N Kì Í Fẹ́ Gba Ohunkóhun Gbọ́, Síbẹ̀ Mo Ṣì Ń Wá A Káàkiri
N Kì Í Fẹ́ Gba Ohunkóhun Gbọ́, Síbẹ̀ Mo Ṣì Ń Wá A Káàkiri
NÍNÚ lẹ́tà tí ọkùnrin kan tó sọ pé wọ́n batisí òun gẹ́gẹ́ bí ẹlẹ́sìn Kátólíìkì kọ sí ẹ̀ka iléeṣẹ́ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó wà ní ìlú Slovenia, ó sọ pé: “Ẹ jọ̀wọ́, ẹ fi ẹ̀dà ìwé pẹlẹbẹ náà, Kí Ni Ọlọrun Ń Béèrè Lọ́wọ́ Wa? ránṣẹ́ sí mi. Màá tún fẹ́ kí ẹ sọ fún mi nípa bí mo ṣe lè máa rí ẹ̀dà ìwé ìròyìn Jí! gbà déédéé nínú ilé mi.”
Ọkùnrin náà sọ pé: “Ẹ jọ̀wọ́, mi ò ní fẹ́ kẹ́ẹ ṣì mí lóye o. Tó bá ti dọ̀rọ̀ ẹlẹ́sìn dé, n kì í fẹ́ gba ohunkóhun gbọ́, àmọ́, nígbà tí mo ka Jí!, ẹnu yà mí gidigidi, nítorí kò sọ ọ̀rọ̀ tí kò lẹ́sẹ̀ nílẹ̀, kàkà bẹ́ẹ̀, ńṣe ló ṣàlàyé àwọn nǹkan lọ́nà tó ṣe tààràtà tó sì yéni yékéyéké.” Lẹ́yìn náà ló wá tọ́ka sí gbajúgbajà ìwé ìròyìn onísìn kan, tó sì sọ pé ńṣe ni ìwé ìròyìn náà kàn ń tan àwọn èèyàn jẹ tó sì ń lo agbára lórí wọn, tó ń sọ irú ẹni tó yẹ kí wọ́n dìbò fún—ẹni tó máa ṣe tiwa àti ẹni tí kò ní í ṣe.”
Ọkùnrin ọ̀hún ṣàlàyé ìdí tóun kò fi kọ ọ̀rọ̀ kún àwọn àlàfo tó wà lẹ́yìn Jí! láti fi béèrè fún ìwé pẹlẹbẹ Béèrè, àmọ́ tó jẹ́ pé ńṣe lòún yàn láti fọwọ́ ara òun kọ̀wé. Ó ní: “Mi ò fẹ́ ba ìwé ìròyìn Jí! náà jẹ́ rárá. Mo fẹ́ kó wà lódindi síbẹ̀!”
Ẹ̀kọ́ mẹ́rìndínlógún ni ìwé pẹlẹbẹ olójú ìwé méjìlélọ́gbọ̀n náà, Kí Ni Ọlọrun Ń Béèrè Lọ́wọ́ Wa? ní. A lè rí àrídájú àwọn ẹ̀kọ́ ṣíṣekókó látinú Bíbélì nínú wọn, àwọn ìsọfúnni Bíbélì nípa ohun tí a gbọ́dọ̀ ṣe láti rí ojú rere Ọlọ́run tún wà níbẹ̀ pẹ̀lú. Bí ìwọ náà bá fẹ́ ẹ̀dà kan ìwé pẹlẹbẹ yìí, jọ̀wọ́ kàn sí àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó wà ládùúgbò rẹ. Bóo bá fẹ́ kí ẹnì kan wá ọ wá, jọ̀wọ́ kọ̀wé sínú fọ́ọ̀mù tó wà nísàlẹ̀ yìí, kí o sì fi ránṣẹ́ sí àdírẹ́sì táa kọ sínú fọ́ọ̀mù náà, tàbí kí o fi ránṣẹ́ sí àdírẹ́sì tó yẹ lára èyí táa tò sójú ìwé 5 nínú ìwé ìròyìn yìí.
□ Ẹ jọ̀wọ́, ẹ kàn sí mi nípa ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì inú ilé lọ́fẹ̀ẹ́.
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 32]
Mílíọ̀nù mẹ́tàléláàádọ́fà ẹ̀dà ní òjìlénígba èdè