rẹ̀ tí ìyẹn á fi máa dán gbinrin, kí nǹkan sì tó bàjẹ́ nínú rẹ̀ ló ti máa pààrọ̀ rẹ̀. Kódà bí nǹkan kékeré kan bá ṣèèṣì gbá ọkọ̀ náà, ńṣe ló máa dà bí ẹni pé gbogbo ọkọ̀ náà ló ti bà jẹ́ ráúráú! Bí àwọn èèyàn mìíràn ṣe máa ń tọ́jú ìlera wọn nìyẹn. Kí ló dé? Nítorí pe wọ́n mọ̀ pé ìlera loògùn ọrọ̀, ìdí èyí ni wọ́n fi fẹ́ dáàbò bò ó.
Dáàbò bo ìgbéyàwó rẹ lọ́nà kan náà. Bíbélì sọ pé ìfẹ́ “a máa retí ohun gbogbo.” (1 Kọ́ríńtì 13:7) Dípò ti wàá fi máa ronú pé ọ̀ràn ọ̀hún kò lè yanjú—bóyá kóo tiẹ̀ gbékútà pé kò sí ọgbọ́n tí ẹ lè dá tí wàhálà á fi dín kù nínú ìgbéyàwó yín nípa sísọ pé, “A ò fìgbà kan nífẹ̀ẹ́ ara wa dénú,” “A ti kéré jù nígbà táa ṣègbéyàwó,” tàbí “A ò mọ nǹkan tí a ń ṣe nígbà yẹn”—kí ló dé tóò máa retí pé nǹkan á sunwọ̀n, kí o sì sapá láti ṣe àtúnṣe tó bá yẹ́ nínú ìgbéyàwó náà, kí o wá mú sùúrù fún àwọn àbájáde rẹ̀? Obìnrin kan tó jẹ́ olùgbaninímọ̀ràn lórí ọ̀ràn ìgbéyàwó sọ pé: “Mo máa ń gbọ́ tí ọ̀pọ̀ lára àwọn tó wá ń gbàmọ̀ràn lọ́dọ̀ mi máa ń ṣàròyé pe, ‘eléyìí ti wá kọjá agbára mi o!’ Dípò tí wọn ì bá fi ṣàyẹ̀wò ìgbéyàwó wọn dáadáa kí wọ́n rí ibi tó ti yẹ kí wọ́n ti ṣe àtúnṣe, ńṣe ni wọ́n kàn fi ìwàǹwára kọ gbogbo ìṣètò ìgbéyàwó sílẹ̀ tí wọ́n sọ pé ó ti nira jù láti bójú tó, títí kan àwọn nǹkan pàtàkì tí wọ́n jọ máa ń nípìn-ín nínú rẹ̀, àwọn ohun tí wọ́n ti jọ gbé ṣe, àti àwọn ohun mìíràn tí wọn ì bá ṣe lọ́jọ́ iwájú.”
Irú àwọn ìrírí ohun tó ti ṣẹlẹ̀ sẹ́yìn wo lo máa ń sọ fún ọkọ tàbí aya rẹ? Láìka àwọn ìṣòro tó wà nínú ìgbéyàwó rẹ sí, ó dájú pé o ṣì lè ronú nípa àwọn àkókò tó lárinrin tí ẹ jọ gbádùn, àwọn àṣeyọrí tí ẹ ti ṣe, àti àwọn ìpèníjà tí ẹ̀yin méjèèjì ti jọ kójú. Ronú lórí àwọn àkókò wọ̀nyí, kí o sì jẹ́ kí ọkọ tàbí aya rẹ mọ̀ pé o mọrírì ìgbéyàwó yín àti òun pẹ̀lú nípa fífi tọkàntọkàn sakun láti mú kí àárín yín dán mọ́rán sí i. Bíbélì fi hàn pé Jèhófà Ọlọ́run ní ìfẹ́ ọkàn tó jinlẹ̀ nínú bí àwọn tọkọtaya ṣe ń bá ara wọn lò. Fún àpẹẹrẹ, nígbà ayé wòlíì Málákì, Jèhófà bá àwọn ọkọọ̀yàwó ní ilẹ̀ Ísírẹ́lì tí wọ́n hùwà àdàkàdekè sí àwọn ìyàwó wọn wí nítorí kíkọ̀ tí wọ́n kọ̀ wọ́n sílẹ̀ lórí àwọn ẹ̀sùn tí kò lẹ́sẹ̀ nílẹ̀. (Málákì 2:13-16) Àwọn Kristẹni ń fẹ́ kí ìgbéyàwó wọn bọlá fún Jèhófà Ọlọ́run.
Èdè Àìyedè—Báwo Ló Ṣe Lágbára Tó?
Lájorí ohun tó ń fa ìṣòro pé kí ìfẹ́ di àwátì nínú ìgbéyàwó kan kò ṣẹ̀yìn pé kí tọkọtaya má lè fi ìtùnbí ìnùbí yanjú èdè àìyedè. Níwọ̀n bó ti jẹ́ pé kò sí èèyàn méjì tí wọ́n lè rí bákan náà, gbogbo ìgbéyàwó ló máa ní èdè àìyedè lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan. Àmọ́ àwọn tọkọtaya tó bá jẹ́ pé òní ẹjọ́ ọ̀la àròyé ni tiwọn yóò rí i pé láàárín ọdún díẹ̀ sí i, ìfẹ́ wọn yóò jó rẹ̀yìn. Wọ́n tiẹ̀ lè wá parí èrò sí pé, ‘A ò tiẹ̀ bára mu rárá. Ìjà ni ràì lójoojúmọ́!’
Àmọ́ ṣá o, pé èdè àìyedè wà láàárín yín kò yẹ kó jẹ́ òpin ìgbéyàwó yín. Ohun tó yẹ ká béèrè ni pé, Báwo la ṣe ń yanjú èdè àìyedè? Nínú ìgbéyàwó tó kẹ́sẹ járí, ọkọ àti aya ti kọ́ láti sọ̀rọ̀ nípa àwọn ìṣòro wọn láìjẹ́ pé wọ́n di ohun tí dókítà kan pè ní “ọ̀tá kòríkòsùn.”
“Agbára Ahọ́n”
Ǹjẹ́ ìwọ àti ọkọ tàbí aya rẹ mọ bó ṣe yẹ kí ẹ jíròrò àwọn ìṣòro yín? Ẹyin méjèèjì gbọ́dọ̀ múra tán láti sọ ohun tó wà lọ́kàn yín jáde. Ká sòótọ́, ohun kan téèyàn ń kọ́ ni—ó sì lè ṣòro díẹ̀ láti kọ́ ọ. Kí ló dé? Fún ìdí kan, gbogbo wa la máa ń “kọsẹ̀ nínú ọ̀rọ̀” lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan nítorí pé a jẹ́ aláìpé. (Jákọ́bù 3:2) Ní àfikún sí i, àwọn kan wá láti ilé tó jẹ́ pé gbogbo ìgbà ni àwọn òbí wọn máa ń sọ̀kò ìbínú. Lọ́nà kan, láti pínníṣín ni wọ́n ti tọ́ wọn láti gbà pé kò sí ohun tó burú nínú ìbújáde ìbínú àti àwọn ọ̀rọ̀ èébú. Ọmọkùnrin tí wọ́n bá tọ́ dàgbà ní irú àgbègbè bí èyí lè wá di “ènìyàn tí ó fi ara fún ìbínú,” ẹnì kan tó “fi ara fún ìhónú” nígbà tó bá dàgbà. (Òwe 29:22) Bákan náà, ọmọbìnrin kan tí wọ́n bá tọ́ dàgbà lọ́nà kan náà lè di “obìnrin ẹlẹ́rẹ̀kẹ́ èébú àti oníbìínú.” (Òwe 21:19, The Bible in Basic English) Ó lè ṣòro láti fi àwọn ọ̀nà tí èèyàn gbà ń ronú àti ọ̀nà tí èèyàn gbà ń bá àwọn èèyàn lò tó ti di bára kú sílẹ̀. a
Nígbà náà, yíyanjú èdè àìyedè kan kíkọ́ àwọn ọ̀nà tuntun láti sọ àwọn èrò tó wà lọ́kàn ẹni jáde. Èyí kì í ṣe ohun kan tó yẹ ká fojú kéré nítorí òwe Bíbélì kan sọ pé: “Ikú àti ìyè ń bẹ ní agbára ahọ́n.” (Òwe 18:21) Bẹ́ẹ̀ ni, ó lè dà bí ohun kan tí kò jọjú, àmọ́ bí o bá ṣe sọ̀rọ̀ sí ọkọ tàbí aya rẹ ní agbára láti dabarú ìgbéyàwó yín tàbí kó mú un sọ jí? Òwe mìíràn nínú Bíbélì sọ pé: “Ẹnì kan wà tí ń sọ̀rọ̀ láìronú bí ẹni pé pẹ̀lú àwọn ìgúnni idà, ṣùgbọ́n ahọ́n ọlọ́gbọ́n jẹ́ ìmúniláradá.”—Òwe 12:18.
Ká tiẹ̀ ní ọkọ tàbí aya rẹ ló ń dá rúgúdù sílẹ̀, ronú nípa àwọn nǹkan tí o ń sọ nígbà tí èdè àìyedè bá ṣẹlẹ̀. Ṣé ńṣe ni ọ̀rọ̀ rẹ máa ń kó ẹ̀dùn ọkàn báni, tàbí ó máa ń gbéni ró? Ṣé ó máa ń fa ìbínú tàbí ó máa ń pẹ̀tù sí i? Bíbélì wí pé: “Ọ̀rọ̀ tí ń fa ìrora máa ń ru ìbínú sókè.” Àmọ́ ní òdì kejì, “ìdáhùn kan, nígbà tí ó bá jẹ́ lọ́nà pẹ̀lẹ́, máa ń yí ìhónú padà.” (Òwe 15:1) Ńṣe ni àwọn ọ̀rọ̀ tó ń mú kí ara kan èèyàn máa ń mú kí ìbínú túbọ̀ ru sí i, kódà kéèyàn tiẹ̀ fi ohùn pẹ̀lẹ́ sọ ọ́ pàápàá.
Òtítọ́ ni pé bí ohun kan bá ń kọ ẹ́ lóminú, o ní ẹ̀tọ́ láti sọ ọ́ jáde. (Jẹ́nẹ́sísì 21:9-12) Àmọ́, o lè sọ àwọn ohun tó ń kọ ẹ́ lóminú láìjẹ́ pé o sọ ọ̀rọ̀ ẹ̀gàn, àwọn ọ̀rọ̀ èébú, àti àwọn ọ̀rọ̀ tí ń buni kù. Díwọ̀n àwọn ohun tí o kò ní fẹ́ láti sọ sí ọkọ tàbí aya rẹ, irú bíi “Mo kórìíra rẹ” tàbí, “Ì bá wù mí ká ní a ò fẹ́ra wa.” Bákan náà, bó tiẹ̀ jẹ́ pé kì í ṣe ọ̀rọ̀ ìgbéyàwó ni àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù tó jẹ́ Kristẹni ń sọ ní pàtó, ó bọ́gbọ́n mu pé ká yẹra fún ohun tó pè ní “fífa ọ̀rọ̀” àti “awuyewuye lílenípá lórí àwọn ohun tí kò tó nǹkan.” b (1 Tímótì 6:4, 5) Bí ọkọ tàbí aya rẹ bá ń ṣe báyìí, má ṣe hùwà padà lọ́nà kan náà ní tìrẹ o. Níwọ̀n bí ó bá ti wà ní ìkáwọ́ rẹ, máa wá àlàáfíà.—Róòmù 12:17, 18; Fílípì 2:14.
Òótọ́ ni pé, nígbà tí ìbínú bá dé, ó máa ń ṣòro láti ṣàkóso àwọn ọ̀rọ̀ téèyàn ń sọ. Òǹkọ̀wé Bíbélì náà Jákọ́bù 3:6, 8) Kí wá ni o lè ṣe bóo bá rí i pé inú bẹ̀rẹ̀ sí bí ọ? Báwo lo ṣe lè bá ọkọ̀ tàbí aya rẹ sọ̀rọ̀ lọ́nà tí yóò mú kí awuyewuye náà rọlẹ̀ dípò sísúnná sí i?
Jákọ́bù sọ pé: “Ahọ́n jẹ́ iná. . . . kò sí ẹnì kan nínú aráyé tí ó lè rọ̀ ọ́ lójú. Ohun ewèlè tí ń ṣeni léṣe, ó kún fún panipani májèlé.” (Pípẹ̀tù sí Àwọn Ìjiyàn Tó Lè Di Wàhálà
Àwọn kan ti rí i pé ó túbọ̀ rọrùn láti mú kí ìbínú rọlẹ̀ kí wọ́n sì wá ráyè sọ̀rọ̀ lórí ohun tó ń dá wàhálà sílẹ̀ bó bá jẹ́ pé ipa tí ọ̀ràn náà ní lórí wọn ni wọ́n tẹnu mọ́ dípò tí wọn ì bá fi máa tẹnu mọ́ ìwà tí ọkọ tàbí aya wọn hù. Fún àpẹẹrẹ, ó dára bí èèyàn bá sọ pé, “Ohun tóo sọ yẹn dùn mí o” ju pé kí èèyàn ní, “O múnú bí mi o” tàbí, “Ó yẹ kí làákàyè ẹ sọ fún ẹ pé kò yẹ kóo sọ̀rọ̀ báyẹn.” Àmọ́ ṣá o, bóo bá ń sọ bí ọ̀rọ̀ náà ṣe rí lára rẹ, má ṣe jẹ́ kí ohùn rẹ fi ìbínú kíkorò hàn tàbí pé kó fi hàn pé ṣe ni ó ń tẹ́ńbẹ́lú ẹnì kejì rẹ. Góńgó rẹ gbọ́dọ̀ jẹ́ láti sọ ohun tó jẹ́ ìṣòro náà kì í ṣe láti gbéjà ko onítọ̀hún.—Jẹ́nẹ́sísì 27:46–28:1.
Ní àfikún, máa rántí ní gbogbo ìgbà pé “ìgbà dídákẹ́ jẹ́ẹ́ àti ìgbà sísọ̀rọ̀” wà. (Oníwàásù 3:7) Bí èèyàn méjì bá ń sọ̀rọ̀ pa pọ̀ lẹ́ẹ̀kan náà, kò sí ẹni tó ń tẹ́tí sí ohun tí ẹnì kejì ń sọ nínú àwọn méjèèjì, èyí kò sì ní yanjú ohunkóhun. Nítorí náà, bó bá tó àsìkò tó yẹ kóo tẹ́tí bẹ̀lẹ̀jẹ́, jẹ́ ẹni tí ó “yára nípa ọ̀rọ̀ gbígbọ́, lọ́ra nípa ọ̀rọ̀ sísọ.” Bákan náà ló tún ṣe pàtàkì pé kí o “lọ́ra nípa ìrunú.” (Jákọ́bù 1:19) Kì í ṣe gbogbo ọ̀rọ̀ tí ọkọ tàbí aya rẹ bá fi ìbínú sọ ni wàá kà sí; má ṣe “kánjú nínú ẹ̀mí rẹ láti fara ya.” (Oníwàásù 7:9) Kàkà bẹ́ẹ̀, gbìyànjú láti mọ ohun tó mú kí ọkọ tàbí aya rẹ sọ irú àwọn ọ̀rọ̀ bẹ́ẹ̀. Bíbélì sọ pé: “Ìjìnlẹ̀ òye tí ènìyàn ní máa ń dẹwọ́ ìbínú rẹ̀ dájúdájú, ẹwà ni ó sì jẹ́ níhà ọ̀dọ̀ rẹ̀ láti gbójú fo ìrélànàkọjá.” (Òwe 19:11) Òye tó jinlẹ̀ lè mú kí ọkọ kan tàbí aya mọ ohun tó jẹ́ kúlẹ̀kúlẹ̀ èdè àìyedè tí wọ́n ní.
Fún àpẹẹrẹ, bí ìyàwó kan bá ń ṣàròyé pé ọkọ òun kì í lo àkókò tó pọ̀ pẹ̀lú òun, ó lè máà jẹ́ pé wákàtí tàbí ìṣẹ́jú ni ó ní lọ́kàn. O lè jẹ́ pé ohun tó ń dùn ún tí ọkọ rẹ̀ kò kà sí tàbí tí kò wá bí yóò ṣe mọ̀ nípa rẹ̀ ni obìnrin yìí ń sọ. Bákan náà ló ṣe rí pẹ̀lú ọkọ kan tó bínú nítorí bí ìyàwó rẹ̀ ṣe ṣàdédé ra nǹkan wálé, ó lè máà jẹ́ pé owó tó ná ló bí ọkọ náà nínú. Ó lè jẹ́ nítorí pé aya rẹ̀ kò bá a sọ ọ́ kó tó ra nǹkan náà ló ń bí ọkọ nínú. Ọkọ kan tàbí aya kan tó bá ní òye tó jinlẹ̀ yóò rí i dájú pé òun wádìí ọ̀rọ̀ náà dáadáa láti mọ ohun tó fa ìṣòro náà.—Òwe 16:23.
Àmọ́ ṣé ẹnu dùn-ún ròfọ́ ni gbogbo ohun tí a ń sọ wọ̀nyí? Ó jọ bẹ́ẹ̀! Nítorí pé ní àwọn àkókò mìíràn, láìka gbogbo akitiyan táa ti ṣe sí, a ṣì máa ń sọ àwọn ọ̀rọ̀ kòbákùngbé tí ìbínú á sì wá dé. Nígbà tóo bá rí i pé ọ̀rọ̀ ti dà bẹ́ẹ̀, ó lè di dandan pé kóo tẹ̀ lé ìmọ̀ràn tó wà nínú Òwe 17:14, tó ní: “Kí aáwọ̀ tó bẹ́, fi ibẹ̀ sílẹ̀.” Kò sóhun tó burú bí ẹ bá pa ìjíròrò ọ̀hún tì títí dìgbà tí inú tó ń bí yín á fi rọlẹ̀. Bó bá wá jẹ́ pé kò sí bí ẹ ṣe máa sọ̀rọ̀ tí ariwo kò ní ṣẹlẹ̀, ì bá bọ́gbọ́n mu pé kí ẹ ké sí ọ̀rẹ́ yín kan tó ní ìwà àgbà láti jókòó pẹ̀lú ẹ̀yin méjèèjì kí ó sì ràn yín lọ́wọ́ láti yanjú aáwọ̀ tó wà láàárín yín. c
Ní-in Lọ́kàn Pé Nǹkan Á Dára
Má ṣe rẹ̀wẹ̀sì bí ìgbéyàwó yín kò bá rí bí o ṣe rò pé ó máa rí nígbà tí ẹ ń fẹ́ra yín sọ́nà. Ikọ̀ àwọn ògbóǹkangí kan nípa ìgbéyàwó sọ pé: “Ìgbéyàwó kì í ṣe ohun kan tó ń dùn yùngbà-yungba fún ọ̀pọ̀ èèyàn. Ó máa ń dùn lákòókò kan tí yóò sì wá korò láwọn àkókò mìíràn.”
Bẹ́ẹ̀ ni, ìgbéyàwó lè má dà bí ìtàn aládùn kan nípa ìfẹ́, bẹ́ẹ̀ sì ni kò yẹ kó jẹ́ ìtàn kan tó ń báni nínú jẹ́. Àwọn àkókò kan yóò wà tó jẹ́ pé ńṣe ni ìwọ àti ọkọ tàbí aya rẹ yóò máa fara dà á fún ara yín, bákan náà sì ni àwọn àkókò kan yóò wà tí ẹ óò pa gbogbo èdè àìyedè tó wà láàárín yín tì sẹ́gbẹ̀ẹ́ kan tí ẹ ó sì gbádùn wíwà pa pọ̀, tí ẹ ó jọ ṣeré, tí ẹ óò sì bá ara yín sọ̀rọ̀ bí ẹni bá ọ̀rẹ́ sọ̀rọ̀. (Éfésù 4:2; Kólósè 3:13) Àwọn àkókò bí irú èyí ni ẹ lè bu epo sí iná ìfẹ́ yín tó ti jó relẹ̀.
Rántí pé, ẹ̀dá ènìyàn aláìpé méjì kò lè ní ìgbéyàwó tó pé. Àmọ́ wọ́n lè ní ayọ̀ tó pọ̀ dáadáa. Àní sẹ́, pẹ̀lú àwọn ìṣòro tí ẹ ń dójú kọ, àjọṣe tó wà láàárín ìwọ àti ọkọ tàbí aya rẹ lè jẹ́ orísun ayọ̀ ńláǹlà. Ohun kan tó dájú ni pé: Bí ìwọ àti ọkọ tàbí aya rẹ bá sakun tí ẹ sì gbìyànjú láti má ṣe jẹ́ ẹni tó ń rinkinkin jù, tí ẹ sì ń wá ire ara yín lẹ́nì kìíní kejì, ó dájú pé ó ṣeé ṣe kí ìgbéyàwó yín má forí ṣánpọ́n.—1 Kọ́ríńtì 10:24.
[Àwọ̀n Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Ipa tí àwọn òbí ní lórí ẹni kò sọ pé kéèyàn máa sọ̀rọ̀ kòbákùngbé sí ọkọ tàbí aya rẹ̀. Àmọ́ ṣá, ó lè jẹ́ kéèyàn lóye bí àwọn ìwà kan ṣe lè di èyí tó wọ èèyàn lẹ́wù gan-an tó fi jẹ́ pé ó máa ṣòro láti fi wọ́n sílẹ̀.
b Ọ̀rọ̀ Gíríìkì náà tí a túmọ̀ sí “èdè àìyedè oníwà ipá nípa àwọn ohun tí kò tó nǹkan” ni a tún lè túmọ̀ sí “ìrunú lọ́dọ̀ tọ̀túntòsì.”
c Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ní àwọn alàgbà ìjọ tí wọ́n lè lọ bá. Bó tiẹ̀ jẹ́ pé kì í ṣe iṣẹ́ wọn ní láti máa tojú bọ ọ̀rọ̀ àwọn lọ́kọláya tí kì í ṣe ọ̀rọ̀ tó kàn wọ́n, àwọn alàgbà lè ṣe ìrànwọ́ lọ́nà tí ń tuni lára fún àwọn tọkọtaya tí wọ́n ní ìṣòro.—Jákọ́bù 5:14, 15.
[Ìsọfúnni tá a pàfiyèsí sí ní ojú ìwé 12]
Ṣé ńṣe làwọn ọ̀rọ̀ rẹ máa ń múnú bíni, tàbí wọ́n máa ń pẹ̀tù síni lọ́kàn?
[Àpótí/Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 10]
MÁ ṢE SỌ̀KÒ Ọ̀RỌ̀ LÙ Ú
Bíbélì sọ pé: “Ẹ jẹ́ kí àsọjáde yín máa fìgbà gbogbo jẹ́ pẹ̀lú oore ọ̀fẹ́, tí a fi iyọ̀ dùn, kí ẹ lè mọ bí ó ti yẹ kí ẹ fi ìdáhùn fún ẹnì kọ̀ọ̀kan.” (Kólósè 4:6) Ọ̀rọ̀ yìí mà wúlò gan-an nínú ìgbéyàwó o! Láti ṣàpèjúwe rẹ̀: Nínú eré bọ́ọ̀lù jíjù, ńṣe ni wàá rọra ju bọ́ọ̀lù kí ó bàa lè rọrùn fún ẹnì kejì rẹ láti mú un. O kò ní fi ipá jù ú tó bẹ́ẹ̀ ti yóò fi pa ẹnì kejì rẹ lára. Fi ìlànà kan náà sílò nígbà tí o bá ń bá ẹnì kejì rẹ nínú ìgbéyàwó sọ̀rọ̀. Sísọ̀kò ọ̀rọ̀ lù ú yóò wulẹ̀ pa á lára ni. Kàkà bẹ́ẹ̀, bá ẹnì kejì rẹ sọ̀rọ̀ lọ́nà pẹ̀lẹ́—pẹ̀lú oore ọ̀fẹ́—kí ó bàa lè lóye ọ̀rọ̀ rẹ.
[Àpótí/Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 11]
RÁNTÍ ÌGBÀ KAN!
Ka àwọn lẹ́tà àti káàdì ìkíni tí ẹ kọ síra yín nígbà kan rí. Wo àwọn fọ́tò. Bi ara rẹ léèrè pé, ‘Kí ló mú kí n nífẹ̀ẹ́ ọkọ tàbí aya mi yìí nígbà yẹn? Àwọn ànímọ́ wo ni mo fẹ́ràn jù lára rẹ̀? Àwọn ìgbòkègbodò wo la ń ṣe pọ̀ nígbà yẹn? Àwọn ohun wo ló máa ń pa wá lẹ́rìn-ín?’ Lẹ́yìn náà, bá ọkọ tàbí aya rẹ sọ̀rọ̀ nípa àwọn ohun mánigbàgbé yẹn. Ìjíròrò tí o bẹ̀rẹ̀ pẹ̀lú gbólóhùn ọ̀rọ̀ náà “Ṣé o rántí ìgbà tí . . . ?” lè ran ìwọ àti ẹnì kejì rẹ lọ́wọ́ láti tún nífẹ̀ẹ́ ara yín bíi ti tẹ́lẹ̀.
[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 12]
BÓO FẸ́ ẸLÒMÍÌ, ÌṢÒRO KAN NÁÀ NI WÀÁ MÁA NÍ
Àwọn tọkọtaya tí wọ́n há sínú ìgbéyàwó aláìnífẹ̀ẹ́ máa ń rò pé káwọn lọ fẹ́ ẹlòmíì, kí àwọ́n sì wá bẹ̀rẹ̀ ìgbésí ayé pẹ̀lú ọkọ tàbí aya mìíràn ni ojútùú rẹ̀. Ṣùgbọ́n Bíbélì dẹ́bi fún ìwà panṣágà, ó sọ pé ẹni tó bá dá ẹ̀ṣẹ̀ náà “jẹ́ ẹni tí ọkàn-àyà kù fún [“ó jẹ́ òpònú aláìnírònú,” New English Bible],” ó sì “ń run ọkàn ara rẹ̀.” (Òwe 6:32) Nígbẹ̀yìngbẹ́yín, ẹni tó ṣe panṣágà, tí kò sì ronú pìwà dà náà yóò pàdánù ojú rere Ọlọ́run—ìyẹn sì ni ìparun tó burú jù lọ tó lè ṣẹlẹ̀ sí èèyàn.—Hébérù 13:4.
Bí híhùwà panṣágà ṣe jẹ́ ìwà òpònú, tó sì burú jáì tún ń fara hàn ní àwọn ọ̀nà mìíràn. Ohun kan ni pé ẹni tó ṣe panṣágà náà, tó sì lọ fẹ́ ẹlòmíràn, lè máa ní irú ìṣòro kan náà tó fọ́ ìgbéyàwó rẹ̀ àkọ́kọ́. Ọ̀mọ̀wé Diane Medved tún tọ́ka sí kókó mìíràn tó yẹ ká gbé yẹ̀ wò, ó sọ pé: “Ohun àkọ́kọ́ tí ẹni tí o ṣẹ̀ṣẹ̀ fẹ́ mọ̀ nípa rẹ ni pé o ṣe tán láti jẹ́ aláìṣòótọ́. Ó mọ̀ pé o lè tan ẹni tí o ṣèlérí pé wàá bọlá fún jẹ. Pé o mọ béèyàn ṣe ń wí àwíjàre. Pé o lè gbàgbé ẹ̀jẹ́ tóo jẹ́. Pé títẹ́ ìfẹ́ rẹ fún fàájì lọ́rùn tàbí títẹ́ ara rẹ lọ́rùn ni wọ́n lè fi dẹ pàkúté mú ọ. . . . Báwo wá ni ẹni tóo ṣẹ̀ṣẹ̀ fẹ́ ṣe fẹ́ mọ̀ pé wọn ò tún ní fi ẹ̀tàn dẹ pàkúté mú ọ?”
[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 14]
KỌ́GBỌ́N NÍNÚ ÒWE BÍBÉLÌ
• Òwe 10:19: “Nínú ọ̀pọ̀ yanturu ọ̀rọ̀ kì í ṣàìsí ìrélànàkọjá, ṣùgbọ́n ẹni tí ń ṣàkóso ètè rẹ̀ ń hùwà tòyetòye.”
Tí inú bá ń bí wa, a lè ṣi ọ̀rọ̀ sọ, ká sì wá kábàámọ̀ níkẹyìn.
• Òwe 15:18: “Ènìyàn tí ó kún fún ìhónú ń ru asọ̀ sókè, ṣùgbọ́n ẹni tí ó lọ́ra láti bínú ń mú aáwọ̀ rọlẹ̀.”
Fífi ẹ̀sùn kan ẹnì kejì rẹ nípa fífi ọ̀rọ̀ gún un lára yóò mú kí òun náà fèsì pẹ̀lú ọ̀rọ̀ burúkú, bẹ́ẹ̀ tẹ́yin méjèèjì bá fara balẹ̀ gbọ́ ara yín lágbọ̀ọ́yé, ẹ óò lè jọ wá ọ̀nà láti yanjú ìṣòro náà.
• Òwe 17:27: “Ẹnikẹ́ni tí ó bá fawọ́ àwọn àsọjáde rẹ̀ sẹ́yìn kún fún ìmọ̀, ènìyàn tí ó ní ìfòyemọ̀ sì tutù ní ẹ̀mí.”
Tí o bá ti rí i pé ìbínú ti ń bọ̀, ó sàn kóo yáa má sọ̀rọ̀, kí ọ̀rọ̀ má bàa di ran-n-to.
• Òwe 29:11: “Gbogbo ẹ̀mí rẹ̀ ni arìndìn ń tú jáde, ṣùgbọ́n ẹni tí ó gbọ́n a máa mú kí ó pa rọ́rọ́ títí dé ìkẹyìn.”
Ìkóra-ẹni-níjàánu ṣe pàtàkì. Fífìbínú sọ̀kò ọ̀rọ̀ sí ẹnì kejì rẹ yóò wulẹ̀ mú kó máa sára fún ọ ni.