Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

“Ó Ń Fini Lọ́kàn Balẹ̀, Ó Tún Ń fún Ìgbàgbọ́ Lókun”

“Ó Ń Fini Lọ́kàn Balẹ̀, Ó Tún Ń fún Ìgbàgbọ́ Lókun”

“Ó Ń Fini Lọ́kàn Balẹ̀, Ó Tún Ń fún Ìgbàgbọ́ Lókun”

ỌPỌ́N ÈTÒ ÌKỌ́NILẸ́KỌ̀Ọ́ BÍBÉLÌ KÁRÍ AYÉ tí àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń ṣe onígbọ̀wọ́ rẹ̀ sún kan fífi ìwọ̀nba oṣù mélòó kan kẹ́kọ̀ọ́ ìtàn ayé ọjọ́un àti àsọtẹ́lẹ̀ tí a ṣàkọsílẹ̀ rẹ̀ nínú ìwé Dáníẹ́lì lẹ́nu àìpẹ́ yìí. Wo ìmọrírì ti a fi hàn nínú lẹ́tà tó wà nísàlẹ̀ yìí tí a rí gbà láti Poland.

“Tipẹ́tipẹ́ láti ń fẹ́ ní òye tó péye nípa àsọtẹ́lẹ̀ Dáníẹ́lì tó wà nínú Bíbélì. Ní báyìí, ọwọ́ wa ti tẹ ohun táa ń wá. Ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Kíyè sí Àsọtẹ́lẹ̀ Dáníẹ́lì! tí a ń lò náà, gbé ọ̀rọ̀ kalẹ̀ lọ́nà rírọrùn gan-an ni, èdè inú rẹ̀ yéni yékéyéké, àwọn àpèjúwe inú rẹ̀ pàápàá bùyààrì. Gbogbo èyí ló mú kí ìwé yìí jẹ́ ọ̀kan tó ń lani lọ́yẹ̀ tó sì tún ń yíni lérò padà. Ńṣe lèyí túbọ̀ mú kí ìgbọ́kànlé tí a ní ga sí i pé Ọlọ́run yóò ṣe ohun tó ní lọ́kàn láti ṣe ní àkókò tó tọ́. Ìwé títayọ lọ́lá táa fi ń kẹ́kọ̀ọ́ yìí ń fini lọ́kàn balẹ̀, ó sì tún ń fún ìgbàgbọ́ lókun.”

Ṣé ẹ̀mí àìnídàánilójú tó gbòde kan lónìí, tó ní nínú, ṣíṣe lámèyítọ́ ìtàn tó wà nínú Bíbélì láìnídìí ti kó ìdààmú bá ọ? Bó bá rí bẹ́ẹ̀, ìtẹ̀jáde náà tí a pè ní Kíyè sí Àsọtẹ́lẹ̀ Dáníẹ́lì! yóò ru ìmọ̀lára rẹ sókè yóò sì tún wọ̀ ọ́ lọ́kàn gidigidi. O lè rí ẹ̀dà kan ìwé yìí gbà tí o bá kàn sí àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó wà ládùúgbò rẹ. Bóo bá fẹ́ kí ẹnì kan wá ọ wá, jọ̀wọ́ kọ̀wé sínú fọ́ọ̀mù tó wà nísàlẹ̀ yìí, kí o sì fi ránṣẹ́ sí àdírẹ́sì táa kọ síbẹ̀ tàbí sí àdírẹ́sì tó yẹ lára èyí tí a tò sí ojú ìwé 5 nínú ìwé ìròyìn yìí.

□ Ẹ jọ̀wọ́, ẹ kàn sí mi nípa ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì inú ilé lọ́fẹ̀ẹ́.

[Àwọn àwòrán Credit Line tó wà ní ojú ìwé 32]

Àwòrán àwọn ará Páṣíà: Láti inú ìwé The Coloured Ornament of All Historical Styles; Alẹkisáńdà Ńlá: Roma, Musei Capitolini; àgbá alámọ̀: A ya fọ́tò nípasẹ̀ ìyọ̀ǹda onínúure ti British Museum