Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Nígbà Tí Àrùn Burúkú Kan Bá Kọ Lù Ọ́

Nígbà Tí Àrùn Burúkú Kan Bá Kọ Lù Ọ́

Nígbà Tí Àrùn Burúkú Kan Bá Kọ Lù Ọ́

“Ńṣe làyà mi là wá gààràgà.”—Ìrírí John nìyẹn, lẹ́yìn tó gbọ́ pé òún ní àìsàn burúkú kan.

“Ẹ̀rù bà mí gan-an ni.”—Ohun tó ṣẹlẹ̀ sí Beth nìyẹn, lẹ́yìn tó mọ̀ nípa bí àìsàn tó kọ lu òun ti le tó.

MÍMỌ̀ pé o ní àìsàn bára kú tí ń sọni di aláàbọ̀ ara, tàbí pé ara tóo fi pa nínú jàǹbá kan yóò sọ ọ́ dẹni tó lálèébù ara títí ayé jẹ́ ọ̀kan lára àwọn ohun tó ń ṣẹlẹ̀ síni tó ń bani nínú jẹ́ jù lọ ní ìgbésí ayé. Ì báà jẹ́ pé inú ọ́fíìsì dókítà lo ti rọra gbọ́ ìròyìn nípa àìsàn rẹ ni o, tàbí kẹ̀ nínú yàrá ìtọ́jú pàjáwìrì ni wọ́n ti sọ fún ọ lójúkojú nípa ipò tóo wà, ó dájú pé oò ní ṣàìkọ́kọ́ rò pé àlá lò ń lá. Ó fẹ́rẹ̀ẹ́ máà sí nǹkan náà láyé tó lè múra ẹ sílẹ̀ fún kíkojú ìpòrúurùu ọkàn tó máa dé bá ọ nígbà tí àrùn burúkú kan bá kọ lù ọ́.

Láti rí ìsọfúnni tó lè ṣèrànwọ́ fáwọn tí àìsàn lílekoko bẹ̀rẹ̀ sí ṣe lẹ́nu àìpẹ́ yìí, Jí! bá àwọn èèyàn kan ní orílẹ̀-èdè ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ sọ̀rọ̀, tó jẹ́ pé fún ọ̀pọ̀ ọdún ni wọ́n fi kojú àìsàn bára kú. Wọ́n ní kí wọ́n sọ èrò wọn lórí àwọn ìbéèrè bíi: Irú àwọn ìmọ̀lára wo lo ní? Kí ló ràn ọ́ lọ́wọ́ láti la àkókò lílekoko náà já kí o sì tún máa ṣe bí o ṣe ń ṣe tẹ́lẹ̀? Kí làwọn nǹkan tóo ṣe láti lè bójú tó ara rẹ níwọ̀nba? Àwọn ọ̀rọ̀ táa gbọ́ ní tààràtà látẹnu àwọn táa fọ̀rọ̀ wá lẹ́nu wò títí kan àwọn ìwádìí táwọn tó ń kẹ́kọ̀ọ́ àbájáde tó ń wá látinú àìsàn ọlọ́jọ́ pípẹ́ ṣe la pèsè fún àǹfààní àwọn tí àrùn lílekoko ń ṣe lọ́wọ́lọ́wọ́. a

[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a Bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn tí àìsàn ń ṣe tàbí tí wọ́n ti di aláàbọ̀ ara la darí ọ̀wọ́ ọ̀rọ̀ ẹ̀kọ́ yìí sí, àwọn ọ̀wọ́ náà, “Àìsàn Bára Kú—Kíkojú Rẹ̀ Gẹ́gẹ́ Bí Ìdílé” (Jí! ti June 8, 2000) ní àwọn ìsọfúnni nínú, táa dìídì darí rẹ̀ sáwọn tó ń bojú tó àwọn tí àìsàn ń ṣe.