Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Báwo Lo Ṣe Lè Fara Da—Àmódi Tí Ń Ṣe Ọ́?

Báwo Lo Ṣe Lè Fara Da—Àmódi Tí Ń Ṣe Ọ́?

Báwo Lo Ṣe Lè Fara Da—Àmódi Tí Ń Ṣe Ọ́?

JẸ́ KÓ dá ọ lójú pé àwọn èrò tó ṣeé ṣe kó máa wá sọ́kàn ẹ ṣáá tọ̀nà. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé o mọ̀ pé kò sóhun tóo lè ṣe sí àìsàn tó ń ṣe ọ́ tàbí àkóbá tó ti fà, síbẹ̀ ọkàn rẹ ò ní gba àwọn ìyípadà tí àìsàn náà fipá mú bá ọ. Ó lè dà bí ìgbà tí ìwọ àti àìsàn tó ń ṣe ọ́ jọ ń wọ̀yá ìjà, ìjàkadì láàárín ẹni tóo ti jẹ́ rí àti ohun tó ṣeé ṣe kó sọ ẹ́ dà. Àmọ́ báyìí, ó lè wa jọ pé àìsàn tó ń ṣe ọ́ ló ń mókè. Síbẹ̀, o lè ṣe nǹkan sí i. Lọ́nà wo?

Dókítà Kitty Stein sọ pé: “Nígbà tí àìsàn bá mú kéèyàn pàdánù nǹkan kan, bí ìgbà téèyàn kú lo ṣe máa ń rí lára onítọ̀hún.” Nípa bẹ́ẹ̀, tóo bá pàdánù ohun kan tó ṣeyebíye fún ọ bí ìlera rẹ, kò sóhun tó burú nínú ẹ̀ rárá tóo bá sunkún tóo sì ṣọ̀fọ̀ nítorí ẹ̀, gan-an bí wàá ṣe ṣe ká ní ẹnì kan tóo fẹ́ràn ló kú. Àní ká sòótọ́, ó lè jẹ́ pé kì í ṣe ìlera rẹ nìkan lo pàdánù. Ńṣe ló rí bí obìnrin kan ṣe ṣàlàyé pé, “Mo ní láti fi iṣẹ́ mi sílẹ̀. . . . Mi ò lómìnira tí mo ti ń gbádùn ẹ̀ nígbà gbogbo tẹ́lẹ̀ mọ́.” Ká tiẹ̀ lọ́rọ̀ dà bẹ́ẹ̀, má sọ àwọn ohun tóo pàdánù náà di bàbàrà ju bó ṣe yẹ lọ. Dókítà Stein, ẹni tóun fúnra ẹ̀ ní àrùn iṣan ara líle gbagidi fi kún un pé: “Ó yẹ kóo dárò ohun tóo pàdánù, àmọ́ o, ó tún yẹ kóo mọyì àwọn ohun tóo ṣì ní.” Àní sẹ́, lẹ́yìn tóo bá ti bọ́ lọ́wọ́ ẹkún tóo máa ń sun tẹ́lẹ̀, wàá rí i pé àwọn nǹkan ṣì wà tóo ní tí kò yingin. Ó kéré tán, ó ṣì lágbára láti mú ara ẹ bá ipò yẹn mu.

Kò sóhun tí atukọ̀ ojú omi kan lè ṣe kí ìjì má jà, àmọ́ ó lè là á já nípa títún aṣọ ìgbòkun ọkọ̀ rẹ̀ ta. Ìwọ náà lè má lè ṣẹ́pá àìsàn tó kọ lu ìgbésí ayé rẹ bí ìjì líle, àmọ́ ó lè kojú rẹ̀ nípa títún “ìgbòkun” rẹ ta, ìyẹn làwọn ohun tóo ní, tara, ti èrò orí, àti tìmọ̀lára. Kí ló ti ran àwọn mìíràn tí àìsàn bára kú ń ṣe lọ́wọ́ láti ṣèyẹn?

Mọ̀ Nípa Àìsàn Tó Ń Ṣe Ọ́

Lẹ́yìn tí ọ̀pọ̀ ti borí wàhálà tó bá wọn nígbà tí wọ́n kọ́kọ́ gbọ́ èsì àyẹ̀wò ìṣègùn wọn, wọ́n ti wá rí i pé ó kúkú sàn kéèyàn mọ òtítọ́ nípa ohun tó ń ṣe é jù kó kàn wà nínú ìbẹ̀rù lọ. Nígbà tó jẹ́ pé ìbẹ̀rù lè má jẹ́ kóo mọ ohun tó yẹ kóo ṣe, mímọ ohun tó ń ṣẹlẹ̀ sí ọ lè ràn ọ́ lọ́wọ́ láti jẹ́ kóo gbé ohun tí wàá ṣe yẹ̀ wò—ìyẹn nìkan fúnra rẹ̀ sì ní ipa tó dára tó ń kó. Dókítà David Spiegel ti Yunifásítì Stanford sọ pé: “Ìwọ wo bára ẹ ṣe máa yá gágá tó nígbà tóo bá rí ohun tó yẹ kóo ṣe sí nǹkan kan tó ń dà ẹ́ láàmú. Kó tiẹ̀ tó di pé o ṣe ohunkóhun sí i rárá, wàá tiẹ̀ ṣì dín àìfararọ tí o ń ní kù ná, nípa wíwéwèé ohun tí wàá ṣe sí i.”

O lè fẹ́ láti túbọ̀ mọ̀ sí i nípa ipò rẹ. Ṣe ló dà bí òwe kan nínú Bíbélì tó sọ pé, “ènìyàn tí ó ní ìmọ̀ . . . ń mú kí agbára túbọ̀ pọ̀ sí i.” (Òwe 24:5) Ọkùnrin kan tí kò lè dìde ńlẹ̀ mọ́ dámọ̀ràn báyìí pé: “Wá àwọn ìwé ní ibi ìkówèésí. Mọ gbogbo ohun tóo bá lè mọ̀ nípa àìsàn tó ń ṣe ọ́.” Bí o ti ń mọ̀ nípa irú ìtọ́jú tó wà lárọ̀ọ́wọ́tó àtàwọn ọ̀nà tóo lè gbà kojú àìsàn ọ̀hún, bóyá o tiẹ̀ lè wá rí i pé ipò rẹ ò burú tó bóo ṣe ń bẹ̀rù rẹ̀ tẹ́lẹ̀. O tiẹ̀ tún lè rí ìdí láti gbà pé nǹkan ṣì máa dára.

Àmọ́ ṣá o, pé o ti wá ní òye díẹ̀ nípa àìsàn tó ń ṣe ọ́ kọ́ nibi tóò ń lọ gan-an. Dókítà Spiegel ṣàlàyé pé: “Ìsọfúnni tí o ń kó jọ yìí wà lára ohun pàtàkì tó máa jẹ́ kóo lè lóye àìsàn náà, kóo sì fojú tó tọ́ wò ó.” Kì í rọrùn láti gbà pé ńṣe ni ìgbésí ayé rẹ wulẹ̀ yí padà, pé kì í ṣe pé ó dópin, ó sì lè pẹ́ díẹ̀ kí èyí tó yé ọ. Àmọ́ ìgbésẹ̀ àkọ́kọ́ yìí—ìyẹn lílóye àìsàn tó ń ṣe ọ́ tó fi dórí títẹ́wọ́ gbà á—jẹ́ ohun tóo lè gbà mọ́ra. Lọ́nà wo?

Rírí Ohun Tóo Lè Fi Kojú Ìbànújẹ́

Ó lè pọndandan pé kóo tún èrò rẹ ṣe nípa ohun tí títẹ́wọ́gba àìsàn tó ń ṣe ọ́ túmọ̀ sí. Ó ṣe tán, pé o gbà pé òótọ́ lára ẹ ò dá kì í ṣe àmì pé o kùnà, bó ṣe jẹ́ pé kì í ṣe ìkùnà fún atukọ̀ kan láti gbà pé òótọ́ lòún wà nínú ìjì. Kàkà bẹ́ẹ̀, ńṣe ni rírí i pé ìjì ń jà ní ti gidi máa jẹ́ kí atukọ̀ náà tètè wá nǹkan ṣe. Lọ́nà kan náà, títẹ́wọ́gba àìsàn tó ń ṣe ọ́ kì í ṣe pé o kùnà, gẹ́gẹ́ bí ohun ti obìnrin kan tí àìsàn bára ku ń ṣe sọ, ó wulẹ̀ túmọ̀ sí “yíyà sí ọ̀nà mìíràn ni.”

Kódà bí àwọn ohun tóo ti lè dá ṣe fúnra ẹ tẹ́lẹ̀ bá ti dín kù, o lè máa rán ara ẹ létí pé kò pọndandan kíyẹn nípa lórí àwọn ànímọ́ rẹ ní ti èrò orí, ti ìmọ̀lára àti tẹ̀mí. Fún àpẹẹrẹ, ṣé làákàyè tóo ní láti ṣètò nǹkan lọ́nà tó gún régé àti agbára ìrònú rẹ ṣì wà níbẹ̀? Ó sì lè jẹ́ pé ẹ̀rín músẹ́ rẹ yẹn, bóo ṣe máa ń bìkítà nípa àwọn ènìyàn yẹn, àti bóo ṣe máa ń tẹ́tí sílẹ̀ dáadáa táwọn ẹlòmíì bá ń sọ̀rọ̀ tóo sì tún jẹ ọ̀rẹ́ tòótọ́ ṣì wà níbẹ̀ sẹpẹ́. Èyí tó tún wá ṣe pàtàkì jù ni pé ìgbàgbọ́ rẹ nínú Ọlọ́run ṣì wà digbí.

Láfikún sí i, fi sọ́kàn pé bó tilẹ̀ jẹ́ pé kì í ṣe gbogbo ohun tó dé sí ọ lo lè yí padà, síbẹ̀ o ṣì lè pinnu ohun tí wàá ṣe nípa wọn. Irene Pollin, tó ń ṣiṣẹ́ ní Ilé Ẹ̀kọ́ Àpapọ̀ Nípa Àrùn Jẹjẹrẹ, sọ pé: “Ohun tóo máa ṣe nípa àìsàn tó dé sí ọ wà ní ìkáwọ́ ẹ. Ọwọ́ tó sì wù kí àìsàn náà yọ, agbára yẹn ṣì wà lọ́wọ́ ẹ.” Helen, obìnrin kan tó jẹ́ ẹni àádọ́rin ọdún tí àrùn iṣan ara líle gbagidi tó ń ṣe é ti túbọ̀ gogò sí i sọ pé: “Kì í ṣe àìsàn tó ń ṣe ọ́ yẹn, àmọ́ ọwọ́ tóo fi mú un ló máa pinnu bóyá o ṣì mọ ohun tóò ń ṣe.” Ọkùnrin kan tó ti kojú àléébù ara fún ohun tó lé ní ogún ọdún sọ pé: “Níní ẹ̀mí tó dára ni oògùn tí kò ní jẹ́ kóo bọ́hùn.” Àní sẹ́, Òwe 18:14 sọ pé: “Ẹ̀mí ènìyàn lè fara da àrùn rẹ̀; ṣùgbọ́n ní ti ẹ̀mí tí ìdààmú bá, ta ní lè mú un mọ́ra?”

Kíkọ́fẹ Padà

Bí ìrònú rẹ ti ń padà bọ̀ sípò, àwọn ìbéèrè bíi ‘Kí ló dé tí irú nǹkan báyìí fi ṣẹlẹ̀ sí mi?’ lè wá yí padà di ‘Ìgbà tọ́rọ̀ mi ti dà báyìí, kí wá ni ṣíṣe?’ Ibí yìí ni o lè ti wá yan àwọn ìgbésẹ̀ míì tó máa gbé láti ṣe ju ohun tóo ti ń ṣe tẹ́lẹ̀. Jẹ́ ká gbé díẹ̀ yẹ̀ wò.

Gbé ipò ẹ yẹ̀ wò, ronú ohun tó yẹ kóo wá àtúnṣe sí, sì wá ọ̀nà láti ṣàyípadà àwọn nǹkan tó bá ṣeé yí padà. Dókítà Spiegel sọ pé: “Àìsàn tó ń ṣe ọ́ fún ẹ láǹfààní láti tún ìgbésí ayé ẹ gbé yẹ̀ wò, ó jẹ́ àkókò láti jí sí ohun tó yẹ ní ṣíṣe, kì í ṣe àmì pé gbogbo ẹ̀ ti parí nìyẹn.” Bi ara rẹ pé, ‘Kí lohun tó ṣe pàtàkì fún mi ṣáájú kí àìsàn yí tó bẹ̀rẹ̀ sí ṣe mí? Ìyípadà wo ló ti dé bá ìyẹn?’ Béèrè irú àwọn ìbéèrè yìí, kì í ṣe láti mọ àwọn ohun tí o kò lè ṣe mọ́, àmọ́ kí o lè mọ àwọn ohun tóo ṣì lè ṣe ni, bóyá nípa yíyí ọ̀nà tóo ń gbà ṣe wọ́n tẹ́lẹ̀ padà. Fún àpẹẹrẹ, ìwọ wo Helen táa mẹ́nu kàn níṣàáájú.

Láti ọdún mẹ́ẹ̀dọ́ọ́gbọ̀n sẹ́yìn ni àrùn iṣan líle gbagidi ti sọ àwọn iṣan ara rẹ̀ di aláìlera. Ó kọ́kọ́ ń lo igi láti fi rìn. Nígbà tó yá, tí kò lè lo ọwọ́ ọ̀tún rẹ̀ mọ́, ló bá bẹ̀rẹ̀ sí í lo tòsì nìkan. Nígbà tó tún ṣe, tòsì náà tún kọṣẹ́. Nígbà tó yá, ní bí ọdún mẹ́jọ sẹ́yìn, kò tiẹ̀ wá lè rìn mọ́ rárá. Ní báyìí, ó wá di dandan kí àwọn ẹlòmíràn máa wẹ̀ ẹ́, kí wọ́n máa fún un lóúnjẹ, kí wọ́n sì máa wọṣọ fún un. Èyí máa ń bà á nínú jẹ́, bó tilẹ̀ rí bẹ́ẹ̀, ohun tó sọ ni pé: “Ìlànà tí mo ní lọ́kàn ò yí padà, ìyẹn ni, ‘Ronú ohun tóo lè ṣe, má ronú nípa ohun tóo ti ń ṣe rí.’” Pẹ̀lú ìrànlọ́wọ́ ọkọ rẹ̀ àti tàwọn nọ́ọ̀sì tó máa ń wá bẹ̀ ẹ́ wò àti ìdánúṣe òun fúnra rẹ̀, ó máa ń gbìyànjú láti ṣe díẹ̀ lára àwọn ohun tó ti fẹ̀ẹ̀kàn gbádùn àtimáaṣe. Fún àpẹẹrẹ, àtìgbà tó ti wà lọ́mọ ọdún mọ́kànlá ni sísọ ìlérí Bíbélì nípa ayé tuntun alálàáfíà tí ń bọ̀ fáwọn ẹlòmíràn ti jẹ́ apá tó ṣe pàtàkì nínú ìgbésí ayé rẹ̀, ó sì ń ṣe bẹ́ẹ̀ lọ́sọ̀ọ̀sẹ̀ títí dòní olónìí. (Mátíù 28:19, 20) Helen sọ bí òún ṣe ń ṣe é:

“Mo máa ń ní kí nọ́ọ̀sì tó wá ń tọ́jú mi nílé gbé ìwé ìròyìn dání fún mi. A óò wá jùmọ̀ ka àwọn ìkéde òkú tó wà nínú ẹ̀, àá sì wá yọ àwọn kan sọ́tọ̀. Lẹ́yìn ìyẹn, màá wá sọ àwọn ohun tí mo fẹ́ kó wà nínú lẹ́tà sí àwọn ẹbí ẹni tó kú náà fún nọ́ọ̀sì yẹn, òun ló máa wá tẹ̀ ẹ́ síwèé. Ohun tí mo máa ń fi ránṣẹ́ pẹ̀lú lẹ́tà náà ni ìwé pẹlẹbẹ náà, Nígbà Tí Ẹnìkan Tí Ìwọ Fẹ́ràn Bá Kú, a èyí tó ṣàlàyé ìrètí atuninínú tí Bíbélì sọ nípa àjíǹde. Mo máa ń ṣe èyí ní ọ̀sán ní gbogbo ọjọ́ Sunday. Sísọ ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run fún àwọn ẹlòmíràn máa ń múnú mi dùn.”

Gbé àwọn góńgó tó bọ́gbọ́n mu tọ́wọ́ sì lè tẹ̀ kalẹ̀. Ìdí kan tó mú Helen tiraka pé òún máa ṣàyípadà ohun tó ṣe é yí padà ni pé, ó jẹ́ kó ṣeé ṣe fún un láti gbé àwọn góńgó kalẹ̀, kọ́wọ́ rẹ̀ sì tẹ̀ wọ́n. Èyí ṣe pàtàkì fún ìwọ náà pẹ̀lú. Èé ṣe? Nítorí pé gbígbé góńgó kalẹ̀ máa jẹ́ kóo fọkàn sí nǹkan kan tó wà níwájú, tọ́wọ́ ẹ bá sì tẹ̀ wọ́n, ìyẹn á jẹ́ kóo nímọ̀lára pé o ṣàṣeyege. Ó tiẹ̀ tún lè jẹ́ kóo lè gbára lé ara ẹ díẹ̀ sí i. Àmọ́ rí i dájú pé àwọn góńgó tóo gbé kalẹ̀ ṣe pàtó. Fún àpẹẹrẹ, o lè pinnu pé: ‘Màá rí i pé mo ka orí kan nínú Bíbélì lónìí.’ Tún rí i pé àwọn góńgó tọ́wọ́ ẹ máa lè tẹ̀ lo gbé kalẹ̀. Níwọ̀n bí ara tìẹ àti bí nǹkan ṣe máa ń rí lára ẹ ti yàtọ̀ sí tàwọn ẹlòmíràn táwọn náà ń ṣàìsàn ọlọ́jọ́ pípẹ́, ọwọ́ ẹ lè má lè tẹ irú góńgó kan náà bíi tiwọn.—Gálátíà 6:4.

Lex, tó ń gbé ní Netherlands sọ pé: “Kò sí bí góńgó kan ti lè dà bí èyí tó kéré tó, tọ́wọ́ ẹ bá ti lè tẹ̀ ẹ́, á mú kóo tún fẹ́ ṣe sí i.” Ní ohun tó ju ogún ọdún sẹ́yìn, nígbà tó jẹ́ ẹni ọdún mẹ́tàlélógún, ó kàgbákò jàǹbá kan tó sọ ọ́ di alárùn ẹ̀gbà. Ní àkókò tó fi ń gba ìtọ́jú lẹ́yìn ìgbà yẹn, wọ́n rọ̀ ọ́ pé kó gbé àwọn góńgó kalẹ̀, irú bíi kó lè máa fi aṣọ ìfọjú fọ ojú fúnra ẹ̀. Kò rọrùn fún un, àmọ́ ó ṣàṣeyọrí. Nígbà tó rí i pé òun ti lé góńgó yẹn bá, ló bá tún gbé òmíràn kalẹ̀—ìyẹn ni ṣíṣí agolo ọṣẹ ìfọyín àti dídé e padà. Lẹ́ẹ̀kan sí i, ó tún ṣàṣeyọrí. Lex sọ pé: “Bó tilẹ̀ jẹ́ pé kò rọrùn, mo wá rí i pé mo lè ṣe ju ohun tí mo rò pé màá lè ṣe lọ.”

Àní sẹ́, pẹ̀lú àtìlẹ́yìn ìyàwó rẹ̀, Tineke, ọwọ́ Lex tẹ àwọn góńgó tó ga. Fún àpẹẹrẹ, bí Tineke, ṣe ń tẹ̀ lé e, ó ti ṣeé ṣe fún un láti máa lọ láti ilé dé ilé báyìí lórí àga àwọn arọ láti fi ìmọ̀ Bíbélì kọ́ àwọn ẹlòmíràn. Ó tún máa ń bẹ ọkùnrin kan tó lálèébù ara bíbùáyà wò lọ́sọ̀ọ̀sẹ̀ láti fún un ní ìṣírí àti láti kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì pẹ̀lú rẹ̀. Lex sọ pé: “Ríran àwọn ẹlòmíràn lọ́wọ́ ń mú inú mi dùn gidigidi.” Bí Bíbélì ṣe sọ ọ́ gẹ́lẹ́ ló rí pé, “ayọ̀ púpọ̀ wà nínú fífúnni ju èyí tí ó wà nínú rírígbà lọ.”—Ìṣe 20:35.

Ṣé ìwọ náà lè gbé àwọn góńgó kalẹ̀ láti ran àwọn ẹlòmíràn lọ́wọ́? Àárẹ̀ tàbí ìṣòro tó dé bá ọ lè ràn ọ́ lọ́wọ́ láti jẹ́ ẹni tó mọ èèyàn tù nínú dáadáa, nítorí àwọn ìṣòro rẹ ti túbọ̀ jẹ́ kóo mọ bí ìrora ṣe ń rí lára àwọn ẹlòmíràn.

Máa kàn sí àwọn èèyàn. Ìwádìí ìṣègùn fi hàn pé níní àjọṣe pẹ̀lú àwọn èèyàn dára púpọ̀ fún ìlera rẹ. Àìṣe bẹ́ẹ̀ náà sì tún níbi tó ń já sí. Olùṣèwádìí kan sọ pé: “Bó ṣe jẹ́ pé sìgá mímu . . . máa ń yọrí sí ikú, bẹ́ẹ̀ náà ni yíya ara ẹni sọ́tọ̀ ṣe lè fa ikú.” Ó fi kún un pé: “Mímú kí àjọṣe rẹ pẹ̀lú àwọn èèyàn túbọ̀ dán mọ́rán sí i lè ṣàǹfààní fún ìlera rẹ gẹ́gẹ́ bí jíjáwọ́ nínú sìgá mímu ti ṣe pàtàkì fún ìlera.” Abájọ tó fi parí ọ̀rọ̀ rẹ̀ pé mímọ̀ táa bá mọ báa ti ń lájọṣe pẹ̀lú àwọn èèyàn “ṣe pàtàkì fún ìwàláàyè wa”!—Òwe 18:1.

Àmọ́ ṣá o, gẹ́gẹ́ bí a ti sọ nínú àpilẹ̀kọ tó ṣáájú, ó lè jẹ́ ọwọ́ àwọn ọ̀rẹ́ rẹ ni ìṣòro yẹn wà, tí wọ́n kọ̀ láti máa wá ẹ wá. Jọ̀wọ́, nítorí tara ẹ, o gbọ́dọ̀ wá nǹkan ṣe sí ìnìkanwà rẹ. Àmọ́ báwo ni wàá ṣe ṣe é? O lè bẹ̀rẹ̀ láti ibi kíkésí àwọn ọ̀rẹ́ rẹ láti wá bẹ̀ ọ́ wò.

Jẹ́ kí wíwá bẹ̀ ọ́ wò jẹ́ ohun tó ń gbádùn mọ́ wọn. b O lè ṣe bẹ́ẹ̀ nípa dídín ọ̀rọ̀ tóo máa ń sọ nípa àìsàn tó ń ṣe ọ́ kù, kí agara gbígbọ́ nípa rẹ̀ má bàa dá wọn. Obìnrin kan tí àìsàn tó ń ṣe é ti di bára kú yanjú ìṣòro yìí nípa fífòté lé iye ìgbà tó fí ń bá ọ̀kọ̀ ẹ̀ sọ̀rọ̀ nípa àìsàn rẹ̀. Ó ní, “a gbọ́dọ̀ dín in kù ṣáá ni.” Àní sẹ́, kò yẹ kí àìsàn tó ń ṣe ọ́ ṣèpalára fún gbogbo ohun mìíràn tóo lè ṣàjọpín rẹ̀. Olùṣèbẹ̀wò kan, lẹ́yìn tóun àti ọ̀rẹ́ rẹ̀ tí kò lè dìde ńlẹ̀ ti jọ sọ̀rọ̀ nípa ọgbọ́n-ọnà, ìtàn, àtàwọn ìdí tó mú un gba Jèhófà Ọlọ́run gbọ́, sọ pé: “Ọ̀rẹ́ mi kò jẹ́ kí àìsàn tó ń ṣe é gba ìwà tó ní tẹ́lẹ̀ lọ́wọ́ ẹ̀. Ọ̀rọ̀ táa jọ sọ gbádùn mọ́ mi gan-an ni.”

Ṣíṣe àwàdà máa tún jẹ́ kínú àwọn ọ̀rẹ́ rẹ dùn láti yà wò ẹ́. Yàtọ̀ síyẹn, rírẹ́rìn-ín tún ṣàǹfààní fún ìwọ gan-an alára. Ọkùnrin kan tó ní àrùn Parkinson sọ pé: “Ṣíṣe àwàdà máa ràn ẹ́ lọ́wọ́ láti kojú ìṣòro tó bá dojú kọ ẹ́, àtèyí tóo bá báranínú rẹ̀.” Àní sẹ́, ẹ̀rín lè jẹ́ oògùn gidi. Òwe 17:22 sọ pé: “Ọkàn-àyà tí ó kún fún ìdùnnú ń ṣe rere gẹ́gẹ́ bí awonisàn.” Kódà ẹ̀rín tóo rín fún ìṣẹ́jú díẹ̀ ní oore tó máa ṣe ẹ́. Òǹkọ̀wé kan, Susan Milstrey Wells, tí àìsàn bárakú ń ṣe òun fúnra ẹ̀ sọ pé: “Ẹ̀rín yàtọ̀ pátápátá sí gbogbo àwọn oògùn tó kù táa ti dán wò, kò léwu rárá, kò ní májèlé, ó sì ń dùn mọ́ni. Ńṣe ló tiẹ̀ tún máa ń jẹ́ ká pa ìbànújẹ́ rẹ́.”

Wá ọ̀nà láti dín másùnmáwo kù. Àwọn ìwádìí fi hàn pé másùnmáwo lè mú kí àwọn àmì àrùn kan túbọ̀ di èyí tó burú sí i, nígbà tó sì jẹ́ pé dídín másùnmáwo kù máa ń ṣèrànwọ́ láti lè fara dà wọ́n. Nítorí náà, máa já ara rẹ gbà lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan. (Oníwàásù 3:1, 4) Má sọ àìsàn tó ń ṣe ọ́ di nǹkan tí wàá máa fi gbogbo ọjọ́ ayé ronú nípa rẹ̀. Bó bá jẹ́ pé ńṣe ni àìsàn tó ń ṣe ọ́ sé ẹ mọ́lé, o lè gbìyànjú láti dín ìrònú rẹ kù nípa fífetísí orin tó rọra ń dún, kíkàwé, wíwẹ ìwẹ̀ fún àkókò tó gùn, kíkọ lẹ́tà tàbí ewì, fífọ̀dà ya àwòrán, fífi ohun èlò orin ṣeré, bíbá ọ̀rẹ́ kan tóo finú tán sọ̀rọ̀, tàbí kóo lọ́wọ́ nínú àwọn ìgbòkègbodò bí ìwọ̀nyí. Ṣíṣe bẹ́ẹ̀ ò ní yanjú ìṣòro ẹ pátápátá o, àmọ́ ó lè mú kára tù ọ́ díẹ̀.

Bóo bá lè rìn, rìn jáde, lọ rajà, tu oko láyìíká, wọ ọkọ̀ tàbí, tó bá ṣeé ṣe, lọ fún ìsinmi. Lóòótọ́, rírìnrìn àjò lè nira fún ọ nítorí àìsàn tó ń ṣe ọ́, àmọ́ tóo bá lè múra sílẹ̀ dáadáa tóo sì wá ọgbọ́n dá sí i, ó lè ṣeé ṣe kóo ṣẹ́pá àwọn ohun ìdènà kan. Fún àpẹẹrẹ, Lex àti Tineke, táa mẹ́nu kan níṣàájú wá ọ̀nà láti rìnrìn àjò lọ sí òkè òkun. Lex sọ pé: “Ó nira gan-an lákọ̀ọ́kọ́, àmọ́, a gbádùn ìsinmi náà gidigidi!” Àní sẹ́, bó tilẹ̀ jẹ́ pé àìsàn tó ń ṣe ọ́ ti di apá kan ìgbésí ayé rẹ, àmọ́ kò wá yẹ kó jọba lé ìgbésí ayé rẹ lórí.

Jèrè okun látinú ìgbàgbọ́. Àwọn Kristẹni tòótọ́ tí wọ́n ti ṣàṣeyọrí nínú kíkojú àwọn àìlera tó gogò sọ pé ìgbàgbọ́ àwọn nínú Jèhófà Ọlọ́run àti dídarapọ̀ mọ́ ìjọ Kristẹni ti jẹ́ orísun ìtùnú àti okun ìgbà gbogbo fáwọn. c Díẹ̀ rèé lára àwọn ọ̀rọ̀ tí wọ́n sọ nípa ìjẹ́pàtàkì gbígbàdúrà, kíkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, ṣíṣàṣàrò lórí ọjọ́ iwájú, àti lílọ sáwọn ìpàdé Kristẹni ní Gbọ̀ngàn Ìjọba.

● “Lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan, inú mi ṣì máa ń bà jẹ́. Nígbà tíyẹn bá ṣẹlẹ̀, mo máa ń gbàdúrà sí Jèhófà, ó sì máa ń sọ ìpinnu mi dọ̀tun láti máa bá a lọ láti ṣe àwọn ohun ti mo ṣì lè ṣe.”—Sáàmù 55:22; Lúùkù 11:13.

● “Kíka Bíbélì àti ṣíṣàṣàrò lórí ohun tí mo kà máa ń ràn mí lọ́wọ́ gan-an ni láti mú kí ọkàn mi balẹ̀.”—Sáàmù 63:6; 77:11, 12.

● “Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì máa ń rán mi létí pé ìgbésí ayé gidi ṣì wà lọ́jọ́ iwájú àti pé mí ò ní máa jẹ́ aláàbọ̀ ará lọ títí ayé.”—Aísáyà 35:5, 6; Ìṣípayá 21:3, 4.

● “Níní ìgbàgbọ́ nínú ọjọ́ iwájú tí Bíbélì ṣèlérí rẹ̀ máa ń fún mi lókun láti kojú ohun tí ọjọ́ kọ̀ọ̀kan ní ìgbésí ayé bá mú wá.”—Mátíù 6:33, 34; Róòmù 12:12.

● “Wíwà nípàdé nínú Gbọ̀ngàn Ìjọba máa ń mú mi pọkàn pọ̀ sórí àwọn nǹkan tí ń gbéni ró, kì í sì í jẹ́ kí ń máa ronú nípa àìsàn tó ń ṣe mí.”—Sáàmù 26:12; 27:4.

● “Ìbákẹ́gbẹ́ oníṣìírí pẹ̀lú àwọn mẹ́ńbà ìjọ máa ń mọ́kàn mi yọ̀.”—Ìṣe 28:15.

Bíbélì mú un dá wa lójú pé: “Jèhófà jẹ́ ẹni rere, ibi odi agbára ní ọjọ́ wàhálà. Ó sì mọ àwọn tí ń wá ibi ìsádi lọ́dọ̀ rẹ̀.” (Náhúmù 1:7) Wíwà tímọ́tímọ́ pẹ̀lú Jèhófà Ọlọ́run àti dídarapọ̀ mọ́ ìjọ Kristẹni ni orísun ìtùnú àti okun.—Róòmù 1:11, 12; 2 Kọ́ríńtì 1:3; 4:7.

Fúnra Rẹ Lákòókò

Nígbà tí òṣìṣẹ́ afẹ́nifẹ́re kan tó máa ń ran àwọn èèyàn lọ́wọ́ láti kojú àwọn ohun tí àìsàn ọlọ́jọ́ pípẹ́ máa ń fà ń sọ̀rọ̀ nípa bóo ṣe máa fara da àìsàn tó le tàbí àléébù ara tó ń yọ ẹ́ lẹ́nu, ó ní “kì í ṣe ohun tóo kàn lè ṣe lọ́jọ́ kan, yóò gba àkókò.” Ògbógi mìíràn dámọ̀ràn pé kóo fúnra ẹ lákòókò, nítorí ńṣe lo ṣẹ̀ṣẹ̀ ń kọ́ “ohun kan tó yàtọ̀ pátápátá: ìyẹn bóo ṣe lè kojú àìsàn líle tó ń ṣe ọ́.” Mọ̀ dájú pé bóo bá tiẹ̀ ní ìṣarasíhùwà tó dára, àwọn ọjọ́ tàbí ọ̀sẹ̀ kan lè wà táwọn ohun tó jẹyọ látinú àìsàn tó ń ṣe ọ́ máa káàárẹ̀ bá ọ. Àmọ́ ṣá o, bí àkókò ti ń lọ, o lè rí ìyàtọ̀. Bọ́ràn obìnrin kan ṣe rí nìyẹn, ẹni tó sọ pé: “Inú mi dùn gidigidi nígbà tí mo rí i pé odindi ọjọ́ kan kọjá lọ, mi ò si ṣèèṣì ronú nípa àrùn jẹjẹrẹ tó ń bá mi jà. . . . Ìgbà kan wà tó jẹ́ pé mi ò ronú pé ìyẹn lè ṣeé ṣe rárá.”

Láìṣe àní-àní, tóo bá ti lè la àwọn ìbẹ̀rù àkọ́kọ́ já tóo sì ti gbé àwọn góńgó tuntun kalẹ̀, ó lè yà ọ́ lẹ́nu láti rí i bí wàá ṣe lè kojú ẹ̀ dáadáa—gẹ́gẹ́ bí àpilẹ̀kọ tó tẹ̀ lé èyí yóò ṣe jẹ́ ká rí i.

[Àwọ̀n Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a Èyí tí Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania tẹ̀ jáde.

b Dájúdájú, àwọn ìmọ̀ràn lórí bó ṣe yẹ kóo máa ṣe sáwọn tó ń wá bẹ̀ ọ́ wò kan bóo ṣe ń hùwà sí ọkọ rẹ tàbí aya rẹ, àwọn ọmọ rẹ, tàbí ẹni tó ń tọ́jú ẹ.

c Ó dùn mọ́ni pé, ọ̀pọ̀ ìwádìí ìṣègùn ló ti fi hàn pé níní ìgbàgbọ́ máa ń ṣàlékún ìlera ó sì ń mú kára ẹni yá gágá. Gẹ́gẹ́ bí Ọ̀jọ̀gbọ́n Dale Matthews ti Yunifásítì Ẹ̀kọ́ṣẹ́ Ìṣègùn ní Georgetown ti sọ, “àǹfààní tó ń wá látinú níní ìgbàgbọ́ ti fi hàn pé ó ṣe pàtàkì.”

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 19]

Mímọ̀ nípa àìsàn tó ń ṣe ọ́ lè ràn ẹ́ lọ́wọ́ láti lè kápá rẹ̀

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 20]

Pẹ̀lú ìrànlọ́wọ́ àwọn ẹlòmíràn, Helen máa ń kọ àwọn lẹ́tà tó ń gbéni ró

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 20]

“Sísọ ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run fún àwọn ẹlòmíràn máa ń múnú mi dùn”

[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 21]

“Bó tilẹ̀ jẹ́ pé mo ní àrùn ẹ̀gbà, mo wá rí i pé mo lè ṣe ju ohun tí mo rò pé màá lè ṣe lọ.”—Lex