Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Fífayọ̀ Fara Dà Á Nínú Ayé Oníkòókòó Jàn-ánjàn-án Yìí

Fífayọ̀ Fara Dà Á Nínú Ayé Oníkòókòó Jàn-ánjàn-án Yìí

Fífayọ̀ Fara Dà Á Nínú Ayé Oníkòókòó Jàn-ánjàn-án Yìí

Ọ̀PỌ̀ JÙ LỌ ÀWỌN ÈÈYÀN LÓ Ń FARA DA WÀHÁLÀ ÌGBÉSÍ AYÉ, ÀMỌ́ ÌWỌ̀NBA DÍẸ̀ LÀWỌN TÓ Ń FAYỌ̀ ṢE BẸ́Ẹ̀. ÌYẸN SÌ Ń BÉÈRÈ FÚN ỌGBỌ́N ÀRÀ Ọ̀TỌ̀ KAN.

ÌWÉ The 24-Hour Society kín òótọ́ yìí lẹ́yìn, ó sọ pé: “Ó di dandan ká wá ọgbọ́n táa máa fi dáàbò bo àwọn ohun téèyàn nílò àti irú ẹni tí wọ́n jẹ́ nínú ayé onímọ̀ iṣẹ́ ẹ̀rọ táa ti fọwọ́ ara wa dá sílẹ̀ yìí.”

Inú wa dùn pé, ọgbọ́n tó wúlò ti wà ní sẹpẹ́ nínú ìwé tó gbayì jù lọ lágbàáyé—ìyẹn Bíbélì, Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run. Níwọ̀n bó ti jẹ́ pé Ẹni tó mọ ohun tí ẹ̀dá ènìyàn nílò àti irú ẹni tí wọ́n jẹ́ gan-an ló mí sí Bíbélì, ó ní àwọn ìlànà tó dára tó sì wúlò nínú. Fífi àwọn ìlànà yìí sílò lè ràn ọ́ lọ́wọ́ láti túbọ̀ kápá ìgbésí ayé rẹ, kó sì fún ọ ní ayọ̀ díẹ̀ ó kéré tán bóo ti ń fara dà á nínú ayé oníkòókòó jàn-ánjàn-án tòde òní.—Aísáyà 48:18; 2 Tímótì 3:16.

Àwọn ìlànà yìí kan apá mẹ́ta tó ṣe pàtàkì. Àkọ́kọ́, wọ́n tọ́ka sí àwọn ibi tóo ti lè fi ọgbọ́n já àwọn nǹkan tí ò ṣe pàtàkì kúrò. Èkejì, wọ́n lè ràn ọ́ lọ́wọ́ láti gbé àwọn ohun àkọ́múṣe tó bọ́gbọ́n mu kalẹ̀. Ẹ̀kẹta, wọ́n jẹ́ kéèyàn fojú tẹ̀mí wo ìgbésí ayé, èyí sì sàn fíìfíì ju fífi ojú tayé wò ó lọ. Ní báyìí, ẹ jẹ́ ká gbé àwọn apá mẹ́tẹ̀ẹ̀ta yìí yẹ̀ wò.

Má Walé Ayé Máyà, Má Kóhun Tó Pọ̀ Jù Mọ́ra

Fojú inú wò ó pé o fẹ́ gbafẹ́ lọ fún bí ọjọ́ mélòó kan. O fẹ́ kára tù ọ́, lo bá di aṣọ ńlá tí wàá fi pàgọ́ àtàwọn ẹrù lóríṣiríṣi dání. O tún fọkọ̀ ẹrù ńlá di àga, tábìlì, àwọn ohun èèlò ìgbọ́únjẹ, ẹ̀rọ tó ń jẹ́ kí omi dì, ẹ̀rọ amúnáwá kékeré, àwọn ohun tó ń pèsè ìmọ́lẹ̀, tẹlifíṣọ̀n, àti ọ̀pọ̀ jaburata àwọn nǹkan míì títí kan oúnjẹ. Àmọ́, ó gbà ọ́ ní ọ̀pọ̀ wákàtí kóo tó to àwọn nǹkan wọ̀nyí tán! Lẹ́yìn tóo wá parí ìsinmi ráńpẹ́ ọ̀hún, lo bá tún lo iye wákàtí kan náà láti fi palẹ̀ wọn mọ́—ìyẹn kò sì tíì mọ́ àkókò tí wàá fi to gbogbo wọn padà sáyè wọn nílé o. Nígbà tí wàá wẹ̀yìn padà, o rí i pé o ò ní àkókò tó rárá láti fi gbádùn ìsinmi náà! O wá ń ṣe kàyéfì bóyá gbogbo wàhálà tóo ṣe tiẹ̀ bọ́gbọ́n mu.

Fún àràádọ́ta ọ̀kẹ́ èèyàn lóde òní, bí ìrìn àjò ìsinmi yẹn ni ìgbésí ayé wọn rí. Wọ́n ń lo àkókò tó pọ̀ kọjá ààlà láti rà kí wọ́n sì bójú tó àìmọye àwọn ohun ìní tara èyí táyé ń fẹ́ ká rò pé a nílò wọn ká tó lè láyọ̀. Ní ìyàtọ̀ síyẹn, Jésù Kristi sọ pé: “Nígbà tí ẹnì kan bá tilẹ̀ ní ọ̀pọ̀ yanturu pàápàá, ìwàláàyè rẹ̀ kò wá láti inú àwọn ohun tí ó ní.” (Lúùkù 12:15) Òótọ́ ọ̀rọ̀ ni, kì í ṣe béèyàn ṣe ní nǹkan sí ni ìdiwọ̀n bí ìgbésí ayé onítọ̀hún ṣe nítumọ̀ sí. Ká sọ tòótọ́, ńṣe ni ọrọ̀ tiẹ̀ sábà máa ń dá kún másùnmáwo àti àníyàn ìgbésí ayé. Oníwàásù 5:12 sọ pé: “Ọ̀pọ̀ rẹpẹtẹ tí ó jẹ́ ti ọlọ́rọ̀ kì í jẹ́ kí ó sùn.”

Wáá wo àwọn ohun tóo ní dáadáa níkọ̀ọ̀kan, kóo sì wá bi ara rẹ pé, ‘Ṣé lóòótọ́ ni mo nílò eléyìí, àbí ẹrù ìdíwọ́ ló jẹ́? Ǹjẹ́ ó mú ìgbésí ayé mi sunwọ̀n sí i, àbí ńṣe ló ń jí lára ìwọ̀nba àkókò gidi tí mo ní?’ Nínú ìnasẹ̀ ọ̀rọ̀ ìwé Why Am I So Tired?, tí Leonie McMahon kọ, ó sọ pé: “Mímú tí wọ́n ń mú oríṣiríṣi àwọn ohun èèlò jáde, èyí tí wọ́n ń ṣe nítorí àti mú wàhálà iṣẹ́ ilé kúrò ti yọrí sí káwọn ìyàwó máa filé sílẹ̀ láti lọ ṣiṣẹ́ níta, kí wọ́n bàa lè ra àwọn ohun èèlò náà kí wọ́n sì lè rí owó bójú tó wọn.”

Nígbà tí o ò bá walé ayé máyà, wàá túbọ̀ ráyè fáwọn ẹbí, ọ̀rẹ́, àti fún ara rẹ. Irú àkókò bẹ́ẹ̀ ṣe pàtàkì fún ayọ̀ rẹ. Má ṣe dà bí àwọn tó jẹ́ pé ìgbà tọ́ràn bá ti bọ́ sórí tán ni wọ́n tó ṣẹ̀ṣẹ̀ ń mọ̀ pé àwọn ọ̀rẹ́ àti ìdílé ẹni ló ṣe pàtàkì jù lọ—pé wọ́n tún gbádùn mọ́ni ju owó àtàwọn nǹkan ìní lọ. Àwọn ènìyàn nìkan ló lè nífẹ̀ẹ́ rẹ. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé owó tóo ní sí báńkì, ìpín ìdókòwò ilé iṣẹ́ ńlá tóo ní, kọ̀ǹpútà, tẹlifíṣọ̀n, àtàwọn nǹkan mìíràn ní àyè tiwọn, àyàbá ni wọ́n jẹ́, wọn kì í ṣe ohun tó ṣe pàtàkì jù lọ nínú ìgbésí ayé. Àwọn tó sọ irú àwọn nǹkan bẹ́ẹ̀ di bàbàrà wulẹ̀ ń fi ìgbésí ayé wọn wọ́lẹ̀ ni, àsẹ̀yìnwá àsẹ̀yìnbọ̀, wọn kì í ní ìtẹ́lọ́rùn, ìbànújẹ́ tilẹ̀ lè dé bá wọn.—1 Tímótì 6:6-10.

Ṣọ́ Àkókò Lò, sì Mọ Ohun Tó Yẹ Kó Ṣáájú

Láwọn ọ̀nà kan, ṣíṣọ́ àkókò lò dà bí ìgbà téèyàn gbéṣirò lé bó ṣe fẹ́ náwó. Tóo bá gbìyànjú àti ṣe ohun tó pọ̀ jù láàárín ìwọ̀nba àkókò tóo ní, á jẹ́ pé o ò ṣe bóo ti mọ nìyẹn nínú lílo àkókò. Ìjákulẹ̀, másùnmáwo àti àárẹ̀ ara ló ń kẹ́yìn irú ìgbésí ayé bẹ́ẹ̀. Nítorí náà, kọ́ bí a ṣe ń mọ àwọn ohun àkọ́múṣe.

Lákọ̀ọ́kọ́ ná, mọ àwọn nǹkan wo ló ṣe pàtàkì jù, kóo sì fún wọn ní àkókò tó pọ̀ tó. Ní tàwọn Kristẹni, lílépa àwọn nǹkan tẹ̀mí ló máa ń ṣáájú nínú ìgbésí ayé wọn. (Mátíù 6:31-34) Béèyàn bá fi wàdùwàdù ṣe àwọn nǹkan tó ṣe pàtàkì tàbí tó kàn ṣe wọ́n lọ́nà kan ṣá, wàhálà ńlá ló sábà máa ń tẹ̀ lé e. Nítorí náà, ó lè di dandan pé kí o mú ohunkóhun tó ń gba àkókò ṣùgbọ́n tí kò ṣàǹfààní kúrò.

Ní gbígbé àwọn ohun àkọ́múṣe kalẹ̀, má gbàgbé pé o nílò àkókò díẹ̀ láti nìkan wà—ìyẹn àkókò fún ṣíṣàṣàrò gbígbámúṣé àti láti jèrè okun padà. Ìwé ìròyìn náà, Psychology Today, sọ pé: “Àkókò ìnìkanwà tó nítumọ̀ jẹ́ ohun tó pọndandan tó ń fúnni lókun táa nílò nínú ayé páápààpá táa ń gbé lónìí. . . . Àkókò ìnìkanwà jẹ́ ohun tó ń so ìgbésí ayé ró.” Àwọn èèyàn tí ọwọ́ wọn dí jù láti ṣàṣàrò lè dẹni tó kàn ń gbé ìgbé ayé lọ́nà kan ṣáá.

Wíwà Níwọ̀ntúnwọ̀nsì àti Jíjẹ́ Ẹni Tẹ̀mí

Wíwà níwọ̀ntúnwọ̀nsì àti jíjẹ́ ẹni tẹ̀mí jẹ́ méjì lára àwọn ohun ṣíṣeyebíye jù lọ tóo lè ní tó bá kan gbígbé ìgbésí ayé aláyọ̀ tó sì wà déédéé. Wíwà níwọ̀ntúnwọ̀nsì ṣe pàtàkì nítorí á ràn ọ́ lọ́wọ́ láti má ṣe tẹ́wọ́ gba àwọn ẹrù iṣẹ́ tí kò pọndandan fún ọ. Bóo bá wà níwọ̀ntúnwọ̀nsì, wàá mọ ìgbà tí kò yẹ kóo gba iṣẹ́ tó máa mú ẹ lo àkókò ré kọjá tàbí àwọn ìgbòkègbodò mìíràn tó máa nípa lórí nǹkan tó ṣe pàtàkì jù. Àwọn èèyàn tó wà níwọ̀ntúnwọ̀nsì kì í ṣe ìlara nǹkan táwọn ẹlòmíràn ní àti nǹkan tí wọ́n ń ṣe; ìdí nìyẹn tí wọ́n fi jẹ́ ẹni tó túbọ̀ nítẹ̀ẹ́lọ́rùn. Èyí ló mú kí ojúlówó ìwọ̀ntúnwọ̀nsì jẹ́ apá kan lára ipò tẹ̀mí, tó jẹ́ kókó mìíràn tó ṣe pàtàkì fún wa láti túbọ̀ lè darí ìgbésí ayé wa.—Míkà 6:8; 1 Jòhánù 2:15-17.

Ipò tẹ̀mí táa gbé karí ìmọ̀ pípéye Bíbélì á sọ ẹ́ di ẹni tó túbọ̀ lè fòye mọ nǹkan—ẹnì kan tí a kò fi ìtumọ̀ tí kò wúlò tàn jẹ, ìtumọ̀ tí ayé ń fún àṣeyọrí. Fi ìmọ̀ràn ọlọ́gbọ́n tó wà nínú 1 Kọ́ríńtì 7:31 sọ́kàn tó sọ pé: “[Kí] àwọn tí ń lo ayé [dà] bí àwọn tí kò lò ó dé ẹ̀kúnrẹ́rẹ́; nítorí ìrísí ìran ayé yìí ń yí padà.” Àwọn Kristẹni “ń lo ayé” nígbà ti wọ́n bá ń pèsè fún ara wọn àti fún ìdílé wọn, àmọ́ wọn kì í jẹ́ kí ayé yìí gbà wọ́n lọ́kàn pátápátá. Wọ́n mọ̀ pé kò lè pèsè ojúlówó ìfọ̀kànbalẹ̀ kankan, pé láìpẹ́, yóò di èyí tí a pa run pátápátá, àti pé ojúlówó àṣeyọrí—ìyẹn ìfọ̀kànbalẹ̀ àti ìyè àìnípẹ̀kun nínú Párádísè ilẹ̀ ayé—sinmi lórí ìdúró tí ẹnì kan ní pẹ̀lú Ọlọ́run. (Sáàmù 1:1-3; 37:11, 29) Nítorí náà, fi ìṣílétí Jésù sílò, kóo sì fọgbọ́n dókòwò nípa títo “ìṣúra jọ pa mọ́ . . . ní ọ̀run, níbi tí òólá tàbí ìpẹtà kò lè jẹ nǹkan run, àti níbi tí àwọn olè kò lè fọ́lé, kí wọ́n sì jalè.”—Mátíù 6:20.

Yẹra fún Àníyàn Kí O sì Wá Ojúlówó Àlàáfíà

Kò sí àní-àní pé, bí ètò ìgbékalẹ̀ yìí tí ń lọ sópin rẹ̀, másùnmáwo àtàwọn ohun tó máa fẹ́ láti gba àkókò rẹ yóò máa pọ̀ sí i. Nígbà náà, o ò rí i pé ó ṣe pàtàkì pé kóo tiraka láti mú ìmọ̀ràn Bíbélì lò, èyí tó sọ pé: “Ẹ má ṣe máa ṣàníyàn nípa ohunkóhun, ṣùgbọ́n nínú ohun gbogbo nípasẹ̀ àdúrà àti ìrawọ́ ẹ̀bẹ̀ pa pọ̀ pẹ̀lú ìdúpẹ́ kí ẹ máa sọ àwọn ohun tí ẹ ń tọrọ di mímọ̀ fún Ọlọ́run; àlàáfíà Ọlọ́run tí ó ta gbogbo ìrònú yọ yóò sì máa ṣọ́ ọkàn-àyà yín àti agbára èrò orí yín nípasẹ̀ Kristi Jésù.” Irú àlàáfíà yẹn jìnnà sí ẹnikẹ́ni tí kò mọ nǹkan kan ju ohun tó jẹ́ tayé yìí lọ, tí kò rí àǹfààní kankan tí àdúrà ní.—Fílípì 4:6, 7.

Àní sẹ́, ohun tí Jèhófà máa ṣe fún ẹ ju kìkì pé á fún ẹ ní ìbàlẹ̀ ọkàn lọ. Yóò ràn ọ́ lọ́wọ́ láti gbé ẹrù ìnira rẹ lójoojúmọ́ bí o bá “kó gbogbo àníyàn [rẹ] lé e.” (1 Pétérù 5:7; Sáàmù 68:19) Nítorí náà, ó bọ́gbọ́n mu láti máa tẹ́tí sí Ọlọ́run lójoojúmọ́ nípa kíka apá kan lára Ọ̀rọ̀ rẹ̀. Ta lẹni tó tún lè fún ọ nímọ̀ràn tó dara ju èyí tí Ẹlẹ́dàá rẹ yóò fún ọ? (Sáàmù 119:99, 100, 105) Dájúdájú, ìrírí ti fi hàn pé àwọn tó fi Ọlọ́run ṣe àkọ́kọ́ ní ìgbésí ayé wọn ń rí ìrànlọ́wọ́ gidi gbà láti máa fayọ̀ fara dà á nínú ayé oníkòókòó jàn-án jàn-án yìí.—Òwe 1:33; 3:5, 6.

[Ìsọfúnni tá a pàfiyèsí sí ní ojú ìwé 11]

Gbé àwọn ohun àkọ́múṣe kalẹ̀, títí kan wíwá àkókò fún nínìkanwà àti ṣíṣe ohun tí yóò mú ọ jẹ́ ẹni tẹ̀mí

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 9]

Ṣé o lè mú ìgbésí ayé rẹ túbọ̀ rọrùn sí i, kóo má sì kó ohun tó pọ̀ jù mọ́ra?

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 10]

Ṣé àwọn nǹkan ìní ló ṣe pàtàkì fún ọ jù tàbí àwọn èèyàn?