Kòókòó Jàn-ánjàn-án Ayé Yìí Pàpọ̀jù
Kòókòó Jàn-ánjàn-án Ayé Yìí Pàpọ̀jù
ǸJẸ́ Ó MÁA Ń JỌ PÉ Ẹ̀MÍ RẸ FẸ́ BỌ́ NÍTORÍ KÒÓKÒÓ JÀN-ÁNJÀN-ÁN TÓ PÀPỌ̀JÙ NÍ ÌGBÉSÍ AYÉ NÍGBÀ MÍÌ BÍ? ṢÉ Ó MÁA Ń YỌ ILÉ AYÉ LẸ́MÌÍ RẸ, TÁ JẸ́ KÓ RẸ̀ Ọ́, BÍI PÉ O Ò LÈ ṢÀṢEYỌRÍ? TÓ BÁ RÍ BẸ́Ẹ̀, KÌ Í ṢE ÌWỌ NÌKAN LỌ̀RỌ̀ Ọ̀HÚN KÀN.
ÀRÀÁDỌ́TA ọ̀kẹ́ èèyàn, àgàgà láwọn ìlú ńlá, ló rí i pé ìgbésí ayé ti wá kún fún ságbàsúlà tó kọjá kèrémí. Láwọn orílẹ̀-èdè Ìwọ̀ Oòrùn ayé lèyí tiẹ̀ pọ̀ sí jù. Níbi ìpàdé onísìn kan tó wáyé ní Orílẹ̀-Èdè Amẹ́ríkà, olùbánisọ̀rọ̀ kan sọ pé káwọn èèyàn tó bá jẹ́ pé ọ̀pọ̀ ìgbà ló máa ń rẹ̀ wọ́n na ọwọ́ sókè. Kíá, ọ̀pọ̀ èèyàn rẹpẹtẹ na ọwọ́ sókè.
Ìwé kan tí wọ́n pè ní Why Am I So Tired? sọ pé: “Ìgbésí ayé òde òní kún fún àwọn wàhálà tí a kò gbọ́ nípa wọn nígbà kan rí—àwọn bí ọkọ̀ òfuurufú tí kò gbọ́dọ̀ jáni sílẹ̀, àwọn ohun táa gbọ́dọ̀ ṣe kí àkókò wọn tó kọjá, àwọn ọmọ táa gbọ́dọ̀ mú lọ sí iléèwé jẹ́lé-ó-sinmi ká sì tún padà lọ mú wọn lásìkò—bẹ́ẹ̀ ni wọ́n pọ̀ lọ jàra.” Abájọ tí wọ́n fi fi rírẹ̀ tó má ń rẹ èèyàn wé orísun ewu ti àkókò wa. a
Láyé ọjọ́un, ìgbésí ayé rọrùn jù báyìí lọ, bẹ́ẹ̀ ni kòókòó jàn-ánjàn-án kò tó báyìí. Àwọn èèyàn sábà máa ń gbé níbàámu pẹ̀lú ìṣètò ìṣẹ̀dá—ìyẹn kéèyàn fojú mọmọ ṣiṣẹ́, bí ilẹ̀ bá sì ti ṣú ká wà pẹ̀lú ìdílé ẹni, lẹ́yìn náà, oorun ló kàn. Lóde òní, àwọn ìdí kan wà tó túbọ̀ ń mú kó máa rẹ àwọn èèyàn sí i, kí nǹkan sì máa sú wọn.
Ọjọ́ Di Gígùn Sí I Láìròtẹ́lẹ̀
Ìdí kan tó lè fa èyí ni pé oorun táwọn èèyàn ń sùn ń dín kù. Lára àwọn ohun pàtàkì tó túbọ̀ kó wàhálà bá àkókò tó wà fún oorun ni dídé tí iná mànàmáná dé. Kìkì nípa ṣíṣẹ́ ògiri léèékánná lásán, ó ti ṣeé ṣe fáwọn èèyàn láti mú “ọjọ́” gùn sí i, làwọn èèyàn bá bẹ̀rẹ̀ sí pẹ́ kí wọ́n tó lọ sùn. Àní sẹ́, ọ̀pọ̀ ni kò tiẹ̀ rí nǹkan ṣe sí ọ̀ràn ọ̀hún, nítorí pé ńṣe làwọn iléeṣẹ́ bẹ̀rẹ̀ sí ṣiṣẹ́ àṣemọ́jú, táwọn tó ń ṣe onírúurú iṣẹ́ náà sì bẹ̀rẹ̀ sí mú àkókò tí wọ́n ń lò gùn sí i. Òǹkọ̀wé kan sọ pé: “A ti bí àwùjọ èèyàn oníwákàtí mẹ́rìnlélógún.”
Àwọn ohun mìíràn tí ìmọ̀ iṣẹ́ ẹ̀rọ mú jáde bíi rédíò, tẹlifíṣọ̀n, àti kọ̀ǹpútà àdáni tún ń kópa tiwọn nínú gbígba oorun tó yẹ káwọn èèyàn sùn lójú wọn. Ní ọ̀pọ̀ orílẹ̀-èdè, wákàtí mẹ́rìnlélógún lóòjọ́ ni ilé iṣẹ́ tẹlifíṣọ̀n fi ń ṣiṣẹ́. Kò ya èèyàn lẹ́nu láti rí àwọn olólùfẹ́ eré sinimá tàbí ti eré ìdárayá, kí wọ́n dé ibi iṣẹ́ kí wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí tòògbé tàbí kó ti rẹ̀ wọ́n lẹ́yìn tí wọ́n ti
fi gbogbo alẹ́ wòran. Àwọn kọ̀ǹpútà inú ilé, àti àìlóǹkà ohun ìnàjú tí wọ́n ń pèsè, tún máa ń jẹ́ kí àràádọ́ta ọ̀kẹ́ àwọn èèyàn pẹ́ẹ́ sùn. Lóòótọ́, kì í ṣe àwọn ohun èèlò wọ̀nyí fúnra wọn ló lẹ̀bi; àmọ́ kóríyá ni wọ́n túbọ̀ jẹ́ fáwọn èèyàn kan láti mú kí wọ́n gbé èrò náà pé àwọ́n nílò ìsinmi tì sẹ́gbẹ̀ẹ́ kan.Ìgbésí Ayé Ń Sáré Tete
Kì í ṣe pé àwọn ọjọ́ wa di èyí tó gùn sí i nìkan ni, àmọ́ ńṣe ló dà bí ẹni pé ìgbésí ayé fúnra rẹ̀ ń sáré tete—lẹ́ẹ̀kan sí i, ìmọ̀ ẹ̀rọ náà ló tún wà nídìí ẹ̀. Kẹ̀kẹ́ ẹrù tí ẹṣin ń fà ní ohun tó dín díẹ̀ ní ọgọ́rùn-ún ọdún sẹ́yìn ti yàtọ̀ pátápátá sí ọkọ̀ ayọ́kẹ́lẹ́ akùnbọ̀ùn, ọkọ̀ ojú irin asáré tete, àti àwọn ọkọ̀ òfúúrufú ayára-bí-àṣá tòde òní. Àní sẹ́, oníṣòwò òde-òní kan, tó jẹ́ pé ẹsẹ̀ ni bàbá tó bí bàbá rẹ̀ fi ń rìn tàbí tó jẹ́ pé ẹṣin tàbí kẹ̀kẹ́ ló ń gùn lọ síbi iṣẹ́ nígbà ayé tirẹ̀, lè jẹun àárọ̀ nílẹ̀ yìí kó sì lọ jẹ tọ̀sán lókè òkun!
Iṣẹ́ ọ́fíìsì náà ti fi pẹ̀lẹ́pẹ̀lẹ́ yí padà kúrò lóhun tó ti jẹ́ tẹ́lẹ̀ rí nítorí àtimúṣẹ́yá àti láti mú ohun púpọ̀ sí i jáde. Kọ̀ǹpútà, ẹ̀rọ aṣàdàkọ ìsọfúnni, àti lẹ́tà orí kọ̀ǹpútà ti gborí lọ́wọ́ ẹ̀rọ ìtẹ̀wé àti lẹ́tà tí wọ́n ń fọwọ́ gbé. Kíkọ̀wé lórí kọ̀ǹpútà, àwọn tẹlifóònù alágbèérìn àti àwọn ẹ̀rọ kóńkóló tí ń tani lólobó kò jẹ́ kí iṣẹ́ ọ́fíìsì parí sí ọ́fíìsì mọ́, kàkà bẹ́ẹ̀, iṣẹ́ tún ń bá a nìṣó nínú ilé ni.
Dájúdájú, kò sẹ́nì kankan nínú wa tó lè dín bóò-lọ-o-yàá-mi tó gbayé kan yìí kù. Àmọ́ o, àwa fúnra wa lè ṣe àwọn àtúnṣe tó máa jẹ́ ká lè gbé ìgbésí ayé tó túbọ̀ parọ́rọ́ tó sì wà déédéé. Ṣùgbọ́n kó tó di pe a gbé ọ̀ràn yí yẹ̀ wò, ẹ jẹ́ ká ṣàyẹ̀wò díẹ̀ lára ipa tí ìgbésí ayé kòókòó jàn-ánjàn-án tòní lè ní lórí wa lẹ́nì kọ̀ọ̀kan àti lórí àwùjọ lódindi.
[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Àwọn ohun kan wà tó tún lè mú kó máa rẹ èèyàn ṣáá yàtọ̀ sí àwọn wàhálà ojoojúmọ́. Àwọn nǹkan tó lè fà á lè jẹ́ àìjẹunrekánú, egbòogi, ìbàyíkájẹ́, másùnmáwo àti ìdààmú, ọjọ́ ogbó, tàbí àpapọ̀ àwọn nǹkan wọ̀nyí.