Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Bí Àwọn Òbí Mi Bá Sọ Pé Mi Ò Tíì Tẹ́ni Ń Dájọ́ Àjọròde Ńkọ́?

Bí Àwọn Òbí Mi Bá Sọ Pé Mi Ò Tíì Tẹ́ni Ń Dájọ́ Àjọròde Ńkọ́?

Àwọn Ọ̀dọ́ Béèrè Pé . . .

Bí Àwọn Òbí Mi Bá Sọ Pé Mi Ò Tíì Tẹ́ni Ń Dájọ́ Àjọròde Ńkọ́?

“Ẹ ò mọ nǹkan tó lòde, Mọ́mì. Ìgbà ti yí padà. Gbogbo èèyàn ló ń dájọ́ àjọròde! N kì í ṣe ìkókó yín ọjọ́un mọ́.”—Janie, ọmọbìnrin ọlọ́dún mẹ́rìndínlógún. a

Ó MÁA ká ọ lára gan-an bí ẹnì kan bá sọ fún ọ pé o ò tíì dàgbà tó láti dájọ́ àjọròde. Ọmọkùnrin kan sọ pé: “Mo fẹ́ ṣe ìgbọràn sí àṣẹ Bíbélì tó sọ pé kí n bọlá fún bàbá àti ìyá mi, àmọ́ ó dà bí ẹni pé èyí tí wọ́n wá sọ yìí pé kí n má ṣe dájọ́ àjọròde kò bọ́ sí i rárá. Mi ò tiẹ̀ mọ bí mo ṣe lè bá wọn sọ ọ́.” Ìwọ náà lè ronú bíi ti ọmọkùnrin yìí pé àwọn òbí rẹ kì í gba tèèyàn rò bẹ́ẹ̀ sì ni wọn ò láàánú lójú. Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé o ti rí ẹnì kan tóo fẹ́ràn gan-an tóo sì fẹ́ túbọ̀ mọ̀ dáadáa. Tàbí bóyá o rò pé wíwọ ẹgbẹ́ àwọn tó ń dájọ́ àjọròde yóò mú kí o túbọ̀ bá ẹgbẹ́ mu. Ọmọbìnrin kan tó ń jẹ́ Michelle sọ pé: “Ńṣe làwọn ọmọ ilé ìwé ẹgbẹ́ ẹ máa gbógun tì ọ́. Bí o kì í bá dájọ́ àjọròde, wọ́n á sọ pé ńṣe ni wọ́n ń sà sí ọ.”

Olùgbani-nímọ̀ràn nípa ìdílé kan sọ nípa dídá ọjọ́ àjọròde pé: “Lójú àwọn ọmọ, ó fẹ́rẹ̀ẹ́ jẹ́ pé níbi ọ̀ràn dídá ọjọ́ àjọròde ni àwọn òbí ti máa ń yarí jù.” Àmọ́, ṣé nítorí pé àwọn òbí ẹ kò jẹ́ kóo ṣe ohun tóo fẹ́ ṣe lọ́tẹ̀ yìí wá túmọ̀ sí pé kì í gbọ́ kì í gbà ni wọ́n? Ó ṣe tán, àwọn òbí rẹ ni Ọlọ́run fún láṣẹ láti kọ́ ọ lẹ́kọ̀ọ́, kí wọ́n dáàbò bò ọ́, kí wọ́n sì tún tọ́ ọ sọ́nà. (Diutarónómì 6:6, 7) Ṣé o kò ronú pé àwọn òbí rẹ ń ṣàníyàn gan-an nípa àwọn ohun tó lè ṣe ọ́ láǹfààní? Ìyá kan sọ pé: “Mo rí ewu náà tó ń rọ̀ dẹ̀dẹ̀, ewu náà sì ń bani lẹ́rù gan-an ni.” Kí ló tiẹ̀ fà á tí títètè bẹ̀rẹ̀ sí dájọ́ àjọròde fi máa ń kó ìdágìrì bá ọ̀pọ̀ òbí?

Èrò Tó Léwu

Beth, ọmọbìnrin ọlọ́dún mẹ́rìnlá sọ pé: “Ńṣe làwọn òbí mi mú kó dà bí ẹni pé kò dára kéèyàn fẹ́ràn ẹnì kan.” Bó ti wù ó rí, bó bá jẹ́ pé Kristẹni làwọn òbí rẹ, wọ́n mọ̀ dáadáa pé Ọlọ́run dá takọtabo láti ní òòfà fún ara wọn. (Jẹ́nẹ́sísì 2:18-23) Wọ́n mọ̀ pé òòfà àtinúwá yìí jẹ́ àdánidá, pé ó ń ṣiṣẹ́ ní ìbámu pẹ̀lú ète Ẹlẹ́dàá fún ìran ènìyàn láti “kún ilẹ̀ ayé.”—Jẹ́nẹ́sísì 1:28.

Síwájú sí i, àwọn òbí rẹ mọ bí ìfẹ́ ọkàn fún ìbálòpọ̀ ṣe máa ń mú hánhán nígbà tóo ṣì wà ní “ìgbà ìtànná òdòdó èwe.” (1 Kọ́ríńtì 7:36) Bákan náà ni wọ́n mọ̀ pé o kò tíì mọ bí o ṣe lè ṣàkóso irú ìfẹ́ ọkàn bẹ́ẹ̀. Bí o bá ń lo àkókò tó pọ̀ pẹ̀lú ẹnì kan tó jẹ́ ẹ̀yà kejì, tàbí nípa bíbá a sọ̀rọ̀ lórí tẹlifóònù, àbí nípa kíkọ lẹ́tà, tàbí kíkọ lẹ́tà orí kọ̀ǹpútà, òòfà àtinúwá yìí yóò ga sí i. O lè béèrè pé, ‘Kí wá lohun tó burú nínú ìyẹn?’ Ó dára, ǹjẹ́ o ní ọ̀nà kan tí ó tọ́ láti tẹ́ àwọn ìfẹ́ ọkàn wọ̀nyí lọ́rùn? Ṣé o ti gbára dì ní tòótọ́ láti ṣe ohun tí àwọn ìfẹ́ ọkàn wọ̀nyí fẹ́ kóo ṣe, ìyẹn ni ìgbéyàwó? Kò jọ bẹ́ẹ̀.

Nítorí náà, títètè bẹ̀rẹ̀ sí dájọ́ àjọròde léwu gidi gan-an. Bíbélì sọ pé: “Ṣé ọkùnrin kan lè wa iná jọ sí oókan àyà rẹ̀, síbẹ̀síbẹ̀ kí ẹ̀wù rẹ̀ gan-an má sì jóná?” (Òwe 6:27) Lọ́pọ̀ ìgbà ni dídá ọjọ́ àjọròde nígbà tí ẹnì kan bá ṣì kéré máa ń yọrí sí ìbálòpọ̀ ṣáájú ìgbéyàwó, èyí tó lè tètè mú kí àwọn èwe gboyún láìṣe ìgbéyàwó tàbí kí wọ́n kó àwọn àrùn tí ìbálòpọ̀ takọtabo ń ta látaré. (1 Tẹsalóníkà 4:4-6) Fún àpẹẹrẹ, ọmọbìnrin kan tó ń jẹ́ Tammy rò pé ńṣe ni àwọn òbí òun ń ṣe ojúsàájú nígbà tí wọn ò jẹ́ kó dájọ́ àjọròde. Ló bá bẹ̀rẹ̀ sí dájọ́ àjọròde pẹ̀lú ẹnì kan ní ilé ìwé láìjẹ́ kí ẹnikẹ́ni mọ̀. Ṣùgbọ́n láìpẹ́, Tammy lóyún—bí ìgbésí ayé rẹ̀ ṣe yí padà nìyẹn o. Ní báyìí, ó wá sọ pé: “Kì í ṣe bí mo ṣe rò pé dídá ọjọ́ àjọròde ṣe máa ga lọ́lá tó ló ṣe wá rí.”

Àmọ́, bí àwọn ọ̀dọ́ méjì tí wọ́n jọ ń dájọ́ àjọròde bá fi tìṣọ́ratìṣọ́ra yẹra fún rírí ara wọn ní gbogbo ìgbà ńkọ́? Bó tiẹ̀ rí bẹ́ẹ̀, ewu pé kí wọ́n máa ru ìfẹ́ sókè nínú ara wọn láìtó àkókò ṣì wà níbẹ̀. (Orin Sólómọ́nì 2:7) Ìjákulẹ̀ àti ìbànújẹ́ ló máa ń tìdí ẹ̀ yọ béèyàn bá ń súnná sí àwọn ìfẹ́ ọkàn tó jẹ́ pé ó ṣì máa di ọ̀pọ̀ dún lọ́jọ́ iwájú kéèyàn tó lè tẹ́ ẹ lọ́rùn lọ́nà tó bẹ́tọ̀ọ́ mu.

Àwọn kókó mìíràn tó yẹ kéèyàn ronú lé lórí: Ṣé ìrírí tí o ti ní nínú ìgbésí ayé ti tó fún ọ láti mọ àwọn ànímọ́ tó yẹ kí o wò lára ẹni tóo fẹ́ fẹ́? (Òwe 1:4) Yàtọ̀ sí ìyẹn, ṣé ìwọ náà ti ní àwọn ànímọ́ àti òye iṣẹ́ tí yóò mú kí o di ọkọ tàbí aya tí a fẹ́ràn tí a sì bọ̀wọ̀ fún? Ṣé o lè ní sùúrù kí o sì pinnu láti fẹ́ ẹni náà sọ́nà fún àkókò tó gùn jàn-àn-ràn jan-an-ran bẹ́ẹ̀? Kò yani lẹ́nu pé èyí tó pọ̀ jù lára àwọn ìfararora ìfẹ́ tí àwọn ọ̀dọ́langba ń ní kì í tọ́jọ́, ó sì máa ń fa ẹ̀dùn ọkàn. Ìwọ̀nba díẹ̀ ló máa ń yọrí sí ìgbéyàwó tó wà pẹ́ títí.

Monica, ọmọ ọdún méjìdínlógún parí ọ̀rọ̀ nígbà tó sọ pé: “Gbogbo àwọn ọ̀rẹ́ mi ní ilé ẹ̀kọ́ ni wọ́n máa ń sọ̀rọ̀ nípa àwọn ọ̀rẹ́kùnrin wọn fún mi. Àmọ́ níkẹyìn, yálà kí wọ́n ṣe ìgbéyàwó kògbókògbó tàbí kí wọ́n fi ìbànújẹ́ túká nítorí pé wọn ò tíì gbára dì láti ṣe ìgbéyàwó.” Ọmọkùnrin kan tó ń jẹ́ Brandon náà sọ pé: “Bóò bá tíì ṣe tán láti bá ẹnì kan ṣàdéhùn pé o máa fẹ́ ẹ, tóo sì wá rí i pé o ti ṣe bẹ́ẹ̀ nítorí pé ẹ ń dájọ́ àjọròde, ó máa ń dani lọ́kàn rú gan-an ni. Báwo lo ṣe máa sọ pé o ò ṣe mọ́ tóò sì ní ba ẹnì kejì nínú jẹ́?”

Kò sí iyè méjì pé irú ìrora àti ẹ̀dùn ọkàn yìí làwọn òbí ẹ ò fẹ́ kóo ní, ìdí nìyẹn tí wọ́n fi yarí fún ọ pé o kò gbọ́dọ̀ dájọ́ àjọròde títí tí wàá fi dàgbà tó láti bá ẹnì kan ṣe àdéhùn ìgbéyàwó. Àmọ́, ká sòótọ́, àwọn òbí rẹ wulẹ̀ ń hùwà ní ìbámu pẹ̀lú ìmọ̀ràn onímìísí tó wà nínú ìwé Oníwàásù 11:10 ni, tó sọ pé: “Mú pákáǹleke kúrò ní ọkàn-àyà rẹ, kí o sì taari ìyọnu àjálù kúrò ní ẹran ara rẹ.”

‘Gbígbòòrò Síwájú’

Àmọ́ o, èyí kò túmọ̀ sí pé ìwọ àti ẹ̀yà kejì ò lè jọ ní ìbákẹ́gbẹ́ tó ládùn. Àmọ́, kí ló dé tó fi jẹ́ pé ẹnì kan ṣoṣo gíro lò ń bá ṣe wọlé wọ̀de? Bíbélì gbà wá níyànjú ní ibòmíràn pé ká “gbòòrò síwájú” nínú ìbákẹ́gbẹ́ wa. (2 Kọ́ríńtì 6:12, 13) Ìmọ̀ràn gidi lèyí jẹ́ fún àwọn èwe. Ọ̀nà kan tí a lè gbà ṣe èyí ni láti kóra jọ pọ̀ ní àwùjọ àwùjọ, tọkùnrin tobìnrin. Tammy ṣàlàyé pé: “Ó máa ń gbádùn mọ́ni gan-an táa bá ṣe é bẹ́ẹ̀. Ó dára gan an ni kéèyàn ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọ̀rẹ́.” Monica náà sọ pé: “Ti pé ká máa kóra jọ pọ̀ ní àwùjọ àwùjọ yẹn dára gan-an ni, nítorí pé wàá rí ọ̀pọ̀lọpọ̀ èèyàn pẹ̀lú oríṣiríṣi ìwà wọn, ìyẹn á sì wá jẹ́ kóo mọ̀ pé àìmọye àwọn èèyàn ló wà tí o ò tíì bá pàdé rí.”

Àwọn òbí rẹ tiẹ̀ lè kín ẹ lẹ́yìn láti múra sílẹ̀ fún ìbákẹ́gbẹ́ tó gbámúṣé pẹ̀lú àwọn èwe mìíràn pàápàá. Anne, tó jẹ́ ìyá ọlọ́mọ méjì, sọ pé: “Gbogbo ìgbà la máa ń rí i dájú pé ilé wa jẹ́ ibì kan táwọn ọmọ ti lè gbádùn ara wọn dáadáa. A máa ń ké sí àwọn ọ̀rẹ́ wọn pé kí wọ́n wá, a máa ń fún wọn ní ìpápánu, a sì máa ń jẹ́ kí wọ́n ṣeré ìdárayá. Nípa báyìí, wọn kì í ní in lọ́kàn pé káwọn lọ síta láti lọ gbádùn ara àwọn.”

Bí ẹ bá sì tún kóra jọ pọ̀ ní àwùjọ àwùjọ pàápàá, o tún gbọ́dọ̀ ṣọ́ra fún fífún ẹnì kan ní àfiyèsí tó pọ̀ jù. Àwọn ọ̀dọ́ kan ronú pé bí àwọn bá ti wà pa pọ̀ pẹ̀lú àwọn ẹlòmíràn, ìyẹn túmọ̀ sí pé àwọn ò dájọ́ àjọròde. Ṣọ́ra kí o má ṣe tan ara rẹ jẹ. (Sáàmù 36:2) Bó bá jẹ́ pé ìwọ àti ẹnì kan pàtó lẹ jọ máa ń ṣe kùrùkẹrẹ ní gbogbo ìgbà tí ẹ bá kóra jọ pọ̀ pẹ̀lú àwọn ọ̀rẹ́, a jẹ́ pé ẹ ti ń dájọ́ àjọròde nìyẹn o. b Sapá láti rí i dájú pé o ń ṣe ìpinnu tó bọ́gbọ́n mu nínú ìbádọ́rẹ̀ẹ́ rẹ pẹ̀lú ẹ̀yà kejì.—1 Tímótì 5:2.

Àǹfààní Kéèyàn Ní Sùúrù

Inú rẹ ò ní dùn nígbà tí ẹnì kan bá sọ fún ọ pé o ò tíì tẹ́ni ń dájọ́ àjọròde. Àmọ́ kì í ṣe pé àwọn òbí rẹ ń gbìyànjú láti ṣe ohun tí yóò bà ọ́ nínú jẹ́. Kàkà bẹ́ẹ̀, ńṣe ni wọ́n ń ṣe gbogbo ohun tí wọ́n bá lè ṣe láti ràn ọ́ lọ́wọ́ kí wọ́n sì dáàbò bò ọ́. Fún ìdí yìí, dípò kí o gbẹ́kẹ̀ lé ọkàn-àyà ara rẹ kí o sì tipa bẹ́ẹ̀ máa fọwọ́ rọ́ àwọn ìmọ̀ràn wọn tì sẹ́gbẹ̀ẹ́ kan, kí ló dé tóò kúkú fi ìrírí tiwọn ṣàríkọ́gbọ́n? Fún àpẹẹrẹ, èé ṣe tóò sọ pé kí wọ́n fún ọ nímọ̀ràn nígbà míì tóo bá ní ìṣòro láti bá ẹ̀yà kejì kẹ́gbẹ́? Ìwe Òwe 28:26 fún wa ní ìṣílétí náà pé: “Ẹni tí ó bá gbẹ́kẹ̀ lé ọkàn-àyà ara rẹ̀ jẹ́ arìndìn.” Ọ̀dọ́bìnrin kan tó ń jẹ́ Connie sọ pé: “Bíbá tí mo bá mọ́mì mi sọ̀rọ̀ ló ràn mí lọ́wọ́ nígbà tí ọmọkùnrin kan fẹ́ kó sí mi lórí láti bá a dájọ́ àjọròde. Mọ́mì sọ ìrírí nípa àwọn nǹkan tó ṣẹlẹ̀ sí àwọn ọ̀rẹ́ àti ẹbí rẹ̀ sẹ́yìn fún mi. Ó ràn mí lọ́wọ́ gidi gan-an ni.”

Níní sùúrù díẹ̀ kóo tó bẹ̀rẹ̀ sí dájọ́ àjọròde kì yóò ṣe ìpalára kankan fún ìdàgbàsókè èrò rẹ, kò sì ní ṣèdíwọ́ fún òmìnira rẹ. O ní òmìnira láti ‘máa yọ̀ ní ìgbà èwe rẹ,’ nítorí pé o ò tíì bẹ̀rẹ̀ sí ṣe ohun táwọn àgbà ń ṣe, ìyẹn ìfẹ́rasọ́nà àti ìgbéyàwó. (Oníwàásù 11:9) Níní sùúrù yóò tún fún ọ lákòókò láti mú àkópọ̀ ìwà dídára dàgbà, yóò jẹ́ kóo dàgbà dénú, ju gbogbo rẹ̀ lọ, á jẹ́ kóo dàgbà nípa tẹ̀mí. (Ìdárò 3:26, 27) Ọ̀dọ́bìnrin Kristẹni kan sọ pé, “kọ́kọ́ nífẹ̀ẹ́ Jèhófà ná kóo tó nífẹ̀ẹ́ ẹlòmíràn.”

Bóo bá ṣe ń dàgbà sí i tí ìlọsíwájú rẹ sì ń di mímọ̀ kedere fún gbogbo ènìyàn, àwọn òbí rẹ náà á wá bẹ̀rẹ̀ sí yí irú ojú tí wọ́n fi ń wò ọ tẹ́lẹ̀ padà. (1 Tímótì 4:15) Bóo bá sì ti wá dàgbà tó láti dájọ́ àjọròde, kò sí iyè méjì pé àwọn òbí rẹ yóò fọwọ́ sí i.

[Àwọn Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a A ti yí àwọn orúkọ padà.

b Fún ìsọfúnni síwájú sí i, wo ojú ìwé 232 àti 233 nínú ìwé Awọn Ìbéèrè Tí Awọn Ọ̀dọ́ Ń Béèrè—Awọn Ìdáhùn Tí Ó Gbéṣẹ́, tí Watchtower Bible and Tract Society of New York, Inc., tẹ̀ jáde.

[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 28]

Fífún ẹnì kan tó jẹ́ ẹ̀yà kejì ní àfiyèsí tó ṣàrà ọ̀tọ̀ . . .

. . . sábà máa ń ru ìfẹ́ ìbálòpọ̀ sókè

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 29]

Dípò ṣíṣe wọlé wọ̀de pẹ̀lú ẹnì kan ṣoṣo, kúkú bá àwọn èèyàn tó pọ̀ dọ́rẹ̀ẹ́