Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ọgọ́rùn-ún Ọdún Sẹ́yìn Ni Wọ́n Ra Ilé Iṣẹ́ Àkọ́kọ́

Ọgọ́rùn-ún Ọdún Sẹ́yìn Ni Wọ́n Ra Ilé Iṣẹ́ Àkọ́kọ́

Ọgọ́rùn-ún Ọdún Sẹ́yìn Ni Wọ́n Ra Ilé Iṣẹ́ Àkọ́kọ́

Wọ́n fìdí ẹgbẹ́ Watch Tower Bible and Tract Society múlẹ̀ lábẹ́ òfin ní Pennsylvania, ní Orílẹ̀-Èdè Amẹ́ríkà, ní December 15, 1884. a Ibẹ̀ náà ni olú iléeṣẹ́ ẹgbẹ́ yìí fìdí kalẹ̀ sí. Lẹ́yìn náà, ní April 23, 1900, wọ́n ra ilé àkọ́kọ́ tí wọ́n fi ṣe ẹ̀ka iléeṣẹ́ sí London, ní ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì. Ó wà ní ojúlé 131 Gipsy Lane, Forest Gate, ní Ìlà Oòrùn London, gẹ́gẹ́ bí a ti fi hàn níhìn-ín.

NÍGBÀ tí wọ́n fìdí ẹ̀ka iléeṣẹ́ àkọ́kọ́ yẹn kalẹ̀ ní ọgọ́rùn-ún ọdún sẹ́yìn, méjìdínlógóje [138] ni àròpọ̀ gbogbo àwọn Akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, gẹ́gẹ́ bí a ti mọ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà sí nígbà yẹn, tí wọ́n wà ní ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì. Ọdún méjì lẹ́yìn náà, ìyẹn ní 1902, wọ́n ṣí ẹ̀ka kejì ní Jámánì; nígbà tó sì di ọdún 1904, wọn ti dá àwọn ẹ̀ka iléeṣẹ́ mìíràn sílẹ̀ ní Ọsirélíà àti ní Switzerland.

Ní ọdún 1918, ìyẹn ọdún tí Ogun Àgbáyé Kìíní parí, àwọn Akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì tó ń ròyìn ìgbòkègbodò iṣẹ́ ìwàásù kárí ayé jẹ́ ẹgbẹ̀rún mẹ́ta, ọgọ́rùn-ún mẹ́jọ àti méjìdínláàádọ́rin [3,868]. Ní ọdún tó tẹ̀ lé e, wọ́n ṣí ẹ̀ka iléeṣẹ́ Watch Tower Society karùn-ún—èyí jẹ́ ní Kánádà. Lẹ́yìn náà, bí iṣẹ́ ìpolongo ìhìn Bíbélì ti ń tẹ̀ síwájú, wọ́n tún ṣí àwọn ẹ̀ka tuntun sí i lónírúurú orílẹ̀-èdè, mẹ́fà ni wọ́n dá sílẹ̀ ní ọdún 1921 nìkan.

Nígbà to fi máa di ọdún 1931, ọdún táwọn Akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì bẹ̀rẹ̀ sí jẹ́ orúkọ náà táa gbé karí Bíbélì, Ẹlẹ́rìí Jèhófà, ẹ̀ka iléeṣẹ́ tó wà káàkiri ayé ti di ogójì. (Aísáyà 43:10-12) Láàárín ọdún mẹ́ta tó tẹ lé e, iye náà ti pọ̀ sí i, ó ti di mọ́kàndínláàádọ́ta! Lọ́dún 1938, iye àwọn Ẹlẹ́rìí tó ń wàásù ní orílẹ̀-èdè méjìléláàádọ́ta nígbà náà pọ̀ ju ti ìgbàkígbà rí lọ, wọ́n jẹ́ ẹgbẹ̀rún mọ́kàndínlọ́gọ́ta ó lé mẹ́tàdínláàádọ́ta [59,047], àmọ́ nígbà yẹn, àwọn èèyàn ti bẹ̀rẹ̀ sí ṣàtakò gan-an sí ìgbòkègbodò Kristẹni wọn láwọn ibi púpọ̀.

Bí ìṣèlú kànńpá àti ìṣàkóso bóofẹ́bóokọ̀ ti ń tàn kálẹ̀ láti orílẹ̀-èdè kan sí òmíràn, tí Ogun Àgbáyé Kejì sì bẹ́ sílẹ̀ ní September ọdún 1939, wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí ti àwọn ẹ̀ka iléeṣẹ́ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà pa láti orílẹ̀-èdè kan sí òmíràn. Nígbà tó fi máa di ọdún 1942, mẹ́ẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n péré ló kù tó ṣì ń báṣẹ́ lọ. Àmọ́ sí ìyàlẹ́nu wa, lákòókò tí ogun tó tíì burú jù lọ nínú ìtàn ẹ̀dá ènìyàn yẹn ń lọ lọ́wọ́, àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà káàkiri ayé kò dáwọ́ iṣẹ́ dúró jákèjádò ayé, iye wọn pọ̀ sí i, ìyẹn sì jẹ́ ọ̀kan nínú àwọn ìgbà tí iye wọn ròkè jù lọ nínú ìtàn òde òní.

Àní sẹ́, bí Ogun Àgbáyé Kejì ti ń parí lọ ní ọdún 1945—tí ọ̀pọ̀ ibi nínú ayé sì ti dahoro—wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí í ṣí àwọn ẹ̀ka iléeṣẹ́ àwọn Ẹlẹ́rìí tí wọ́n ti tì pa, wọ́n sì tún dá àwọn tuntun mìíràn sílẹ̀. Ní ọdún 1946, ó ti di mẹ́tàdínlọ́gọ́ta jákèjádò ayé. Mélòó sì làwọn Ẹlẹ́rìí tó ń ṣe déédéé nígbà yẹn? Iye wọn tó pọ̀ ju ti ìgbàkigbà rí nígbà yẹn jẹ́ ẹgbẹ̀rún mẹ́rìndínlọ́gọ́sàn-án àti irínwó ó lé mẹ́rìndínlọ́gọ́ta [176,456]! Ìyẹn fẹ́rẹ̀ẹ́ tó ìlọ́po mẹ́ta iye tí wọ́n jẹ́ ní ọdún 1938!

Bí Ẹ̀ka Iléeṣẹ́ Àkọ́kọ́ Ṣe Di Èyí Tó Tóbi Sí I

Ní ọdún 1911, a kó ẹ̀ka iléeṣẹ́ Watch Tower Society àkọ́kọ́ ní ìlú London, ní ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì, wá sí ojúlé 34 Craven Terrace, àyè wà níbẹ̀ dáadáa fún ọ́fíìsì àti ilé gbígbé ju ti tẹ́lẹ̀ lọ. Lẹ́yìn náà, ní April 26, 1959, a ya àwọn ẹ̀ka iléeṣẹ́ tuntun sí mímọ́ ní àdúgbò Mill Hill, ní ìlú London. Lẹ́yìn ìgbà yẹn, wọ́n kọ́ àwọn ilé gbígbé sí i, àsẹ̀yìnwá àsẹ̀yìnbọ̀ (lọ́dún 1993), wọ́n ya ilé ìtẹ̀wé àti ilé tí àwọn ọ́fíìsì wà, tí títóbi rẹ̀ jẹ́ ẹgbàásàn-án ó lé ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta [18,500] mítà níbùú lóròó sí mímọ́ nítòsí ibẹ̀. Ó lé ní àádọ́rùn-ún mílíọ̀nù [90,000,000] ẹ̀dà Ilé Ìṣọ́  àti Jí! tí wọ́n ń tẹ̀ jáde ní èdè mẹ́tàlélógún níbẹ̀.

Ṣíṣe ìmúgbòòrò ẹ̀ka Society kejì tiẹ̀ tún wá kàmàmà. Ní ọdún 1923, wọ́n kó ẹ̀ka ti Jámánì lọ sí Magdeburg. Ilé Ìṣọ́  July 15, 1923, ni ìwé ìròyìn tí wọ́n kọ́kọ́ tẹ̀ lórí ẹ̀rọ ìtẹ̀wé Society níbẹ̀. Láàárín àwọn ọdún díẹ̀ tó tẹ̀ lé e, wọ́n ra ilé kan tó wà nítòsí, wọ́n kọ́ kún àwọn ilé náà, wọ́n sì ra ẹ̀rọ tó ń di ìwé pọ̀ àtàwọn ẹ̀rọ ìtẹ̀wé sí i. Lọ́dún 1933, ìjọba Násì gbẹ́sẹ̀ lé ẹ̀ka náà, wọ́n tún fòfin de àwọn Ẹlẹ́rìí, bí àkókò sì ti ń lọ, wọ́n kó ẹgbẹ̀rún méjì lára wọn lọ sí àgọ́ ìṣẹ́niníṣẹ̀ẹ́.

Nígbà tí Ogun Àgbáyé Kejì parí ní ọdún 1945, wọ́n dá ilé iṣẹ́ tó wà ní Magdeburg tó jẹ́ apá kan Ìlà Oòrùn Jámánì nígbà yẹn padà, a sì tún bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ padà ní ẹ̀ka yẹn. Àmọ́ bó ṣe di August 30, 1950, làwọn ọlọ́pàá Kọ́múníìsì bá ya wọ ilé iṣẹ́ náà, wọ́n sì kó àwọn tó ń ṣiṣẹ́ níbẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni wọ́n tún fòfin de àwọn Ẹlẹ́rìí tó wà ní Ìlà Oòrùn Jámánì. Láàárín àkókò yẹn, ní ọdún 1947, wọ́n ti ra ilé kan ní Wiesbaden, ní Ìwọ̀ Oòrùn Jámánì. Ní àwọn ẹ̀wádún tó tẹ̀ lé e, léraléra ni wọ́n ń kọ́ kún àwọn ilé tí wọ́n kọ́ sí ẹ̀ka náà, kó ba lè kájú pípèsè àwọn ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ táwọn èèyàn ń béèrè fún.

Nígbà to di pé àyè ò sí mọ́ láti túbọ̀ mú ẹ̀ka Wiesbaden náà gbòòrò sí i, wọ́n ra ilẹ̀ kan tí títóbi rẹ̀ jẹ́ nǹkan bí ọgbọ̀n hẹ́kítà nítòsí ìlú Selters lọ́dún 1979. Lẹ́yìn nǹkan bí ọdún márùn-ún, wọ́n parí kíkọ́ ẹ̀ka iléeṣẹ́ ńlá náà a sì yà á sí mímọ́ ní April 21, 1984. Látìgbà náà ni wọ́n ti ń mú un gbòòrò sí i, ko ba lè gba àwọn òṣìṣẹ́ ẹ̀ka náà tí iye wọ́n lé lẹ́gbẹ̀rún. Lóṣooṣù, ó lé ní mílíọ̀nù mẹ́rìndínlógún ìwé ìròyìn tí wọ́n ń fi àwọn ẹ̀rọ ìtẹ̀wé ńláńlá tẹ̀ ní ohun tó lé ní ọgbọ̀n èdè ní Selters; lẹ́nu ọdún àìpẹ́ yìí sì rèé, ó lé ní mílíọ̀nù méjìdínlógún àwọn ìwé ńlá, títí kan Bíbélì tí wọ́n ṣe jáde ní ibi tí wọ́n ti ń dì ìwé pọ̀.

Àwọn Ẹ̀ka Iléeṣẹ́ Ńláńlá Mìíràn Tó Ń Tẹ̀wé

Lọ́dún 1927 ni wọ́n kọ́kọ́ dá ẹ̀ka kan sílẹ̀ ní Kobe, Japan, àmọ́ inúnibíni gbígbóná janjan tí wọ́n ṣe sáwọn Ẹlẹ́rìí lákòókò Ogun Àgbáyé Kejì bẹ́gi dínà ìgbòkègbodò wọn. Bó ti wù kó rí, kò pẹ́ rárá lẹ́yìn ogun yẹn tí wọ́n fi tún ẹ̀ka náà kọ́ sí Tokyo. Nígbà tí kò sáyè níbẹ̀ mọ́ láti mú un gbòòrò sí i, wọ́n kọ́ ẹ̀ka tuntun mìíràn sí Numazu. Ọdún 1973 ni wọ́n yà á sí mímọ́. Láìpẹ́, nígbà to di pé ibẹ̀ yẹn kò tún gbà wọ́n mọ́, wọ́n wá lọ kọ́ tuntun kan tó tóbi sí Ebina, ọdún 1982 ni wọ́n sì ya ìyẹn sí mímọ́. Àìpẹ́ yìí ni wọn parí àwọn ilé tí wọ́n mú gbòòrò sí i níbẹ̀, ó sì lè gba ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀rún [900] òṣìṣẹ́. Ó lé ní mílíọ̀nù mẹ́rìnléláàádọ́rùn-ún [94,000,000] ẹ̀dà Ilé Ìṣọ́  àti Jí! tí wọ́n tẹ̀ ní èdè Japanese nìkan ní ọdún 1999, bẹ́ẹ̀ ni wọ́n sì tẹ ọ̀pọ̀ mílíọ̀nù ìwé pẹ̀lú.

Ọ̀rọ̀ kò yàtọ̀ láti orílẹ̀-èdè kan sí òmíràn o, nígbà táa bá ń sọ nípa mímú àwọn ẹ̀ka gbòòrò sí i. Wọ́n kọ́ ẹ̀ka kan sí Ìlú Mẹ́síkò, lórílẹ̀ èdè Mẹ́síkò ní ọdún 1929. Nígbà tí iye àwọn Ẹlẹ́rìí nígbà yẹn lọ́hùn-ún di ọ̀kẹ́ mẹ́ta [60,000], wọ́n kọ́ iléeṣẹ́ kan tó túbọ̀ láyè sí i lẹ́yìn ìlú yẹn. Ọdún 1974 ni wọ́n yà á sí mímọ́, wọ́n sì parí àwọn tí wọ́n kọ́ ní àfikún sí i ní ọdún 1985 àti 1989. Lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí, wọ́n ti fẹ́rẹ̀ẹ́ parí ilé iṣẹ́ ìtẹ̀wé títóbi kan àti àwọn ilé gbígbé. Nípa bẹ́ẹ̀, yóò lè ṣeé ṣe láìpẹ́ fún ẹ̀ka Mẹ́síkò láti gba àwọn òṣìṣẹ́ tó tó ẹgbẹ̀fà [1,200]. Lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí, ẹ̀ka náà ń pèsè àwọn ìwé àti ìwé ìròyìn fún àwọn Ẹlẹ́rìí tó lé ní ìdajì mílíọ̀nù [500,000] àti fún ọ̀pọ̀ mílíọ̀nù àwọn èèyàn mìíràn ní Mẹ́síkò, àti fáwọn èèyàn tó ń gbé láwọn orílẹ̀-èdè tó wà ní tòsí pẹ̀lú.

Ní ọdún 1923, wọ́n dá ẹ̀ka kan sílẹ̀ ní ìlú Rio de Janeiro, ní orílẹ̀-èdè Brazil, lẹ́yìn náà ni wọ́n wá kọ́ àwọn ilé gbígbé tuntun, tó lẹ́wà síbẹ̀. Àmọ́ níwọ̀n ìgbà tó jẹ́ pé São Paulo ni ibi tí ètò ìrìnnà àti ètò ìṣòwò Brazil fìdí kalẹ̀ sí, wọ́n kọ́ ẹ̀ka kan sí ìlú náà ní ọdún 1968. Nígbà tó fi máa di àwọn ọdún 1970, àwọn Ẹlẹ́rìí tó wà ní Brazil ti ń lọ sí nǹkan bí i ẹgbẹ̀rún lọ́nà ọgọ́rùn-ún. Ṣùgbọ́n kò tún ṣeé ṣe mọ́ láti mú ẹ̀ka náà gbòòrò sí i ní São Paulo, nítorí náà wọ́n ra ilẹ̀ kan tó jẹ́ hẹ́kítà márùndínlọ́gọ́fà [115] ní Cesário Lange, ó fi nǹkan bí àádọ́jọ kìlómítà jìnnà sí ìlú São Paulo. Ní March 21, 1981, wọ́n ya ẹ̀ka ilé iṣẹ́ tí wọ́n kọ́ sórí ilẹ̀ tuntun náà sí mímọ́. Nítorí mímú tí wọ́n mú un gbòòrò sí i, ó wá ṣeé ṣe kí ẹ̀ka náà gba nǹkan bí i ẹgbẹ̀fà [1,200] èèyàn. Brazil ni wọ́n ti ń mú àwọn ìwé ìròyìn àtàwọn ìwé ńlá jáde fún púpọ̀ lára ilẹ̀ Gúúsù Amẹ́ríkà àti àwọn apá ibòmíràn láyé pẹ̀lú.

Wọ́n tún parí kíkọ́ ẹ̀ka kan tó ń tẹ̀wé ní ìbẹ̀rẹ̀ ọdún 1990, nítòsí Bogotá, ní Kòlóńbíà. Ibẹ̀ ni wọ́n ti ń tẹ àwọn ìwé ìròyìn Ilé Ìṣọ́ àti Jí! tó wà fún ìpínkiri káàkiri ìhà àríwá ìwọ̀ oòrùn Ilẹ̀ Gúúsù Amẹ́ríkà.

Àwọn ẹ̀ka mìíràn táwọn náà tún ń tẹ ọ̀pọ̀ mílíọ̀nù ìwé ìròyìn jáde lọ́dọọdún wà ní Ajẹntínà, Finland, Gúúsù Áfíríkà, Ítálì, Kánádà, Korea, Nàìjíríà, Ọsirélíà, Philippines, àti Sípéènì. Ẹ̀ka ti Ítálì tún ń tẹ ọ̀pọ̀ mílíọ̀nù ìwé jáde, títí kan Bíbélì, lọ́dọọdún ní ọ̀pọ̀ èdè. Àmọ́ o, púpọ̀ nínú àwọn ìwé tó ń jáde lọ́dọọdún yìí, èyí tó lé ní ogójì mílíọ̀nù ìwé ńlá àti ohun tó ju bílíọ̀nù kan ìwé ìròyìn lọ, ló jẹ́ pé oríléeṣẹ́ Watch Tower Bible and Tract Society ní Brooklyn, New York, àti ní ilé ìtẹ̀wé rẹ̀ tó wà ní apá àríwá ìpínlẹ̀ New York la ti ń ṣe wọ́n.

Ka sòótọ́, ohun tó jọni lójú gbáà ni pé iye àwọn ẹ̀ka ọ́fíìsì ti pọ̀ sí i, látorí ẹyọ kan ní ọgọ́rùn-ún ọdún sẹ́yìn dórí mọ́kàndínláàádọ́fà [109] lónìí, èyí tó ń pèsè ohun tí àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà nílò ní igbà ilẹ̀ ó lé mẹ́rìnlélọ́gbọ̀n [234]. Ká má tún ṣẹ̀ṣẹ̀ wá sọ ti nǹkan bí ẹgbẹ̀rún mẹ́tàlá [13,000] àwọn Kristẹni olùyọ̀ǹda ara ẹni tí wọ́n ń ṣiṣẹ́ níbẹ̀! Láìsíyèméjì, iṣẹ́ tí wọ́n ń ṣe, papọ̀ pẹ̀lú ti àwọn bí ẹ̀ẹ́dégbèjìndínlọ́gbọ̀n [5,500] olùyọ̀ǹda ara ẹni tí wọ́n wà ní oríléeṣẹ́ Society, ti jẹ́ ohun ṣíṣe pàtàkì sí mímú àsọtẹ́lẹ̀ Jésù Kristi náà ṣẹ pé ‘ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run yìí la ó wàásù rẹ̀ ní gbogbo ilẹ̀ ayé tí a ń gbé kí òpin tóo dé.’—Mátíù 24:14.

[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a Zion’s Watch Tower Tract Society ni wọ́n ń pè é nígbà yẹn.

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 25]

Tom Hart, tí a gbà pé òun ni Akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì àkọ́kọ́ ní ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì

[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 26]

Ẹ̀ka London tó wà ní ojúlé 34 Craven Terrace (nínú fọ́tò lápá ọ̀tún)

[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 26]

Àwọn ilé tí a ń lò lọ́wọ́lọ́wọ́ ní London