Ṣé Ó Yẹ Kí Ìgbéyàwó Wà Pẹ́ Títí?
Ojú Ìwòye Bíbélì
Ṣé Ó Yẹ Kí Ìgbéyàwó Wà Pẹ́ Títí?
KÍ LÓ dé táa fi ń béèrè irú ìbéèrè yẹn ná? Bí a bá ní ká sọ ọ́ bí ẹ̀jẹ́ àwọn ará Ìwọ̀ Oòrùn tí wí, kò ha yẹ kí ìgbéyàwó wà bẹ́ẹ̀ “nígbà òjò àti nígbà ẹ̀ẹ̀rùn” àti “títí dìgbà tíkú bá yà wá”? Bẹ́ẹ̀ ni, ńṣe ni ẹ̀jẹ́ ìgbéyàwó ń fi hàn pé ìyàwó ọ̀ṣìngín àti ọkọ rẹ̀ ń kó wọnú ìdè kan tí yóò wà pẹ́ títí. Àmọ́, ọ̀pọ̀ ènìyàn ni kò ronú mọ́ pé ìlérí tó ṣe pàtàkì yìí kàn wọ́n. Àìmọye tọkọtaya ló ti tú ká—kò tiẹ̀ ju oṣù díẹ̀ lẹ́yìn tí àwọn kán ṣe ìgbéyàwó tí wọ́n fi tú ká, nígbà tí àwọn mìíràn ṣe bẹ́ẹ̀ lẹ́yìn ọ̀pọ̀ ọdún. Ẹ gbọ́ ná, kí ló dé táwọn èèyàn fi wá bẹ̀rẹ̀ sí fọwọ́ yẹpẹrẹ mú ọ̀ràn ìgbéyàwó? Bíbélì sọ ohun tó fà á fún wa.
Jọ̀wọ́, gbé ohun tó wà nínú ìwé 2 Tímótì 3:1-3 yẹ̀ wò, kí o sì wá fi í wéra pẹ̀lú àwọn ohun tóo kíyè sí pé ó gbòde kan lónìí. Àwọn ẹsẹ wọ̀nyẹn kà lápá kan pé: “Ní àwọn ọjọ́ ìkẹyìn, àwọn àkókò lílekoko tí ó nira láti bá lò yóò wà níhìn-ín. Nítorí àwọn ènìyàn yóò jẹ́ olùfẹ́ ara wọn, olùfẹ́ owó, . . . aláìlọ́pẹ́, aláìdúróṣinṣin, aláìní ìfẹ́ni àdánidá, aláìṣeé bá ṣe àdéhùn kankan, . . . aláìní ìkóra-ẹni-níjàánu.” Àsọtẹ́lẹ̀ Bíbélì yìí péye lóòótọ́. Àwọn ìṣarasíhùwà tí a mẹ́nu kàn níbẹ̀ ti ba ọ̀pọ̀ ìgbéyàwó jẹ́, ó sì ti sọ ọ̀pọ̀ wọn di ahẹrẹpẹ káàkiri àgbáyé, tí ìkọ̀sílẹ̀ tó ń ròkè lálá sì fi èyí hàn.
Ó hàn gbangba pé, ọ̀pọ̀ èèyàn ni kò tiẹ̀ bọ̀wọ̀ fún ìgbéyàwó mọ́. Bọ́ràn ṣe wá rí yìí, a lè béèrè pé: Ṣé nǹkan tó yẹ ká fọwọ́ dan-indan-in mú ni ìgbéyàwó tiẹ̀ jẹ́? Ṣé ohun kan tiẹ̀ wà tó ń jẹ́ ìjẹ́mímọ́ ìgbéyàwó? Ojú wo ló yẹ kí àwọn Kristẹni máa fi wo ìgbéyàwó? Ìrànlọ́wọ́ wo ni Bíbélì pèsè fún àwọn tí wọ́n ti gbéyàwó lóde òní?
Ṣé Ohun Tí Ọlọ́run Ní Lọ́kàn Ti Yí Padà Ni?
Ní ìbẹ̀rẹ̀pẹ̀pẹ̀, Ọlọ́run ò sọ pé ìdè ìgbéyàwó á kàn wà fún kìkì ìgbà díẹ̀ ni. Bó ṣe so ọkùnrin àti obìnrin àkọ́kọ́ pa pọ̀ ló wà nínú ìwé Jẹ́nẹ́sísì 2:21-24, a kò sì rí i kà níbẹ̀ pé bí wọ́n bá fẹ́ wọ́n lè jáwèé ìkọ̀sílẹ̀ tàbí kí wọ́n pínyà. Kàkà bẹ́ẹ̀, ńṣe ni ẹsẹ 24 sọ pé: ‘Ọkùnrin yóò fi baba rẹ̀ àti ìyá rẹ̀ sílẹ̀ yóò sì fà mọ́ aya rẹ̀, wọn yóò sì di ara kan.’ Kí ni ẹsẹ Ìwé Mímọ́ yẹn túmọ̀ sí?
Tiẹ̀ ronú nípa ara ènìyàn ná, bí oríṣiríṣi ìṣùpọ̀ ẹran ara ṣe hun mọ́ ara wọn láìní ojú ibi tí a ti so wọ́n pọ̀ àti bí àwọn egungun ṣe so pọ̀ mọ́ ara wọn tí wọ́n fi lágbára, tí kò sì sí pé ọ̀kan há sínú èkejì. Ìṣọ̀kan yìí mà kàmàmà o! Wíwà pẹ́ títí wọn náà tún bùyààrì! Àmọ́ bí ẹ̀yà ara tí a ń sọ yìí bá lọ gbọgbẹ́ pẹ́nrẹ́n, ìrora náà máa ń kọjá kèrémí! Nítorí náà, nínú Jẹ́nẹ́sísì 2:24, gbólóhùn náà, “ara kan” ń tẹnu mọ́ ìsúnmọ́ra tímọ́tímọ́ àti wíwà pẹ́ títí ìdè ìgbéyàwó. Bákan náà ló tún kìlọ̀ fún wa nípa ìrora lílékenkà tó máa ń jẹ yọ bí ìdè náà bá tú ká.
Bó tilẹ̀ jẹ́ pé èrò tó ń yí padà ṣáá ní àwọn ẹgbẹ̀rún ọdún tó ti kọjá ti mú kí àwọn èèyàn máa ní onírúurú èrò nípa ìgbéyàwó, síbẹ̀, Ọlọ́run ṣì ń wò ó gẹ́gẹ́ bí ohun kan tó gbọ́dọ̀ wà pẹ́ títí. Ní nǹkan bí egbèjìlá ọdún [2,400] sẹ́yìn, àwọn ọkùnrin Júù kan bẹ̀rẹ̀ sí kọ àwọn aya tí wọ́n kọ́kọ́ fẹ́ sílẹ̀ tí wọ́n sì ń fi àwọn ọ̀ṣọ́ọ́rọ́ obìnrin mìíràn ṣaya. Ọlọ́run dẹ́bi fún irú àṣà yìí, ó tiẹ̀ tẹnu wòlíì rẹ̀ Málákì sọ pé: “‘Kí ẹ sì ṣọ́ ara yín ní ti ẹ̀mí yín, kí ẹnikẹ́ni má sì ṣe àdàkàdekè sí aya ìgbà èwe rẹ̀. Nítorí òun kórìíra ìkọ̀sílẹ̀,’ ni Jèhófà Ọlọ́run Ísírẹ́lì wí.”—Málákì 2:15, 16.
Ní ohun tó ju ọ̀rúndún mẹ́rin lẹ́yìn náà, ojú tí Ọlọ́run fi wo ìgbéyàwó ní ìbẹ̀rẹ̀ ni Jésù tún fìdí ẹ̀ múlẹ̀ nígbà tó ṣàyọlò ọ̀rọ̀ tó wà nínú ìwé Jẹ́nẹ́sísì 2:24, tó sì wá pàṣẹ pé: “Ohun tí Ọlọ́run ti so pọ̀, kí ènìyàn kankan má ṣe yà á sọ́tọ̀.” (Mátíù 19:5, 6) Ọ̀pọ̀ ọdún lẹ́yìn náà, àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù sọ pé “kí aya má lọ kúrò lọ́dọ̀ ọkọ rẹ̀” àti pé “kí ọkọ má sì fi aya rẹ̀ sílẹ̀.” (1 Kọ́ríńtì 7:10, 11) Àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ wọ̀nyí fi ojú tí Ọlọ́run fi ń wo ìgbéyàwó hàn lọ́nà tó pé.
Ǹjẹ́ Bíbélì tiẹ̀ fìgbà kan rí gbà pé kí ìgbéyàwó kan tú ká páàpáà? Bẹ́ẹ̀ ni, ìgbéyàwó kan yóò tú ká bí ẹnì kan lára àwọn méjèèjì bá kú. (1 Kọ́ríńtì 7:39) Ìwà panṣágà tún lè fòpin sí ìgbéyàwó kan bí ọkọ tàbí aya tí ẹnì kejì rẹ̀ ṣe panṣágà náà bá pinnu bẹ́ẹ̀. (Mátíù 19:9) Bí bẹ́ẹ̀ kọ́, ohun tí Bíbélì sọ ni pé kí tọkọtaya wà pa pọ̀.
Bí A Ṣe Lè Mú Kí Ìgbéyàwó Wà Pẹ́ Títí
Ọlọ́run fẹ́ kí ìgbéyàwó wà pẹ́ títí, dípò tí ì bá fi jẹ́ òní ẹjọ́ ọ̀la àròyé, ó fẹ́ kó jẹ́ ìrìn àjò aláyọ̀. Ó fẹ́ kí ọkọ àti aya yanjú àwọn ìṣòro tí wọ́n bá ní kí wọ́n sì gbádùn jíjọ wà wọn. Ọ̀rọ̀ rẹ̀ pèsè àwọn ìtọ́sọ́nà tó lè mú kí ìgbéyàwó kan mìrìngìndìn, kó sì wà pẹ́ títí. Jọ̀wọ́ ṣàkíyèsí àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ tó wà nísàlẹ̀ wọ̀nyí.
Éfésù 4:26: “Ẹ má ṣe jẹ́ kí oòrùn wọ̀ bá yín nínú ipò ìbínú.” a Ọkùnrin kan tí ìdùnnú jọba nínú ilé rẹ̀ rí i pé ẹsẹ Ìwé Mímọ́ yìí ran òun àti ìyàwó òun lọ́wọ́ láti yanjú èdè àìyedè ní kíá tó bá ti ṣẹlẹ̀. Ó ní: “Bóò bá lè sùn lẹ́yìn tí èdè àìyedè bá ṣẹlẹ̀ láàárín yín, a jẹ́ pé nǹkan ò tíì gún régé nìyẹn o. Kò sì ní dáa pé kóo fi ìṣòro ọ̀hún sílẹ̀ bẹ́ẹ̀.” Nígbà mìíràn pàápàá, ọkùnrin yìí àti ìyàwó rẹ̀ yóò jíròrò kúnnákúnná nípa àwọn èdè àìyedè wọn títí di ọ̀gànjọ́ òru. Èyí sì ti ràn wọ́n lọ́wọ́. Ó fi kún un pé: “Fífi àwọn ìlànà inú Bíbélì sílò ti mú àwọn àbájáde tó yani lẹ́nu wá.” Nípa ṣíṣe bẹ́ẹ̀, ìgbéyàwó ọkùnrin tí a ń wí yìí àti ìyàwó rẹ̀ ti dùn yùngbà yungba fún odindi ọdún méjìlélógójì báyìí.
Kólósè 3:13: “Ẹ máa bá a lọ ní fífaradà á fún ara yín lẹ́nì kìíní-kejì, kí ẹ sì máa dárí ji ara yín fàlàlà lẹ́nì kìíní-kejì.” Ọkọ kan ṣàlàyé bí òun àti ìyàwó òun ṣe fi èyí sílò. Ó sọ pé: “Tọkọtaya lè mú inú bí ara wọn láìjẹ́ pé wọ́n ṣe ohun kan tó burú ní ti gidi, nígbà tó kúkú jẹ́ pé kálukú ló ní àbùkù tirẹ̀ lára àti àwọn ìwà tó lè mú kí inú bí ẹlòmíràn. A máa ń fara dà á fún ara wa nípa ṣíṣàìjẹ́ kí àwọn nǹkan wọ̀nyí da àárín wa rú.” Ẹ ò rí nǹkan, èrò yẹn ti ran tọkọtaya yìí lọ́wọ́ fún odindi ọdún mẹ́rìnléláàádọ́ta tí wọ́n ti ṣe ìgbéyàwó!
Bí àwọn tọkọtaya bá ń fi irú àwọn ìlànà bí ìwọ̀nyí tó wà nínú Ìwé Mímọ́ sílò, ńṣe ni ìdè tó so tọkọtaya pọ̀ yóò túbọ̀ máa lágbára sí i. Èyí yóò sì mú kí ìgbéyàwó wọn jẹ́ èyí tó mìrìngìndìn, tó ń tẹ́ni lọ́rùn, tó sì wà pẹ́ títí.
[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Gẹ́gẹ́ bí àwọn ará Àárín Gbùngbùn Ìlà Oòrùn ṣe ń ka ọjọ́, ọjọ́ kan máa ń wá sí òpin nígbà tí oòrùn bá wọ̀. Pọ́ọ̀lù ń tipa báyìí gba àwọn òǹkàwé níyànjú láti yanjú awuyewuye èyíkéyìí tí wọ́n bá ní kí ọjọ́ kọ̀ọ̀kan tó dópin.